Ẹgbẹ́ òsìṣẹ́ Labour so ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn rọ̀

aworan

Ẹgbẹ́ òsìṣẹ́ Labour so ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn rọ̀

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ti Nigeria Labour Congress (NLC) kaakiri orileede Naijiria to sọ pe awọn yoo so iwọde ifẹhonuhan wọn rọ fun igba diẹ.

Wọn ni awọn ti mu erongba awọn wa si imuṣẹ pẹlu bi ọpọ eeyan ṣe jade sita lọjọ akọkọ lati fẹhonu wọn han lori ọwọngogo, ebi ati iṣẹ to n ba araalu finra lasiko yii.

Labour lo kede yii lalẹ ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, ninu atẹjade ti aarẹ ẹgbẹ naa, Joe Ajaero ati akọwe fidihẹ wọn, Ismail Bello, ti wọn si ni to si ni eto ọhun n tẹsiwaju pẹlu ipade awọn oniroyin ti yoo waye kaakiri ipinlẹ, to fi mọ ilu Abuja.

Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe awọn yoo tun fun ijọba apapọ ni gbedeke ọjọ mẹrinla, ko to di pe awọn wa bẹrẹ igbesẹ wọn lori ajọsọ ati iwe adehun ti wọn tọwọbọ lọjọ keji, oṣu kejila ọdun to kọja.

Labour ni bi ijọba ba kọ lati mu awọn ileri to wa ninu iwe adehun ti wọn jọ tọwọ bọ ṣẹ, ko si ohunkohun to tun le da awọn duro lati bẹrẹ iwọde ifẹhonuhan tuntun.

Nibi ifẹhonuhan to waye ni ẹgbẹ oṣiṣẹ Labour ti pe gbogbo oṣiṣẹ jakejado, awọn ileeṣẹ, ajọ ati gbogbo eeyan lati jade fẹhonuhan iṣẹ, ebi ati iya to n jẹ araalu ni Naijiria.

Kaakiri gbogbo ipinlẹ to wa lorileede Naijiria ni ifẹhonuhan yii ti waye, bo tilẹ jẹ pe ko pa ilana iṣẹ ijọba, awọn banki ati awọn iṣẹ miran lara.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Atẹjade ọhun ṣalaye pe

“Lati so iwọde ọlọmeji wa rọ fun igba diẹ jẹ eyi ti a ti ṣe aṣeyọri to pọ ni ọjọ akọkọ ti a bẹrẹ.

“Ṣugbọn sibẹ, eto yii n tẹsiwaju ni ọla (Ọjọru, oni) pẹlu ipade awọn oniroyin kaakiri ipinlẹ to wa lorileede yii. Awọn alakoso ẹgbẹ ni yoo ṣagbatẹru ẹ, to fi mọ olu ileeṣẹ wa to wa ni Abuja

“Lati fidi rẹ mulẹ ati pe a tun n fi gbedeke ọjọ meje ai afikun ọjọ meje lelẹ bayii, ti yoo si pari lọjọ kẹtala, oṣu kẹta, ọdun 2024 pẹlu erongba wi pe ijọba apapọ yoo mu awọn ileri to wa ninu iwe adehun ọjọ keji, oṣu kẹwaa, ọsun 2023 pẹlu awọn ohun ti a tun n beere nibi ifẹhonuhan wa loni ṣẹ.

“A maa tun pade lati gbe igbesẹ to kan lẹyin ti ọjọ mẹrinla yii ba pe, ti ijọba apapọ ba kọ lati ṣe awọn ohun ti a n fẹ laarin asiko yii.

“Lẹẹkan sii, igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ NLC yoo maa ṣagbatẹru ifẹ araalu, ati ireti awọn oṣiṣẹ Naijiria pẹlu awọn araalu to jiṣẹ-jiya.”

Ariwo sọ lasiko ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde fi ara han ni agbegbe Total Garden niluu Ibadan nibi ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti n fi ẹhonu han lori ọwọngogo ounjẹ ati ohun elo lọjọ Iṣẹgun.

Ṣugbọn ariwo to sọ fi han wi pe ara ti kan awọn eeyan de ibi pe wọn ko fẹ ri Gomina gan an soju.

