Olórí ẹgbẹ́ alátakò Chad Yaya Dillo pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ikọlù pẹlú àwọn ọmọ ogun

Oríṣun àwòrán, ISSOUF SANOGO
Awọn alaṣẹ ti fìdí ọrọ mulẹ pe olori ẹgbẹ alatako kan nilẹ naa ti padanu ẹmi rẹ nigba to koju awọn ọmọ ogun ilẹ naa pẹlu ibọn.
Iku Yaya Dillo n waye lẹyin ti ijọba da l'ẹbi ikọlu kan si ẹka alaabo ilẹ naa.
O sọ pe oun ko lọwọ ninu ikọlu ọhun.
Lọjoru l'awọn eeyan sadede bẹrẹ sí ní gbọ iro ibọn lẹgbẹ olu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu rẹ to wa ni olu ilu ilẹ naa,N'Djamena.
Dillo ki f'ọrọ pamọ sọ pẹlu atako aarẹ ilẹ naa to jẹ Ibatan rẹ Aarẹ Mahamet Déby to ti wa lori aleefa lati ọdun 2021.
Ọwọ baba rẹ ni Déby ti gba ijọba lẹyìn t'awọn ọmọ ogun ọlọtẹ sẹku pa.
Ọdun mẹtalelọgbọn lo fi wa lori ipo.
Wahala bẹ silẹ ni orileede naa lẹyìn igba ti wọn kede pe idibo aarẹ yoo waye lọjọ Kẹfa oṣu Kaarun
Idibo yi ni wọn yoo fi da ijọba pada fun alagbada.

Oríṣun àwòrán, ISSOUF SANOGO
Minisita f'ọrọ iroyin ni Chad ti sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe Dillo ki lỌjọru " nibi to sa pamọ si ninu olu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu rẹ to si kọ lati jade jọwọ ara rẹ fawọn agbofinro to si tun yìnbọn lu wọn"
LỌjọru yi naa ni Dillo sọ wi pe idi tí wọn fí fẹsun kan oun pe oun ṣe ikọlu si ileeṣẹ ologun ni pe" wọn fẹ dẹru ba mi ki n ma baa fi kopa ninu idibo"
Ọkan lara awọn akẹgbẹ Dillo to jẹ akọwe agba ẹgbẹ oṣelu Socialist Party Without Borders (PSF), so fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe nise ni awọn ologun ṣe ikọlu s'awọn nigba tàwọn fẹ gbe oku akẹgbẹ wọn nileeṣẹ ologun,Ahmed Torabi.
Agbẹnusọ PSF sọ pe wọn mu Torabi lọjọ Iṣẹgun ti wọn si pa ki wọn to ju oku rẹ siwaju ileeṣẹ ANSE.
Gẹgẹ bi ijọba ṣe wi, Torabi n gbiyanju lati sẹkupa aarẹ ile ẹjọ to gaju lọ ni lasiko ti wọn fi pa.
Wọn yinbọn Lu awọn mọlẹbi ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu to gbiyanju lati gbe oku rẹ lỌjọru.
Ìṣẹlẹ yí si mu ki ọpọ ẹmi ṣofo gẹgẹ bi akọwe agba ẹgbẹ naa ṣe sọ.















