Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ìlẹ̀kẹ̀ ara adé ọba ní ohùn? Asíndẹ Olamilekan ṣàlàyé èèwọ̀ tó wà níbẹ̀

Àkọlé fídíò, Fila Asinde fun awon oba
Aworan asinde

Iṣẹ Asindẹ jẹ ọkan lara awọn iṣẹ abalaye nilẹ Yoruba.

Awọn to n ṣe irufẹ iṣẹ yii lo maa n sin ilẹkẹ sara ade ati ọpa ọba.

Ọgbẹni Idris Adio Olamilekan ti inagijẹ rẹ n jẹ Owo Orogbo jẹ ọkan lara awọn to si n ṣiṣẹ yii.

Ọgbẹni Olamilekan to jẹ ọmọbibi Oke-ona ni ipinlẹ Ogun ni oun yan iṣẹ asindẹ laayo tori pe ''baba mi lo sọ fun mi pe ko gbọdọ parun.''

"Iṣẹ telọ aranṣọ ni mo kọ ni ibẹrẹ aye mi, amọ, lati kekere ni mo ti maa n wo bi baba baba maa se n ṣe iṣẹ asindẹ yii.

Iṣẹ to ni ere lori ni, iṣẹ ti mo fi bímọ, ti mo fi fẹ iyawo, ti mo fi kọ ile.

Ko si iṣoro to le ba mi ti mo maa fi pada sẹnu iṣẹ telọ titi aye maa fi parẹ," Ọgbẹni Olamilekan ṣalaye.

O fikun ọrọ rẹ pe "a maa n sin ilẹkẹ lati aarọ ti bi ago mefa irọlẹ.

Ti oorun ba ti wọ, a gbọdọ sin ilẹkẹ yẹn mọ, ti a ba fi tipatipa tẹsiwaju lati maa sin ilẹkẹ naa, o maa fa aisan ara fun èni to n ṣiṣẹ naa.

Awon ọba ti mo ti ṣiṣẹ fun ni Alake ana, Oyebade Lipede.

Nigba ti wọn waja, o kan baba wa Gbadebo, mo ṣiṣẹ fawọn naa.

Lẹyin naa, mo tun ṣiṣẹ fawọn ọba mii bii Oba Agura, Osilẹ, Olowu ati bẹẹ bẹẹ lọ.''