Kí ló dé tí ẹnu ń kun Taye Currency lẹ́yìn ayẹyẹ ìgbadé Olubadan Ladoja?

Aworan Taye Currency

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni ọṣe to kọja, ọpọ awọn eekan ilu lo peju sibi ayẹyẹ ifinijoye Olubadan, Oba Adewolu Ladoja, Olubadan kẹrinlelogoji ti ilu Ibadan.

Aarẹ Bola Tinubu, awọn Gomina kaakiri orilẹede Naijiria, awọn lọbalọba ati eeyan nla lo wa nibi ayẹyẹ naa ṣugbọn nnkan mii lo fi ibinu si ọkan awọn ara ati ọmọ Ibadan.

Lasiko ayẹyẹ ifinijoye naa, gbajugbaja olorin Fuji lo wa korin, iyẹn Taye Currency, ti ede to si fọ lasiko to n kọrin si fa ọpọ ariyanjiyan laarin awọn ọmọ Yoruba ati lori ayelujara.

Iru Orin wo ni Taye Currency kọ nibi ifinijoye Olubadan?

Ọmọ bibi ilu Ibadan ni Taye Currency, ti o si jẹ ilumọka lagbo ere Fuj lorilẹede Naijiria ṣugbọn nigba tie de "were la fi n wo were," jade lẹnu rẹ lasiko ti o n kọrin ko Olubadan tuntun, ọpọ eeyan lo bu ẹnu atẹlu to fi mọ awọn ladelade ni ilẹ Yoruba.

Ori ayelujara kun fun ọpọ eebu fun Taye Currency pe ko yẹ wi gbolohun naa lasiko ti Aarẹ orilẹede Naijiria ati awọn eekan ilu wa ni ijoko ati pe gbolohun orin rẹ ko ni nnkan ṣe pẹlu ayẹyẹ ifinijoye to n lọ lọwọ.

Ori ade kan lati ilu Kemta ni ijọba ibilẹ Odeda nipinlẹ Ogun, Olu ti ilu Kemta Orile, Oba Adetokunbo Tejuosho naa pẹlu awọn ọmọ Yoruba to bu ẹnu atẹlu Taye Currency fun ede to pe lasiko ayẹyẹ ifinijoye Olubadan ti ilẹ Ibadan.

Oba Tejuosho ṣapejuwe ede ti Taye Currency fọ gẹgẹ bii eyi ti ko ba asa ati ilana Yoruba mu.

Ninu atẹjade to Ori ade naa fi sita fun awọn akọroyin ni gbogbo orin ti Currency kọ lo ta abuku si aṣa Yoruba, ti ko si yẹ ko jẹ iru orin bayẹn lo ma jade sita lasiko ifinijoye Olubadan.

"Ipo Oba ni ilẹ Yoruba ki I ṣe ipo yẹyẹ, ko si yẹ ko jẹ ibi ti orin a ti ma fọ ede ti ko ba ilana Yoruba mu.

"Iru orin bayẹn ko ba ilana wa mu rara, to si tabuku si ipo Oba."

Wo nnkan ti awọn araalu sọ lori ayelujara

@Frank24net loju opo X ni: "Werey la fi'wo werey jẹ orin ni? Radarada".

@olatunbosun006 ni "Idojutini gbaaa ni eyi si mọlẹbi rẹ. Ki ṣe si awọn eeyan Ibadan. Lọjọ ifinijoye?

@Fortune4me_ola: bẹrẹ pe "Ta lo fun ni mic lati kọ radarada lasiko ifinijoye.".

@OluwaferanmiDan: "Ẹjọ rẹ kọ, ẹjọ awọn to n pe wa kọrin ni. Weyrey la fi n wo weyrey ni nibi ifinijoye? Afi weyrey naa".

@babasafeez: "Ọrọ oṣelu ree nitori kilode ti ẹ ma fi mu Taye Currency dipo Oṣupa ati K1 fun ifinijoye, koda Paso ati Malaika yoo kọrin ju bayẹn lọ. Ẹ sha ma fi werey ghade lọ".

Ta ni Taye Currency?

Taye Akande Adebisi, ẹni ti ọpọ si Taye Currency, jẹ gbajugbaja olorin Fuji, to si wa lati idile olorin. O bẹrẹ iṣẹ orin ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun.

Ibeji ni Taye Currency, ti oun ai ikeji rẹ to ti di oloogbe ati mọnija rẹ, Rahman Akilapa si da ileeṣẹ orin "Currency Band" silẹ.

Ọmọ bibi ilu Ibadan ni Taye Currency, to si ti ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn eekan ilu ninu ere Fuji bii Alhaji Wasiu Alabi Pasuma.

Ọdun 2008 ni Currency kọkọ gbe orin akọkọ rẹ sita, eyi ti o pe ni Millennium, eyi to jẹ itẹwogba lagbo ere Fuji lasiko naa.

Lọwọ bayii, Taye Currency ni olorin ayẹyẹ fun ijọba ipinlẹ Oyo lati igba saa ijọba Seyi Makinde.