Atiku wọ́ Tinubu lọ sí ilé ẹjọ́, Ó ní ìbò tó gbé e wọlé kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀

Bola Tinubu ati Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, bolatinubu/twitter

Oludije fun ipo aarẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ti gba ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye nipa esi idibo aarẹ lorilẹede Naijiria lọ lati tako esi ibo to gbe aarẹ tuntun ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan, Bọla Ahmed Tinubu.

Ọkan lara awọn agbẹjọro fun Atiku, Silas Joseph Onu fi idi eyi mulẹ laṣalẹ ọjọ Iṣẹgun.

Igbesẹ PDP lati wọ Tinubu lọ si ile ẹjọ n waye lẹyin wakati diẹ ti Peter Obi to jẹ oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party, LP pẹlu pe ẹjọ tirẹ ni ile ẹjọ naa nilu Abuja.

Atiku lo ṣe ipo keji ninu eto idibo yii pẹlu ibo miliọnu mẹfa ati ẹgbẹrun lọna ọrinlelẹẹdẹgbẹrun ati mẹrin o le okoolẹẹdẹgbẹta, (6,984,520) lati ko ida mọkandinlọgbọn ninu ọgọrun ibo naa.

Ki lawọn nnkan ti ipẹjọ Atiku n fẹ niwaju ile ẹjọ?

Ninu iwe ipẹjọ rẹ pẹlu nọmba idamọ CA/PEPC/05/2023, Atiku pe ajọ eleto idibo INEC, Tinubu, igbakeji rẹ, Sẹnetọ Kashim Shettima, ati APC lẹjọ.

Awọn olupẹjọ naa n rọ ile ẹjọ to n gbọa awuyewuye eto idibo aarẹ to waye lọjọ karundinlọgbọn oṣu keji ọdun 2023 pe ko kede pe Tinubu ko bori ninu idibo naa ati pe kii ṣe oun lo ko ibo to pọjulọ lasiko idibo naa.

Wọn ni awọn n fẹ aṣẹ ile ẹjọ naa fun INEC lati gba iwe ẹri olubori ibo ti wọn fun Tinubu pada fun awọn.