Ní ìbálòpọ̀ akọ sí akọ tàbí abo sí abo kóo fi ẹ̀wọ̀n gbére jura – Ìjọba

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba Uganda ti fọwọ si abadofin kan, eyii to sọ ibalopọ akọ si akọ tabi abo si abo di eewọ lorilẹ-ede naa.
Ninu ofin tuntun naa, ẹwọn gbere ni ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o n ni ibalopọ akọ si akọ tabi abo si abo yoo fi jura.
Ajafẹtọ ọmọniyan kan nilẹ naa sọ funBBC pe ofin ọhun ti mu ki awọn eeyan maa ṣakọlu si awọn to n ni irufẹ ibalopọ bẹẹ.
O ni “Oniruru ibalorukọjẹ ati iṣẹrubani lo n waye.”
“Awọn eeyan ti bẹrẹ si n n gba ipe lori aago ti awọn kan si n sọ fun wọn pe ‘ti o ba kọ lati fun mi ni owo, mo maa lọ fi ẹjọ rẹ sun ijọba pe o n ni ibalopọ akọ si akọ.’”
Ofin tuntun yii jẹ ọkan lara awọn ofin to tako ibalopọ akọ si akọ, eyii to le ju nilẹ adulawọ.
Bo tilẹ jẹ pe o lodi si ofin lati ni ibalopọ akọ so akọ tabi abo si abo ni Uganda, ofin naa tun mu ijiya ara ọtọ wa.
Labẹ ofin ọhun, ẹnikẹni to ba fi ẹnu ara rẹ jẹwọ pe o oun n ni ibalopọ akọ si akọ tabi abo si abo yoo ṣẹwọn gbere.