Awọn to wa nibi ifẹhonuhan naa mu ariwo bọ ẹnu wi pe, "Rara! A ko le gba ki Gomina ba wa sọrọ, gbogbo wọn ni wọn ba Naijiria jẹ".

Bi wọn ṣe n fi ẹhonu han pẹlu ọrọ ẹnu ni wọn tun n kọ ọkanojọkan orin eebu ti wọn si n ṣafihan oriṣi patako ajuwe.

Lẹyin ọpọlọpọ lilọbibọ ati awuyeye to rọ mọ ifarahan Gomina, awọn alakoso ẹgbẹ oṣiṣẹ naa gba ki Gomina ba awọn eeyan sọrọ.

Ki wa ni Makinde pa sọ fawọn olufẹhonuhan?

Aworan Gomina Seyi Makinde

Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ lásìkò tí Seyi Makinde yọjú síbi ìfẹ̀hónúhàn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní Ibadan

Ẹgbẹ́ òsìṣẹ́ Labour so ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn rọ̀

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ti Nigeria Labour Congress (NLC) kaakiri orileede Naijiria to sọ pe awọn yoo so iwọde ifẹhonuhan wọn rọ fun igba diẹ.

Wọn ni awọn ti mu erongba awọn wa si imuṣẹ pẹlu bi ọpọ eeyan ṣe jade sita lọjọ akọkọ lati fẹhonu wọn han lori ọwọngogo, ebi ati iṣẹ to n ba araalu finra lasiko yii.

Labour lo kede yii lalẹ ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, ninu atẹjade ti aarẹ ẹgbẹ naa, Joe Ajaero ati akọwe fidihẹ wọn, Ismail Bello, ti wọn si ni to si ni eto ọhun n tẹsiwaju pẹlu ipade awọn oniroyin ti yoo waye kaakiri ipinlẹ, to fi mọ ilu Abuja.

Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe awọn yoo tun fun ijọba apapọ ni gbedeke ọjọ mẹrinla, ko to di pe awọn wa bẹrẹ igbesẹ wọn lori ajọsọ ati iwe adehun ti wọn tọwọbọ lọjọ keji, oṣu kejila ọdun to kọja.

Labour ni bi ijọba ba kọ lati mu awọn ileri to wa ninu iwe adehun ti wọn jọ tọwọ bọ ṣẹ, ko si ohunkohun to tun le da awọn duro lati bẹrẹ iwọde ifẹhonuhan tuntun.

Nibi ifẹhonuhan to waye ni ẹgbẹ oṣiṣẹ Labour ti pe gbogbo oṣiṣẹ jakejado, awọn ileeṣẹ, ajọ ati gbogbo eeyan lati jade fẹhonuhan iṣẹ, ebi ati iya to n jẹ araalu ni Naijiria.

Kaakiri gbogbo ipinlẹ to wa lorileede Naijiria ni ifẹhonuhan yii ti waye, bo tilẹ jẹ pe ko pa ilana iṣẹ ijọba, awọn banki ati awọn iṣẹ miran lara.

Atẹjade ọhun ṣalaye pe

“Lati so iwọde ọlọmeji wa rọ fun igba diẹ jẹ eyi ti a ti ṣe aṣeyọri to pọ ni ọjọ akọkọ ti a bẹrẹ.

“Ṣugbọn sibẹ, eto yii n tẹsiwaju ni ọla (Ọjọru, oni) pẹlu ipade awọn oniroyin kaakiri ipinlẹ to wa lorileede yii. Awọn alakoso ẹgbẹ ni yoo ṣagbatẹru ẹ, to fi mọ olu ileeṣẹ wa to wa ni Abuja

“Lati fidi rẹ mulẹ ati pe a tun n fi gbedeke ọjọ meje ai afikun ọjọ meje lelẹ bayii, ti yoo si pari lọjọ kẹtala, oṣu kẹta, ọdun 2024 pẹlu erongba wi pe ijọba apapọ yoo mu awọn ileri to wa ninu iwe adehun ọjọ keji, oṣu kẹwaa, ọsun 2023 pẹlu awọn ohun ti a tun n beere nibi ifẹhonuhan wa loni ṣẹ.

“A maa tun pade lati gbe igbesẹ to kan lẹyin ti ọjọ mẹrinla yii ba pe, ti ijọba apapọ ba kọ lati ṣe awọn ohun ti a n fẹ laarin asiko yii.

