Ọkùnrin kan ṣekúpa ọrẹ rẹ pẹ̀lú irin gáàsì l'Ondo

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Adebayo Peter ni o ti gba ẹmi ọrẹ rẹ ti orukọ rẹ n jẹ Lekan nipinlẹ Ondo.

Iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Ireakari Oloko ni ijọba ibilẹ guusu Akure.

Peter ni iwadii fihan pe o ti lo egbogi oloro lasiko to ṣekupa ọrẹ naa.

Ọwọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ondo tí tẹ Adebayo tí oku oloogbe si ti wa ni ile igbe oku si.

Oloogbe ati afurasi ni iwadi fihan pe wọn jẹ ọmọ ilu Ede nipinlẹ Osun.

Osojumikoro to ba awọn ileeṣẹ iroyin abẹle sọrọ ni Peter àti Lekan ni ede ayede kan ko di pe Peter lọ gbe irin gàási, to si fọ mo Lekan lórí.

"Ariwo ọkan lara awọn ọrẹ wọn ní a gbọ, nigba ti a de sinu yara ti iṣẹlẹ ti waye, a ba Lekan ninu agbara ẹjẹ.

"Lekan si wa laye lasiko naa sugbọn ko pẹ to jade laye, lẹsẹkẹsẹ ni a ransẹ pe Ileeṣẹ Ọlọpaa."

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ondo,Funmilayo Odunlami Omisanya ni afurasi naa ti wa ni akata ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ondo, ti iwadii si ti bẹrẹ.