Wo àwọn ọ̀nà márùn ún tí àwọn ọmọ Naijiria ń gbà kojú ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty

    • Author, Yusuf Akinpelu
    • Role, BBC News
    • Reporting from, Lagos

Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti sun kan ogiri bayii latari ọwọngogo ounjẹ to gbode.

Iroyin ni nnkan bii idaji araalu lo n gbe ninu isẹ ati oṣi nitori bi wọn ko ṣe ri ounjẹ igba mẹta jẹ lojumọ.

Gbogbo rogbodiyan naa ko ṣẹyin igbesẹ ijọba apapọ lati fopin si owo iranwọ ori epo bẹntiro ati bo ṣe ja agbara owo naira silẹ.

Eyii ti n mu ki ara kan ọpọ araalu, ti awọn mii si n lọ ja gbọgan ti ijọba n ko ounjẹ pamọ si ki wọn le bọ ara wọn atawọn mọlẹbi wọn.

Yatọ si nnkan to di ọwọngogo, awọn banki naa tun ti ṣafikun ele ori owo ti awọn onibara wọn ba n ya lọwọ wọn ni ida 22.75%.

Iwọnyi ni awọn ọna ti awọn ọmọ Naijiria n gba koju ọwọngogo to gbede lasiko yii.

Ra a ki o si maa sanwo diẹdiẹ

Pẹlu ọwọngogo to gbode, o n tumọ si pe iye owo ti wọn n ta ọpọ nnkan ti le si ni ọpọ ilọpo.

Abike Jaji, to n ta aṣọ niluu Eko sọ pe san diẹdiẹ ni ọna ti oun fi n ran nnkan bayii, paapaa awọn ikoko ọbẹ kan ti oun ṣẹṣẹ ra laipẹ yii.

Obirin naa, to jẹ ẹni ọgọta ọdun sọ pe “inu oṣu Kejila ọdun to kọja ni mo ra awọn ikoko yẹn, mo ṣẹṣẹ san owo rẹ tan bayii ninu oṣu Keji ni.”

Rira nnkan loju pali

Wakeelah Lawa-Tijani to jẹ onimọ nipa eto ilera sọ pe oun ti bẹrẹ si n ra nnkan ti oun ba nilo lọpọ yanturu dipo ki oun maa ra a ni ẹyọ kọọkan.

O ni “To ba ni oun ti mo nilo, ni ṣe ni mo kuku ra a loju pali.

“Mi o ki n duro lati bere iye ti wọn ta nnkan naa nitori iṣẹju-iṣẹju ni gbogbo nnkan maa n gbowo lowo si bayii.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty

Ronu bi o ṣe le din iye owo ti o n na ku

Lootọ ni kii ṣe gbogbo eeyan lo lagbara lati maa ra ọja loju paali nitori ika ko dọgba.

Awọn mẹta kan sọ fun BBC pe awọn ti bẹrẹ si n ra ọja olowo pọku dipo olowo gọbọi ti wọn maa n ra tẹlẹ.

Yatọ si eyii, wọn tun ti dẹkun ounjẹ jijẹ nita, bẹe naa ni wọn ko ṣe faaji mọ nile ọti tabi ile ijo.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty

Darapọ mọ ajọ dida

Fun awọn eeyan ti wọn mọ pe wọn ni inawo siwaju bii igbeyawo tabi owo ile ẹkọ ọmọ, wọn ti bẹrẹ si n darapọ mọ ajọ.

Ajọ yii ni Halima Ibrahim ati ọkọ rẹ fi ṣeranwọ fun owo ti wọn n ṣe, ninu rẹ ni wọn si ti san owo ile ẹkọ ọmọ wọn.

O ni “A ya miliọnu meji nibi ti a ti n da ajọ, eyii ti a o san pada laarin oṣu mẹwaa.

O le maa da ajọ pẹlu awọn alabaṣiṣe rẹ tabi awọn alabagbe, amọ o ni lati ri daju pe awọn ti o n ba dowopọ jẹ awọn ti o le fọkan tan.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wiwa awọn ọna mii

Ninu oṣu keji ọdun yii, iye owo ti wọn n ta gaasi ti fo soke lati N800 si N1,300.

Awọn kan ti bẹrẹ si n lo eedu ati igi lati dana bayii, eyii to jẹ nnkan ti wọn ti pati tẹlẹ.