“Lẹẹkan sii, igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ NLC yoo maa ṣagbatẹru ifẹ araalu, ati ireti awọn oṣiṣẹ Naijiria pẹlu awọn araalu to jiṣẹ-jiya.”

Ohun akọkọ ti Gomina Ṣeyi Makinde sọ nipe oun ko wa lati dẹkun ifẹhonuhan ti wọn n ṣe nitori gbogbo ọmọ Naijiria lo lẹtọ lati fi ẹhonu han lori ohunkohun ti ko ba tẹ wọn lọrun.

Makinde fi kun ọrọ rẹ wi pe ki gbogbo awọn to n kọrin pe oun naa lọwọ si bi Naijiria ṣe bajẹ ranti pe ẹni ọdun mẹrindinlọgọta pere ni oun, bẹẹ sini oun ko tii lo ju ọdun marun un lọ ninu iṣejọba ipinlẹ Ọyọ.

O ni ti wọn ba tiẹ ka ohun mọ awọn to ba Naijria jẹ, oun tun fẹ wa lara awọn ti yoo tun Naijiria ṣe.

Makinde ni pupọ awọn anfani ti awọn oṣiṣẹ ijọba ni awọn ipinlẹ mii ko tii maa jẹ ni awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ti n ri gba lati inu ọdun to kọja wọ inu oṣu keji ọdun yii.

Lẹyin atotonu Gomina, awọn alakoso ẹgbẹ oṣiṣẹ fi iwẹ akọsilẹ awọn ẹtọ ti wọn n beere fun le Gomina lọwọ, o ṣi ṣe ileri wi pe oun yoo jiṣẹ wọn fun aarẹ Bọla Ahmed Tinubu.

Ṣaaju ifẹhonuhan to bẹrẹ jakejado orilẹede Naijiria lonii ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ti fun ijọba apapọ ni gbedeke ọjọ mẹrinla lati wa ojutu si iṣoro to n ba awọn ọmọ Naijiria finra, aiṣẹ gẹgẹ bi ẹgbẹ naa ṣe wi lo mu ki wọn bẹrẹ ifẹhonuhan ọlọ meji to bẹrẹ lonii.

Aworan Gomina Makinde
Ìfẹ̀hónúhàn wa kò ní i ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú kankan, ebí n pa ará ìlú- NLC Ondo
aworan
Àkọlé àwòrán, Awon osise nipinle Ondo

Igbayegbadun awọn oṣiṣẹ ati awọn ọmọ Nàìjíríà ló jẹ waa logun, a o fi ti ẹgbẹ oṣelu ṣe - Alaga NLC ni ipinlẹ Ondo Victor Amoko

Ṣe ni àbá awọn ọmọ naijiria gbe ẹbọ wọn soke lati sọ fún ìjọba iya ati ìnira to wa nilu

Ọdun márún ti iwe òfin fi kalẹ fún àgbéyẹ̀wò owo oṣù awọn oṣiṣẹ ti pe, ọfin ni a n tẹlẹ lori ìbere waa fún àfikún owo

Awọn ọmọ ẹgbẹ́ oṣiṣẹ ni orilẹede naijiria ẹka ti ipinlẹ Ondo labẹ àsìá NLC ti ṣe ìwọ́de lati fi aidunnu wọn hàn lórí ọrọ ajé orileede yii ti wọn ni o ti mu inira ba awọn oṣiṣẹ ati awọn ọmọ orílẹ̀èdè

naijiria

Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC

Awon oluwọde ọun ti alaga NLC ẹka ti ipinlẹ Ondo le waaju ọgbẹni Victor Amoko bẹrẹ ifehonuhan wọn lati ile ẹgbẹ oṣiṣẹ naa towa ni agbegbe Alagbaka ni ilu Akure ti won si gbe patako pẹlu orisirisi akọle sì ìjọba àpapọ̀ bi:

"Emu opin sì ẹbi opgbafowomeke ti awọn ọmọ orileede Naijiria nkoju" "igbedide awọn oriko ifonpo ṣe kọkọ" ẹgba ọwọ Orí lọwọ awọn olowo, ẹfun awọn tálákà ni nnkan iranlọwọ" ati bẹ bẹ lọ

