Àwọn ohun tó rọ̀ mọ́ àbájáde àbá òfin Ghana tó takò ìbálòpọ̀ akọsákọ LGBTQ+ rèé

Oríṣun àwòrán, AFP
- Author, Thomas Naadi, Esther Ogola & Beryl Munoko
- Role, BBC News Accra, Nairobi and London
- Author, Thomas Naadi
- Role, Journalist
Abadofin to tako ibalopọ akọsiakọ tabi abo si abo ti ri itẹwọgba awọn ile aṣofin Ghana lẹyin ti o kọja ipele kika ẹlẹẹkẹẹta ati ijiroro.
Abadofin yi tunmọ si pe ẹnikẹni ti wọn ba mu pe o n hu iwa bayii yoo ṣewọn to ọdun meta.
Ẹnu ile aṣofin ko nípa itẹwọgba aba ti igbimọ to sagbeyẹwo abadofin yi gbe wa siwaju wọn.
Amọ olori ọmọ ile to pọju Alexander Afenyo-Markin tako ijiya ẹwọn fún awọn tó n ṣe ati awọn agbatẹru rẹ.
Kaka bẹẹ o ni ki wọn ṣe iṣẹ isinru dipo ṣiṣe ẹwọn.
Odun 2021 ni abadofin yi kọkọ de iwaju ile
Nile, loko ati lẹyin odi ni abadofin naa ti mu awuyewuye wa lati ọdọ awọn ti wọn pe ara wọn ni ajafẹtọ-ọmọniyan
Ki lo ṣokunfa abadofin yii?
Lati ilẹ lawọn eeyan Ghana ti ri Ibalopọ akọsiakọ gẹgẹ bi iwa ọdaran.
Ṣugbọn awọn aṣofin to sagbatẹru rẹ sọ pe awọn gbe kalẹ ni idahun sí idasilẹ ibudo itẹsiwaju ati iranwọ fawọn akọsiakọ ni Ghana loṣu kini odun 2021.
Ile asofin agba Ghana,Imam Agba ati agbarijọpọ awọn to n ṣe igbelarugẹ ìwà Ibalopọ to tọ laarin idile ati awọn mii panupọ lati sọ pe ki wọn ti ibudo yi pa ki awọn to ṣe idasilẹ rẹ si foju wina ofin.
Wọn ní ibudo yi ati awọn to n hu iwa akọsiakọ ni Ghana ko huwa ni ibamu pẹlu aṣa orileede naa.
Tori naa wọn ni ki wọn f'agbara kún awọn ofin to tako ihuwasi akọsiakọ nilẹ naa.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ki l'ohun ti igbimọ da laba lori abadofin yi ninu abajade wọn?
Nigba ti wọn kọkọ gbe abadofin yi wa siwaju ile awọn aṣofin bẹnu atẹ lu ati ọpọ iwe itako si waye.
Wọn dari ọrọ rẹ sọdọ igbimọ ile to n ri si ọrọ ofin ati ọrọ ile aṣofin lati fi awọn ẹhonu araalu sinu agbeyẹwo rẹ.
Igbimọ daba ki wọn mu adinku ba iye ọdun ti ijiya la kalẹ lati ṣewọn amọ ko yẹ lori pe eyikeyii ìṣesí to ba jọ iwa akọsiakọ sṣi lodi sí ofin to si jẹ iwa ọdaran.
Ile aṣofin ko gbe aba wọnyii jade si'ta faraye ṣugbọn awọn iwe ti BBC to tọka si wi pe awọn aba to wa ninu rẹ ni pe:
- O lodi sí ofin lati pe ara eeyan ni akọsiakọ LGBTQ+.Ijiya ẹwọn ọdun mẹta lo mu dani.Wọn di eleyii ku ni lati ọdun marun un ti wọn daba ṣaaju.
- Ṣíṣe agbatẹru ayẹyẹ tabi akojọpọ LGBTQ+ tako ofin.Ijiya ẹwọn ọdun marun un lo ba de dipo mẹwaa ti wọn daba tẹlẹ.
- Ṣíṣe akojọ tabi idasilẹ ẹgbẹ LGBTQ+ tako ofin.Ijiya ọdun marun un lo pọ ju fún ẹnikẹni to ba ṣe bẹẹ dipo ọdun mẹwaa to wọn daba tẹlẹ.
- Wọn yoo gba araalu niyanju lati tọka iru ẹni tó bá n hu iwa yi si awọn alaṣẹ ki wọn baa le gbe igbesẹ to tọ.Ijiya ẹwọn ọdun mẹwaa lofin la kalẹ fun ẹnikẹni to ba n foju sí ọmọde lara fún Ibalopọ ti ko tọ
- Atilẹyin fawọn ọrọ to nise pẹlu Ibalopọ akọsiakọ wa pẹlu ẹwọn ọdun marun un.
Wọn ti gbọn abala abadofin naa to sọrọ nipa ṣiṣe itoju iyipada ọkan fawọn to ba n huwa Ibalopọ LGBTQ+.
Wọn ṣe atunse awọn gbolohun kọọkan naa ninu abadofin ọhun

Oríṣun àwòrán, AFP
Ki lawọn iriwisi to tẹle ikede yii?
Amnesty International takò abadofin ọhun ti wọn sì ni o n sagbatẹru inunibini si awọn to foju han gẹgẹ bi LGBTQ+.
Ajọ iṣọkan agbaye juwe rẹ gẹgẹ bi ofin ideyesi ti wọn fi n sọ awọn to lè arawọn ni LGBTQ+ ni ọdaran.
Àwọn ajafẹtọ-ọmọniyan mii naa bẹnu atẹ lu abadofin yii.
Ajọ to n mojuto ọrọ aarun Aids ni Ghana sọ pe gbogbo aṣeyọri awọn lati dẹkun aarun HIV ni abadofin yi yoo ṣe ifasẹhin fun tori pe awọn to ni aarun yi ọkan wọn ko ní balẹ.
Awọn ileeṣẹ ati ọlọdani mii tí sọ pe abadofin yi yoo ṣe akoba fun ibaṣepọ Ghana ati awọn orileede mii paapaa awọn orileede Yuroopu nípa karakata ọrọ aje.
Ipa wo ni abadofin yi yoo ni lori awọn to n ṣe LGBTQ+
Botilẹ jẹ wi pe wọn ko faaye gba itọju iyipada ninu abadofin naa awọn ijiya tó lè to wa ninu rẹ tunmọ si pe ṣiṣe atilẹyin fun LGBTQ+ ti wa fi ọran bayii.
Bi eeyan ba tẹ ọrọ sita to jọ pe o ṣe atilẹyin LGBTQ+ gẹgẹ bi awọn ajafẹtọ-ọmọniyan ṣe sọ ijiya yoo tẹle.
Wọn ni ibẹru tun wa wi pe awọn to n ṣe Ibalopọ akọsiakọ yoo maa gbe igbe aye ifoya ni bayii.
Awọn akọroyin naa to ba jọ pe ọrọ wọn ṣe atilẹyin iwa Ibalopọ akọsiakọ yoo foju wina ofin tohun ti pe iwe ofin fun wọn lẹtọ lati gbe iroyin jade lalae si ifoya tabi ibẹru kankan.
Ki lo kan bayii?
Bayii ti abadofin naa ti gba itẹwọgba awọn aṣofin ohun to ku ni pe aarẹ yoo buwọlu lati fi sọ di ofin.
Aarẹ si le ma f'asẹ si to ba wo wi pe amulo ofin naa yoo mu inawo pupọ wa.














