Agbébọn ya bo ilé ìjọsìn, ṣíná ìbọn bolẹ̀, sọ iná sí i, èèyàn mẹ́rin kú
O kere tan eeyan mẹrin lo ti ku, ti awọn mẹjọ mii si farapa niluu Michigan, nilẹ Amẹrika lẹyin ti ọkunrin kan wa ọkọ ayọkẹlẹ wọ ile ijọsin kan to ṣi ṣina ibọn bolẹ nibẹ.
Yatọ si ibọn to dun lakọlakọ, afurasi naa tun sọ ina sile ijọsin ọhun.
Ọlọpaa ni ile ijọsin Church of Jesus Christ of Latter-day Saints to wa ni Grand Blanc, niluu Detroit ni ikọlu naa ti waye, ki ọlọpaa to yinbọn pa afurasi ọhun.

Wọn kede orukọ afurasi naa gẹgẹ bii Thomas Jacob Sanford to jẹ ẹni ogoji ọdun lati Burton, nipinlẹ Michigan.
Awọn alaṣẹ ni ṣe ni ọkunrin naa mọọmọ kọlu ile ijọsin ọhun amọ wọn ko le sọ eredi igbesẹ naa.
Ọga ọlọpaa agbegbe Grand Blanc, William Renye sọ nibi ipade awọn akọroyin kan lọjọ Aiku pe eeyan meji lo ku lẹkẹkẹsẹ latari ọta ibọn to ba wọn.
O fi kun pe wọn tun pada ri oku eeyan meji mii, nigba ti awọn kan ti di awati.
Bi ikọlu naa ṣe waye
Renye ṣalaye pe asiko ti awọn eeyan n jọsin lọwọ ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ni ọkunrin naa wa ọkọ wọ inu ọgba ile ijọsin ọhun.
Lẹyin naa ni afurasi ọhun ṣina ibọn bọle to si kọ oju rẹ si awọn to n jọsin lọwọ.
Kete lẹyin eyi ni awọn ọlọpaa yabo agbegbe naa ti wọn si kọ oju ibọ si i ki wọn to gbẹmi rẹ ni aago mẹwaa kọja iṣẹju mẹtalelọgbọn aarọ.
O ni "A ṣi n ṣewadii ibi pato ti ina to n jo nile ijọsin naa ti ṣẹ wa ati bo ṣe bẹrẹ ni."
Amọ wọn ni o ṣeeṣe ko jẹ epo bẹntiro ni afurasi naa da sibẹ ko to sọ ina si.
Renye tun gboriyin fun awọn olujọsin ile ijọsin naa fun igbiyanju wọn lati daabo bo awọn ọmọ wẹwẹ to wa nibẹ lasiko ikọlu naa.
Iwadii ti n lọwọ lati yẹ foonu atawọn dukia ọkunrin naa wo lọna ati le mọ bi ọrọ rẹ ṣe jẹ ni pato amọ o ti fi akoo igba kan ṣiṣẹ fun ileeṣẹ ọmọ ogun US Marine Corps ri.
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ FBI lo n lewaju iwadii ọhun.
