Awọn oṣiṣẹ naa rìn lati Ile ẹgbẹ NLC dé ọfisi gomina ipinlẹ Ondo ni bi ti won ti kọ ọpọlọpọ orin òwe

Ninu ọrọ rẹ, alaga NLC ti ipinlẹ Ondo, Amoko sọ pe o ṣe pàtàkì ki ìjọba dẹkun ìnira awọn oṣiṣẹ ki wọn sì ṣẹ imusẹ awọn adehun ti wọn ba ẹgbẹ naa ṣe

Ogbeni Amoko sọ pe, iwọde ifehonuhan naa ko ni ṣe pẹlu ẹgbẹ oṣelu kankan tàbí wípé ẹgbẹ oṣelu kan lon ti awọn oṣiṣẹ lẹyìn lati ṣe ìwọ́de

Amoko sọ pe " to bajẹ awọn araalu lọn ṣe ìwọ́de, ìjọba lẹ ro pe awọn kan abi ẹgbẹ oṣelu kan lọn kii wọn lẹyìn, ṣugbọn bayi, gomina ipinlẹ Ondo kole sọpẹ ẹgbẹ oṣelu kan lọn lo awa ẹgbẹ oṣiṣẹ.

" Àwaa ni ore-ọfẹ lati so fún gomina ati ààrẹ nnkan to nje awọn araalu níyà, paapajulo ìṣòro ati ìnira awọn oṣiṣẹ to jẹ ọmọ egbe wa"

Amoko sàlàyé pe, ninu iwe òfin orileede Naijiria, ọdun márún márùn ni o ye ki agbeyewo owo oṣù awọn oṣiṣẹ jẹ ko ma waye. Bayi bi owo ounjẹ ṣen lọ sókè, owo oṣù oṣiṣẹ to kere julọ ko to nnkan mọ.

" Ni ọdun 2020 ti aarun korona wa, awaa ẹgbẹ oṣiṣẹ o bere fún àfikún owo pelu gbogbo ìnira to wa, be na ni odun 2021 ati odun 2022 pelu' aiko ti to lati ṣe àgbéyẹ̀wò owo oṣù awọn oṣiṣẹ."

Lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣiṣẹ to kopa ni ẹgbẹ awọn olukọ (NUT), Ẹgbẹ awọn akọroyin (NUJ) ati awọn miran

Ìjọba ipinlẹ Ondó Fesi sì ifehonuhan awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ

Kini awon Osise ipinle Ondo tun sọ

Olori oṣiṣẹ ìjọba ti ipinlẹ Ondo pasitọ Kayode Ogundele ti o ba awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ naa sọrọ sọpẹ ìjọba ìpínlè Ondó gẹgẹ bi o ti ni ṣe yóò ma mu igbelarugẹ igbayegbadun awọn oṣiṣẹ. O sọpẹ orisirisi agbekalẹ ni ìjọba ìpínlè naa ti ṣe fún iranwọ awọn oṣiṣẹ bi eto ọkọ ọfẹ to n gbe awọn oṣiṣẹ ati owo iranwo egeberun marundilogoji náírà"

Pasitọ Ogundele ni Gomina Lucky Aiyedatiwa yoo te pepe awọn ibere ẹgbẹ oṣiṣẹ na fún ìjọba apaapo fún igbesẹ to yẹ.

Owo ewu lẹnu isẹ fún awọn dokita L'ondo yóò bẹrẹ losu kẹta

Olórí awọn oṣiṣẹ Kayode Ogundele nígbà to n ba awọn ọmọ egbe oṣiṣẹ sọrọ nibi iwọde to waye ni ilu Akure, kede pe awon dokita yii bere si ni gba owo ewu lẹnu isẹ lati oṣù kẹta

Ẹgbẹ awon dokita n'ipinlẹ Ondo ni wọn ti ṣaaju dunkoko idaṣesilẹ ti wọn sì fún ìjọba ni gbendeke ọjọ meje fún sisan owo ewu ẹnu isẹ ti won ti ṣaaju bọwọlu. Ṣugbọn ti won so idaṣesilẹ na kọ.

