Ẹ dá owó símẹ́ǹtì padà sí iye tí ẹ̀ ń tà á tẹ́lẹ̀- Aarẹ Tinubu paṣẹ

Aare Bola Ahmed Tinubu

Aarẹ orilẹ-ede yii, Bọla Ahmed Tinubu, ti paṣẹ fawọn ileeṣẹ to n ṣe simẹnti, pe ki wọn da iye owo rẹ pada si bo ṣe wa tẹlẹ.

Minisita fun ọrọ iṣẹ ode, Sẹnetọ David Umahi, sọ eyi di mimọ fawọn akọroyin niluu Ṣokoto, lẹyin to ṣabẹwo si ileeṣẹ simẹnti BUA to wa nibẹ.

Lasiko ti Adari ileeṣẹ simẹnti naa, Alaaji Kabiru n ṣalaye fun Minisita lo ni ẹgbẹrun mẹfa naira lawọn n ta apo kan.

O ni eyi wa ni ibamu pẹlu aṣẹ Aarẹ Tinubu, pe apo simẹnti kan ko gbọdọ ju ẹgbẹrun meje naira lọ nibi gbogbo ni Naijiria.

‘’Aarẹ duro lori ipinnu rẹ pe ki wọn da a pada siye ti wọn n ta a tẹlẹ, ko le baa rọrun faraalu lati ra.

Minisita Umahi ni tiẹ ṣalaye, ‘’Lori iye ti wọn n ta simẹnti, mo le fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe wọn ṣi le ṣe atunṣe pẹlu ohun ti Aarẹ ba wọn sọ.

‘’Aarẹ duro lori ipinnu rẹ pe ki wọn da a pada siye ti wọn n ta a tẹlẹ, ko le baa rọrun faraalu lati ra.

‘’Mo fẹẹ rọ awọn onileeṣẹ simẹnti, pe ki wọn tẹle aṣẹ Aarẹ Tinubu, ki ireti ile kikọ yanturu le wa si imuṣẹ, pẹlu ọna to ṣee rin geere’’.