Ìfẹ́ tó sọnu nilẹ̀ Yorùbá ló mú kí wàhálà pọ̀ lorílẹ̀èdèNàìjíría-Ooni Ife

Aworan Ooni Ife

Ọba Adeyeye Ogunwusi Enitan Ooni ti Ile-Ife ti beere fun idapada ifẹ to sọnu laarin ọmọ Yoruba.

Ọrọ yii waye lakoko ayẹyẹ ọdun Aje Olokun ti ọdun 2024 to waye ni ilu Ile-Ife.

Ọba Adeyeye Ogunwusi salaye wi pe, ko si ifẹ ati ẹmi irẹpọ lo mu wahala ko pọ laarin ọmọ Yoruba ati ni orile-ede Naijiria.

Kabiyesi tun tesiwaju pe, laisi ifẹ, yoo soro fun Aje lati mọọ ba ọmọ Yoruba gbe.

"Gẹgẹ baa ti mọ pe, ti ko ba si Aje ko le si alaafia ninu ile."

Lẹhin ti Kabiyesi gba gbogbo ọmọ Yoruba ati orile-ede Naijiria ni imọran tan,Kabiyesi Ooni tí Ile-Ife gbe igba Aje lo si ile aje lati wure fun gbogbo eeyan patapata.

Iya Laje fun gbogbo ọmọ Oduduwa Toyin Kolade sọ pataki ọdun Aje pe Aje jẹ ohun koṣemani fun gbogbo eeyan.

Iya Laje tun tesiwaju wi pe, Aje jẹ orisa akọkọ ninu Irinwo ati ẹyọ kan orisa to wa ni ilẹ Yoruba.

"Paapa julọ, aje jẹ ohun ti gbogbo orisa to ku ma bere fun lakoko ọdun wọn."

Arabinrin Toyin Kolade, wa gba gbogbo ọmọ orile-ede Naijiria ni imọran lati tọju asa Yoruba daada ati lati ma gbadura fun ẹmi ìṣọ̀kan ki orile-ede Naijiria le gba ominira lọwọ iji nto ja lọwọ ni orile-ede yii.

Idowu Phillips ẹni ti gbogbo eeyan mọ sí Iya rainbow na ti sọ pataki ọdun Aje ati oun to rọ mọ ọdun aje.

Idowu Phillips sọ nigba ti o ba BBC Yoruba sọrọ nibi ọdun Aje.

Arabinrin Idowu wi pe, ni gbogbo akoko ti wọn ba ti se ọdun aje ni ohun ma wa ni bẹ ati pe gbogbo oun ti oun ba bere lasiko ọdun aje ni Olodumare ma se fun ohun.

Ọpọlọpọ ẹbun ni Kabiyesi Ọba Adeyeye Ogunwusi fun awọn eeyan to wa si bi ayẹyẹ ọdun aje. Bakan naa ni Iya Laje naa pin ẹbun fun awọn eeyan to pesẹ si bi ayẹyẹ ọdun aje ọdun 2024.

Aworan ọdun Aje

Ọdún Ajé 2024 tí ń gbéra sọ ní Ile Ife pẹ̀lú àwọn àwòdamiẹnu àwòrán

Aworan ọdun Aje ni ile Ife

Ọdun Aje to maa n waye lọdọọdun ni Ile Ife nipinlẹ Osun ti bẹrẹ ni pẹrẹwu.

Orisa Aje je ọkan lara awon orisa ilẹ Oodua ti wọn n bọ ni ilu Ile Ife nipinle Osun ni guusu Iwo oorun Naijiria.

BBC Yoruba ba wọn peju pese sibi ti wọn ti se ajodun orisa Aje ti odun 2024 ni Ile Ife.

Ayaworan wa ka awọn awodamiẹnu aworan kan to ṣafihan awọneekan lorisi to peju sibi ọdun yi.

Ninu wọn la ti ri awọn ọmọ ilu Ile Ife ati awọn gbajumọ ṣoere tiata Yoruba ni Naijriia.

Die ree ninu awọn aworan yii:

Aworan awọn oniṣẹṣe ọdun Aje
Idowu Phillips Mama Rainbow naa bawọn peju sibẹ
Oloye Kanran ṣere tiata Yoruba naa wa nibẹ
Ijo ati orin ṣe pataki lasiko ọdun yi

Oríṣun àwòrán, BBC

Awọn to wa kopa nibi ajọdun ọdun Aje ni Ile Ife
Ile Odua nibi ti ọdun naa ti n waye