Ọlọ́pàá mú èèyàn mẹ́ẹ̀dógún lára àwọn tó fọ́ ilé tí ìjọba kó oúnjẹ pamọ́ sí l'Abuja

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọwọ ọlọpaa ti tẹ eeyan mẹẹẹdogun to lọwọ ninu bi awọn eeyan kan ṣe fọ ile ounjẹ kan l’Abuja, ti wọn si ko awọn ounjẹ naa lọ.
Ọjọ Aiku, ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun 2024, ni iṣẹlẹ naa waye.
Ọsan ọjọ Aiku ni fidio kan gba ori ayelujara, eyi to ṣafihan bi eero rẹpẹtẹ ṣe ya wọ ile kan ti wọn ko ounjẹ pamọ si.
Bo tilẹ jẹ pe Abuja ni ile ounjẹ naa wa, a gbọ pe awọn eeyan tun ya wa lati awọn ilu to sunmọ agbegbe naa, wọn si ko ounjẹ lapolapo lọ.
Ṣaaju ni iroyin sọ pe ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria, National Emergency Management agency, NEMA, lo ni ibudo naa.
Ṣugbọn ninu ikede kan to fi sita, ajọ NEMA sọ pe ile ikẹrusi naa kii ṣe ti oun.
Agbẹnusọ ajọ naa, Manzo Ezekiel, ninu atẹjade kan to fi lede fun awọn akọroyin fi di rẹ mulẹ pe isẹlẹ naa to waye lọjọ Aiku, ọjọ kẹta oṣu kẹta ọdun 2024 ko ni nnkan ṣe pẹlu ajọ NEMA sugbọn awọn ba ajọ to ni ile ounjẹ kẹdun lori ohun to waye.
Taa gan-an lo ni ile ikẹru si ti awọn eeyan ti ko ounjẹ?
Iroyin sọ pe ile ikẹrusi naa, lo jẹ ti ẹka ijọba ilu Abuja, to n mojuto idagbasoke iṣẹ agbẹ, lo ni ibudo naa.
Agbẹnusọ ẹka eto ọgbin naa, Zakari Aliyu fi di isẹlẹ naa mulẹ pe ile ounjẹ to jẹ ti ẹka naa ni awọn araalu ya wọ, ti wọn si gbe ọpọlọpọ ounjẹ lọ.
Iṣẹlẹ yii lo mu kawọn eeyan maa sọ pe ebi to wa niluu, ati ìyàn to n mu lo fa a tawọn araalu fi fọ ibẹ ti wọn ko ounjẹ lọ.
Ọwọngogo ounjẹ ati ọja ti n ba awọn eeyan finra ni Naijiria lati igba ti ijọba Aarẹ Bọla Tinubu ti yọ owo iranwọ ori epo, ṣugbọn o tun buru si i lati oṣu Kinni, ọdun 2024.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ fun ileeṣẹ iroyin Channels TV pe, gbogbo aṣiri to wa nidii iṣẹlẹ yii lo han sileeṣẹ ọlọpaa, bawọn kan ṣe fọ́ ẹka ounjẹ nile ikẹru si to wa ni Tasha, l’Abuja.
‘’A ri i bi wọn ṣe ba ọpọlọpọ nnkan jẹ nibẹ, a si ti kapa gbogbo wahala naa.
‘’Eeyan mẹẹẹdogun to jẹ afurasi ni a ti mu, meji ninu wọn jẹ ọlọdẹ to n ṣọ ile ounjẹ naa.‘’
Apo agbado mẹrindinlọgbọn (26), ọkada marun-un ati awọn nnkan tawọn eeyan naa bajẹ ni wọn ri gba lọwọ wọn bi wọn ṣe sọ.
A ti gba awọn ẹsọ alabo to dabo bo ile ounjẹ wa- NEMA
Lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye ni ajọ NEMA ti ko awọn oṣiṣẹ alaabo lati daabo bo awọn ile ounjẹ kaakiri orilẹede Naijiria.
Ọga agba fun ajọ naa lo gbe aṣẹ naa kalẹ fun awọn ẹka NEMA kaakiri Naijiria .
“Lati le ma fi aye silẹ fun yiyawọ ile ounjẹ NEMA, ọga agba ajọ naa, Mustapha Habib Ahmed ti palasẹ fun gbogbo ọga ẹka NEMA kaakiri lati fikun idabo si awọn ile ounjẹ ati kaakiri ileeṣẹ NEMA kaakiri orilẹede Naijiria.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post












