Mọ̀ nípa ìlànà èlé tuntun tóo bá fẹ́ ya owó bánkì, nǹkan míràn tí CBN kéde lẹ́ka ìṣúná ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, cbn
Ni ọjọ Iṣẹgun ni gomina Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele jade lati kede afẹnuko ipade igbimọ apapọ to ga julọ lori akoso awọn banki lorilẹede Naijiria.
Igbimọ yi lo n ṣe akoso bi nnkan ṣe n lọ si ati awọn igbesẹ ilana iṣuna ti banki apapọ n gbe.
Gomina banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele lo kede awọn afẹnuko naa ninu ipade to ba awọn akọroyin ṣe lọjọ Iṣẹgun.
Owo ele ori awọn owooya yoo lọ soke sii ni ileeṣẹ ifowopamọsi gbogbo
Ṣaaju asiko yii iye owo ele ori owooya ni naijiria duro si ida mẹtadinlogun o le diẹ ninu ọgọrun (17.5%/ pa)
O ni ida iye ele owo ti awọn araalu yoo maa san ti wọn ba ya owo ni banki bayii ti lọ soke si ida mejidinlogun ninu ọgọrun, (18%/ pa).
Gomina banki apapọ Naijiria naa ni igbesẹ yii waye lọna ati lee dena ọwọngogo atawọn wahala miran to n de ba eto ọrọ aje ni Naijiria.
Amọṣa awọn onimọ nipa eto iṣuna n ṣalaye pe afikun owo ele naa lee mu ki awọn nnkan o gbowo lori sii nitori awọn ileeṣẹ to ba gba awọn eyawo yii pẹlu alekun ele rẹ yoo gbe owo le ori ọja wọn lati lee san ele naa.
Ipenija wa fun eto paṣipaarọ ṣugbọn o mu adinku ba owo to n rare nigboro

Oríṣun àwòrán, cbn
Gomina Banki apapọ Naijiria ni lara awọn ohun ti igbimọ to ga julọ lori akoso banki lorilẹede naijiria tun gbe yẹwo ni ọrọ paṣipaarọ owo naira eyi to da ọpọ inira silẹ fun ara ilu.
O ni igbimọ naa woye pe igbesẹ naa ti mu adinku ba iye awọn owo to wa ni ikawọ awọn banki eyi to ni o n mu ireti wa pe itẹsiwaju tyoo wa lori awọn eto ati ilana to de owoona ni Naijiria.
“Awọn ọmọ igbimọ yii ko ṣai mọ awọn ipenija ati inira ti awọn eeyan koju lawọn ilana banki ori ayelujara nitori gbedeke ti wọn gbe le iye owo ti eeyan lee gba ni banki. Igbimọ naa wa ke sawọn banki, awọn ileeṣẹ isanwo ori ayelujara lati rii pe wọn wa nnkan ṣe si gulegule ijakulẹ ikanni ayelujara wọnyii.”
Diduro lori iye ti banki apapọ yoo ma ya awọn banki lowo
Gomina banki apapọ Naijiria, CBN Godwin Emefiele ṣalaye bakan naa pe Banki apapọ ko ni fi kun un tabi yọ kuro ni iye apapọ owo ti yoo ma ya awọn banki, eleyi ti wọn pe ni “asymmetric corridor at +100 and -500 basis points around the MPR.”
Iye owo ti o gbọdọ maa wa ninu aṣuwọn awọn banki (CRR)

Oríṣun àwòrán, bayo Ọmọboriowo
Bakan naa ni ipade igbimọ akoso to ga julọ ni banki lorilẹede Naijiria naa tun fẹnuko pe ayipada ko ni de ba iye owo to gbọdọ wa ninu aṣuwọn awọn banki kọọkan pẹlu rẹ eyi ti wọn pe ni CRR.
Lorilẹede Naijiria, iye ti owo yii jẹ wa ni ida mẹrindinlogun ninu ọgọrun o din diẹ laarin ọdun 2007 si ọdun 2023.
Ipa nla ni owo yii maa n ni lara iye owo ti awọn banki n ya araalu.
Bi wọn ba gbe owo yii soke, o fihan pe iye ipa ti awọn banki yoo ni lati ya ara ilu lowo yoo dinku.
Lọdun 2022 ni igbimọ yii kan naa gbe owo ti awọn banki gbọdọ ni ni aṣuwọn wọn pẹlu CBN soke lati ida mẹtadinlọgbọn abọ si mejilelọgbọn abọ lẹyin ti wọn fun wọn fun awọn banki ni gbedeke wakati mejidinlaadọta lati ṣe eyii nigba naa.












