'Àṣà àti ìṣe ló sọnù tí ìjà àgbà fi ń wáyé láàárín àwọn Ọba Yorùbá'

Ooni Ile Ife, Ọba Enitan Ogunwusi de ade Are ti awọn ilari ti wọn mu ẹgba dani n tẹle
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

‎Ẹsẹ ko gbero ni ilu Ile-Ife, ipinlẹ Osun ni ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2025 ni awọn eeyan kaakiri agbaye ṣe kopa nibi ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ.

Gẹgẹ bi igbagbọ awọn ọmọ Yoruba, irinwó ati ẹyọ kan ni awọn Òrìṣà to wa ní Ilé-Ife, ipinlẹ Osun àti pe gbogbo wọn ni wọn ni ọjọ́ ti wọn maa n bọ wọn.

Ọdún Ọlọjọ jẹ ọdún kan pàtàkì ni ilẹ̀ Yorùbá lati fi ṣami ọjọ ti Olodumare da ile aye, bẹẹ si ni o jẹ ọdún tó ti pẹ ni ilẹ̀ Yorùbá.

O jẹ ọdun to maa n waye ni iranti Ogun to jẹ akọbi Oduduwa.

Aṣa ati iṣe Yoruba lo sọnu ti awọn oriade wa n fi jija agba

Àwọn ero to n kopa nibi ayẹyẹ ọdun Ọlọ́jọ́ wọ aṣọ alaranbara ti wọn si ja ewe dani

Ọba Olayinka Oyetunde, Alayemore ti Ido-Osun sọ pe ọdun Ọlọjọ ṣe pataki lati fi gbe asa ilẹ Yoruba ga.

‎Ọba Alayemore rọ gbogbo awọn oriade ati ọrun ilẹkẹ kaakiri ilẹ Yoruba lati ṣe ara wọn lọkan ki alaafia le jọba, ki wọn gbagbe ọrọ iwọ ju mi emi o ju ọ ki idagbasoke le ba ilẹ Yoruba.

Lati igba iwaṣẹ ni ija iwọ ju mi emi o ju ọ ti maa n waye laaarin awọn ori ade

Awọn to n kopa nibi ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ wọ aṣọ oke

‎‎Aarẹ fun igbimọ Yoruba lagbaaye, Oladotun Hassan sọ pe ija agba laaarin awọn ori ade ti maa n waye lati igba iwaṣẹ to si jẹ pe ẹru ni awọn Ọba maa fi n ko ara wọn nigba naa.

‎‎Oladotun woye pe ogun ija iwọ o ju mi emi o ju ẹ ti yatọ si ti igba iwasẹ, nitori ọlaju to ti gbaye kan lode oni paapa lara awọn ohun to baye jẹ ni ẹrọ ayelujara ti ọpọlọpọ n ṣi lo bayii.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‎O ni ko le si idagbasoke laaarin ilu bi ọrọ ija agba ba n tẹsiwaju laarin awọn oriade ati pe a nilo lati pada si ibẹrẹ pẹpẹ ki ilọsiwaju le ba ilẹ Yoruba.

‎Ninu ọrọ tirẹ, Arabinrin Toyin Kolade, to jẹ Iyalaje Oodua gba awọn oriade ni imọran lati fi ọrọ ija agba silẹ ki alaafia le pọ laaarin ara wọn ati laaarin ọmọ ilẹ Yoruba.

‎‎‎Arabinrin Toyin parọwa si awọn oriade gbogbo ki wọn ṣe ara ni osusu ọwọ ki alaafia le jọba laaarin wọn.

‎‎Oloye Tonade Ajibo ṣe apejuwe ọna ti ọdun Ọlọjọ fi jẹ ọdun asa ni ilẹ yoruba ati bo ṣe jẹ ọdun apewo.‎

‎Oloye Tọnade ni lati igba ti Ooni Ile-Ife, Ọba Enitan Ogunwusi gori itẹ ni ọdun Ọlọjọ ti di gbajugbaja ti ọpọ eeyan maa n fara han nibi ayẹyẹ ọdun naa.

O ni oju ti oun fi n wo idagbasoke asa ilẹ Yoruba ni pe aṣa Yoruba ti n ni idagbasoke si ju ti atẹyinwa lọ.

‎O wa rọ gbogbo awọn oriade lati ṣe ara wọn lọkan ki idagbasoke le tun de ba asa Yoruba ati ọdun Ọlọjọ.

‎‎Ọba Enitan Ogunwusi, Ọọni ti Ilẹ Ifẹ ru Ade isẹbaye ti wọn n pe ni Ade Are ti igbagbọ wa pe ohun lo wuwo julọ lagbaaye lati fi wure fun gbogbo eeyan.

‎‎Ara ọtọ ni ayẹyẹ ọdun Ọlọjọ gbe wa ni ọdun yii bi asọ oke ṣe n pe ara wọn ran nisẹ nibẹ.

Ooni Ogunwusi jokoo lori itẹ ti awọn ẹṣọ ati ero si jokoo ti i

Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọdún Ọlọ́jọ́ tí yóò wáyé ní Ile-Ife lónìí

Ooni Ile-Ife pẹ̀lú Ade Are lórí níbi ayẹyẹ ọdún Ọlọ́jọ́ tó wáyé lọ́dún 2023

Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá, irinwó àti ẹyọ̀kan ni àwọn Òrìṣà tó wà ní Ile-Ife, ìpínlẹ̀ Osun àti pé gbogbo wọn ló ní ọjọ́ tí wọ́n máa ń bọ wọ́n.

Ọdún Ọlọ́jọ́ jẹ́ ọdún kan pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá èyí tí wọ́n fi máa ń ṣàmì ọjọ́ tí Olódùmarè dá ilé ayé.

Ọdún Ọlọ́jọ́ wà lára àwọn ọdún tó ti pẹ́ ní ilẹ̀ Yorùbá.

Ó jẹ́ ọdún tó máa ń wáyé ní ìrántí Ogun tí ìgbàgbọ́ wà pé ó jẹ́ àkọ́bí Olódùmarè.

Ṣáájú àyájọ́ ọdún yìí ni Ooni Ile-Ife yóò ti wà ní ìgbélé ọjọ́ méjì níbi tí yóò ti máa ṣe àdúrà fún ìran Yorùbá àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀.

Lẹ́yìn èyí ni Ooni máa jáde síta pẹ̀lú Ade Are, èyí tí ìgbàgbọ́ wà pé òhun ni Oduduwa kọ́kọ́ dé.

Láàárín oṣù Kẹsàn-án sí oṣù Kẹwàá ọdún ni ọdún Ọlọ́jọ́ máa ń wáyé.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé ni wọ́n máa ń péjú pésè sí ìlú Ile-Ife láti kópa níbi ayẹyẹ ọdún Ọdún Ọlọ́jọ́.