Nibi Ipade won ni oṣù yii ni awon dokita naa ní, lati oṣù Kejìlá ọdun 2021 ni afenuko tiwaye fún sisan owo ewù lénu isẹ fún awọn dokita lorileede naijiria ti ìjọba àpapọ̀ sì ti bẹrẹ sisan owo naa fún awon oṣiṣẹ rẹ ti awọn ipinlẹ kan jakejado naijiria sì ti bẹrẹ sisan ọwọ naa. Paapajulo ni ipinlẹ Ekiti ti o múlẹ ti ipinlẹ Ondo ni awọn dokita níbè tin jẹ anfani naa lati bi ọdun kan.

Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ti bẹrẹ ifẹhonuhan niluu Eko lori ọwọngogo to gbode lorilẹede Naijiria.

Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC

Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ti n ko ara wọn jọ si ile ẹgbẹ wọn ti wọn n pe ni Labour House niluu Abuja fun ifẹhonuhan oni.

Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC

Awọn ọlọpaa duro wamuwamu bi awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ṣe bẹrẹ ifẹhonuhan l'Ekiti

Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC

Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC naa ko ara wọn jọ niluu Ilorin fun ifẹhonuhan

Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ọlọpaa
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC
Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn lórí ọ̀wọ́ngógó tó gbòde ní Nàìjíríà

Aworan ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC

Oríṣun àwòrán, Nigeria Labour Congress/X

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, Nigeria Labour Congress (NLC) bẹrẹ ifẹhonuhan lori ọwọngogo to gbode kaakiri orilẹede Naijiria lonii.

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ pe fun iwọde yi jakejado orileede Naijiria lati le jẹ ki ijọba mọ pe inu araalu ko dun sibi ilu ko ṣe fararọ.

Ṣaaju asiko yii ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ, DSS ti rọ ẹgbẹ NLC lati so ifẹhonuhan ti wọn fẹẹ ṣe rọ fungba diẹ, pẹlu erongba lati gba alaafia laaye.

Bakan naa ni agbejoro agba ati Minisita fọrọ eto idajọ ni Naijiria, Lateef Fagbemi rawọ ẹbẹ sẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, lati pa ifẹhonuhan ti wọn fẹẹ ṣe sẹgbẹ kan.

Ninu lẹta ti minisita naa kọ ranṣẹ si ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC laipẹ yii lo ti sọ pe iwe aṣẹ kan wa nilẹ to tako igbeṣẹ ẹgbẹ naa lati jade ṣe iwọde ifẹhonuhan lasiko yii.

Agbejọro agba naa sọ pe igbesẹ tabi erongba NLC yii jẹ eyi to ṣi wa niwaju ile ẹjọ ti National Industrial Court.

O fikun ọrọ rẹ pe ifẹhonuhan ti ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹẹ ṣe yii ni wọn lo tako aṣẹ ti ile-ẹjọ pa, ti igbẹjọ naa ti wọn ṣi fi ti ṣẹgbẹ kan ṣi n lọwọ

Ati pe igbesẹ ọhun yoo tun tako aṣẹ ti ile-ẹjọ gbe kalẹ nipa dida alaafia ilu laamu.

Ẹwẹ, ijọba apapọ tun ṣe ipade pajawiri pẹlu ẹgbẹ oṣisẹ lalẹ ọjọ Aje lori iwọde ti wọn fẹ ṣe.

Amọ, ẹgbẹ oṣisẹ NLC fi aake kọri pe ifẹhonuhan naa yoo waye kaakiri orilẹede Naijiria lonii ọjọ Iṣẹgun ati Ọjọru.

Ṣugbọn ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC ti wọn ti yọwọ nibi ifẹhonuhan yii, lẹyin ti ẹgbẹ ọhun kede pe awọn o ni kopa ninu ifẹhonuhan ti NLC fẹ ṣe.

Ẹgbẹ TUC ni awọn ko mọ igba ti NLC n gbero lati ṣe ifẹhonuhan kaakiri Naijiria.

Wọn ni NLC ko bawọn ṣe ipade pọ rara lori erongba wọn lati ṣe ifẹhonuhan.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ti jẹjẹ aabo to peye fawọn olufẹhonuhan.

Amọ, wọn sọ pe awọn ko ni jawọ lati ri wi pe wọn ko faaye gba ki wahala ati ikọlu kankan waye nibẹ.

Alukoro agba ileeṣẹ ọlọpaa lo fidi ọrọ yi mulẹ ninu atẹjade kan tui wọn fi sita lalẹ ọjọ Aje.