Ajínigbé jí lọ́yà tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ búra fún pẹ̀lú ìbátan rẹ̀, ẹgbẹ́ agbẹjọ́rò ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀

Oríṣun àwòrán, @NigBarAssoc/X
Ẹgbẹ awọn agbẹjọro ni Naijiria, Nigerian Bar Association (NBA), ti kan si ijọba apapọ lati ṣọna iyọnda akẹgbẹ wọn; Onyesom Peace Udoka ti awọn ajinigbe ji gbe laipẹ yii.
Awọn ajinigbe ọhun ji Udoka ati ibatan rẹ obinrin kan gbe lasiko ti wọn n bọ lati ibi ayẹyẹ ti wọn ti sọ Udoka di lọya ni Naijiria (Call to Bar Ceremony), lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹsan-an ọdun 2025.
Iroyin sọ pe ilu Abuja ni Lọya Udoka ati ibatan rẹ naa ti n bọ, nibi ti ayẹyẹ naa ti waye.
Agbegbe Lokoja-Okene, nipinlẹ Kogi ni awon ajinigbe naa si ti ṣẹburu wọn, ti wọn gbe wọn sa lọ.
Aarẹ ẹgbẹ NBA, Afam Osigwe, ṣalaye loju opo X rẹ, pe iṣẹlẹ itiniloju ti ko bojumu gba a ni eyi.
"O ba ni lọkan jẹ, pe asiko to yẹ ki Naijiria maa yọ lori ọjọ iwaju iṣẹ ofin ni awọn kan sọ ọdọmọde lọya yii ati awọn ẹbi rẹ sinu ibanujẹ.
"Ko si mọlẹbi to yẹ ko koju iru idaamu yii, ko si yẹ ki araalu maa gbe ninu ipaya ni gbogbo igba nitori ewu to kun oju ọna wa gbogbo.
"Ẹgbẹ wa n pe ijọba apapọ ati gbogbo ẹṣọ alaabo to yẹ lati tete mojuto iṣẹlẹ yii, ki wọn si ri i pe wọn tu akẹgbẹ wa atawọn yoku to wa lakata awọn ajinigbe silẹ. "
Bẹẹ ni Aarẹ awọn lọya Naijiria naa ṣalaye.
O ni ko yẹ kijọba tẹsiwaju ninu fifi ọwọ yẹpẹrẹ mu aabo awọn ọmọ Naijiria. Nitori akọkọ ninu ojuṣe ijọba ni riri si aabo araalu.
A ti ri mẹjọ gba ninu awọn mejila ti wọn ji gbe ni Okene-Auchi-Ọlọpaa
Alukoro ọlọpaa Naijiria, CSP Benjamin Hundeyin, kede pe awọn ti ri eeyan mẹjọ gba pada ninu awọn mejila ti ajinigbe ji gbe loju ọna Okene-Auchi, lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹsan-an ọdun 2025.
Ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku lo ti ni pẹlu iranlọwọ ọlọpaa ati awọn ologun ni awọn fi ri awọn eeyan naa gba pada.
O ni igbiyanju n lọ lọwọ lati ri awọn to ṣẹku si igbekun ajinigbe naa gba pada pẹlu alaafia ara.
Wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé tó ti wáyé láìpẹ́ yìí
Ijinigbe jẹ ọkan lara awọn ipenija aabo to n koju orilẹede Naijiria.
Ẹ o ranti pe nipinlẹ Kogi kan naa ni awọn ajinigbe ti ya bo ile ẹkọ giga Confluence University of Science and Technology lọdun to kọja, ti wọn si ji akẹkọọ mẹsan-an gbe lọ.
Inu kilaasi ni awọn akẹkọọ naa wa, wọn n mura silẹ de idanwo, ni ikọ ajinigbe naa de, iyẹn lọjọ Aje, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un ọdun 2024.
Loṣu Karun-un ọdun 2025 yii, awọn ole ori omi (Sea pirates) ji, arinrinajo mẹtala gbe loju omi Isaka Waterways, nijọba ibilẹ Okirika, ipinlẹ Rivers.
Awọn akẹkọọ oniwee mẹwaa to n rin irinajo lati lọ ṣe idanwo wọn ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si lọjọ kẹfa oṣu, Karun-un ọdun 2025.
Iya kan ti ọmọ rẹ wa lara awọn ti wọn ji gbe naa, ṣalaye nigba naa pe ọmọ oun, Baktah Benjamin, wa lara akẹkọọ mẹtala ti ajinigbe gbe sa lọ.
O ni awọn ọdọmọbinrin meje wa lara awọn ọmọ naa.














