Rasidi Ladoja gba adé Olubadan ilẹ̀ Ibadan

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga
Ọba Rasidi Adewolu Ladoja ti gba ade olubadan ti ilẹ Ibadan.
Gbagede Mapo ni ayẹyẹ naa yi waye laarọ oni ọjọ Ẹti niluu Ibadan.
Awọn eeyan jankanjankan nilẹ Ibadan, ilẹ Yoruba ati kaakiri Naijiria lo peju sibi eto naa.

Oríṣun àwòrán, @OloyeSomorin
Oni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹsan an, ọdun 2025 ni Olubadan tuntun, Ọba Rasidi Ladoja yoo gba ọpa gẹgẹ bii Olubadan kẹrinlelogoji.
Gbogbo eto lo ti to, ọpọ awọn alejo atawọn eeyan jankanjankan lo si ti n balẹ siluu Ibadan fun eto naa.
Gbagede Mapo ni ọpọ awọn olori oloṣelu, ladelade araalu atawọn alejo n korajọ si lati foju ganni ayẹyẹ ọhun.
Wamu-wamu ni ni awọn ẹṣọ aabo duro ni gbagede Mapo nibi ti eto gbigba ade ati ọpa aṣẹ naa ti waye.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ ja ewe Akoko le Ladoja lori gẹgẹ bii Olubadan kẹrindinlogoji lati agbo ile Labosinde.
Ojaoba Oluwo Afobaje Labosinde lo ja ewe naa sori Olubadan Ọba Rashidi Adewolu Ladoja.
Eto jija ewe akoko yii lo wa ni ibamu pẹlu ilana ifinijoye ilu Ibadan.
Lẹyin eyi ni Ọba Adewolu Ladoja wọ inu yara Osemeji lọ, eyi to wa ni idojukọ agbo ile Labosinde fun awọn ọrọ ti wọn ma n ṣe fun awọn Ọba.
Ladoja de si agbo ile Labosinde ninu ọkọ ayọkele Limousine funfun, pelu awọn ọmọ ẹgbẹ igbimọ apapọ ti Olubadan ati awọn ọmọ ẹgbẹ to jọ ti ologun ti ilu Ibadan, ati awọn mọlẹbi Ọba Rashidi Ladoja.
Oba Ladoja ni wọn fi idi rọ mulẹ gẹgẹ bii Olubadan kẹrinlelogoji ti ilu Ibadan lẹyin yiyan ti ẹgbẹ igbimọ Olubadan ni Aafin Olubadan tuntun, to w ani Oke-Aremo.
Lara awọn alejo ti wọn n reti nibẹ ni Aarẹ Bola Tinubu, igbakeji Aarẹ tẹlẹ, Atiku Abubakar, gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ, Rabiu Kwankwaso, Sultan Sokoto, Muhammadu Sa'ad Abubakar Kẹta.
Awọn mii ti yoo tun wa nibẹ ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun, gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ati gomina ipinlẹ Ondo Lucky Aiyedatiwa.
Gomin ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ni yoo gbalejo awọn eeyan naa.

Oríṣun àwòrán, Aafin Olubadan
Bo tilẹ jẹ pe gbagede Mapo ni ayẹyẹnaa yoo ti waye, gbogbo ilu Ibadan lo ti n mi titi fun ayẹyẹ ọhun.
Ṣaaju ayẹyẹ gbigba ọpa aṣẹ yii ni awọn eto kan ti kọkọ waye bii adura pataki fun ilu Ibadan, kiko Egungun jade ati afihan aṣa, idanilẹkọọ pataki ti Toyin Falola ṣe, to fi mọ awọn etutu fun Ọba Ladoja.
Ladoja, to jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgọrin lo n gba aṣẹ gẹgẹ bii Olubadan kẹrinlelogoji lẹyin ọpọ ọdun to kọkọ di Mogaji.
Lẹyin to jẹ oye Mogaji lẹyin ọdun 1980 lo gun akasọ titi de ipo Jagun Olubadan lọdun 1993.
Oun ni gomina akọkọ nipinlẹ Oyo ti yoo de ori ipo naa.
Gbogbo bi eto naa ba ṣe n waye ni a o maa fi to yin leti loju opo yii lonii.















