Wo àwọn nǹkan tó ti wáyé nílùú Ibadan ṣáájú ìfinijoyè Ọba Ladoja

Oríṣun àwòrán, Others
Bi awọn ọmọ Ibadan ṣe n gbaradi fun ayẹyẹ ifinijoye Olubadan tuntun ni ọpọ igbesẹ ti n lọ letoleto kaakiri ilu naa.
Bẹrẹ lati bi wọn yoo se ti awọn ọna kan pa, eyi ti wọn ti fi to awọn araalu leti nipa awọn ọna miiran ti wọn le lo ti yoo mu irinajo wọn jẹ irọnu.
Bẹẹ naa ni ijọba ipinlẹ Oyo tun si paapa ofurufu Samuel Ladoke Akintola to wa niluu Ibadan, to si ti gba alejo baalu akọkọ lẹyin ti wọn ti pa ninu oṣu kẹta ọdun yii.
Igbesẹ yii lo waye nitori bi ilu Ibadan yoo ṣe ma gba alejo Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu fun ayẹyẹ ifinijoye Olubadan tuntun.
Baaluu yii balẹ ni deede ago mẹsan an kọja isẹju mẹrinla lọjọru, to si pada ọpọ idunu ati ayọ araalu.
Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ni igbagbọ wa pe yoo balẹ si ilu Ibadan ni Ọjọ Ẹti fun ayẹyẹ Olubadan tuntun, Oba Rashidi Adewolu Ladoja.
Bakan naa, Babaloja gbogbo ipinlẹ Oyo, Asiwaju Yekeen Abass ti paṣẹ pe ki gbogbo ọja pata niluu ibadan di titi pa ṣaaju eto ifinijoye Olubadan.
Ifinijoye yii ni yoo waye ni ọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu kẹsan an ọdun 2025 ni gbọngan Mapo niluu Ibadan, to jẹ olu ilu fun ipinlẹ Oyo.
Ikede yii lo wa ninu atẹjade ti Babalọja fi sita fun awọn akọroyin lati fi ki Olubadan tuntun, Oba Rasidi Adewolu Ladoja ku orire ifinijoye gẹgẹ bii Olubadan kẹrinlelogoji
Babalọja rọ gbogbo awọn ọlọja ni ijọba ibilẹ mọkanla to wa ni ilu Ibadan pe ki wọn ti ọja wọn pa lati bu ọla fun ori ade tuntun.
Ta ni Olubadan?
Oye ọba jijẹ ilẹ Ibadan ko ruju, ẹni to kan yoo ti mọ ara rẹ ṣaaju akoko ti yoo debẹ.
Idi ree ti gbogbo eeyan fi n ṣe Kabiyesi silẹ bayii fun Oloye Sẹnetọ Rasheed Adewolu Ladoja, gomina Oyo tẹ́lẹ̀ tí yóò di Olúbàdàn kẹrìnlélógójì.
Aridaju yii n waye pe Rasheed Ladoja too di Olubadan tori ipapoda Olubadan Owolabi Olakuleyin, nigba to ku ọjọ diẹ ko pe ọdun kan to jọba ilu Ibadan.
Ọjọ kejila, oṣu Keje ọdun 2024 ni ọba to waja naa di Olubadan kẹtalelogoji labẹ ofin.
Ni bayii, igun ti Ladoja ti wa, ni ipo Olubadan kan, agba oye Rasheed Ladoja naa si ni oloye to ga ju nibẹ bayii, eyi to mu ipo Ọba Ibadan tọ si















