Àwọn agbébọn kọlu ọọ́físì iléeṣẹ́ ètò àbò Chad, ọ̀pọ̀ òkú sùn

Aworan afihan awọn agbebọn Chad

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba orilẹ-ede Chad ti sọ pe ọpọ oku lo sun lasiko ti awọn eeyan kan dede ṣina ibo bolẹ niwaju ileeṣẹ to n ri si eto abo, National Security Agency.

Wọn ni awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ni awọn funra si pe o ṣe akọlu naa lọna ati gbẹmi adajọ agba orilẹ-ede ọhun.

Minisita eto iroyin, Abderaman Koulamallah ti fẹsun iṣẹlẹ naa kan ọkan lara awọn akọwe ẹgbẹ alatako, Socialist Party without Borders, pe oun lo pinlẹ ikọlu ọhun.

Abderaman Koulamallah sọ pe Yaya Dillo, to jẹ olori ẹgbẹ naa lo ko awọn eeyan sọdi lati gbẹmi adajọ agba ni ọọfisi ileeṣẹ eto abo.

Wayi o, wọn ti fi ṣikun ofin mu awọn afurasi kan, wọn si ti wa ni ahamọ.

Ijọba ni ọwọ ti tẹ pupọ ninu awọn to lọwọ ninu ikọlu ọhun, awọn si ti n wa awọn afurasi to ku ti wọn ti a papa bora.

A ko tii le sọ boya olori ẹgbẹ Socialist Party without Borders, Yaya Dillo, wa lara awọn ti wọn mu ṣugbọn o sọ loju opo Facebook rẹ pe awọn ologun ti yi ile oun ka.

Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin nnkan bii ọsẹ kan ti olori ile ẹjọ to ga julọ nilẹ naa ni awọn eeyan kan kọlu ọọfisi oun.

Wayi o, awọn ologuu ti duro wamuwamu laarin igboro N’Djamena bayii lati pese eto abo to peye fun awọn araalu lẹyin iṣẹlẹ ọhun.