Ìdí tí àwọn bàbáńlá wa fi ń jẹ ẹran èèyan àti ohun tó fi òpin sí àṣà nàá

Oríṣun àwòrán, getty
- Author, José Luis Guil Guerrero
- Role, BBC
- Reporting from, Reporting from The Conversation
Ẹja lẹja n jẹ sanra ni owe Yoruba kan wi.
Igba kan ti wa ri to jẹ pe eeyan ẹlẹran ara bii tiwa bayii ni awọn babanla wa ma n jẹ.
Eyi ko deede ri bẹẹ, bẹẹ ni ki i ṣe nitori ati fi ajulọ han ara wọn bii ti ẹja to n jẹ ara wọn sanra.
Iṣẹlẹ kan lo ṣẹlẹ to kọkọ mu itan yii waye, eyi ti wọn fi ṣe fiimu laipẹ yii.
Awọn ọmọ orilẹ-ede Uruguay kan ni ọkọ baaluu wọn jabọ loju ofurufu ni agbegbe Andes.
Oku awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ wa nilẹ, awọn ti ori ko yọ ninu wọn naa wa nikalẹ, wọn n wo oku awọn to ku.
Ebi lo mu wọn bẹrẹ si i jẹ oku awọn eeyan wọn naa, nigba ti ko sohun miran ti wọn le jẹ.

Oríṣun àwòrán, NETFLIX
B’áyé ṣe ń yí ni àṣà jíjẹ èèyàn ń bá a yí nígbà kan
Ni nnkan bii miliọnu kan ọdun o le sẹyin (1.45 million years ago) itan sọ fun wa pe awọn eeyan lorilẹ-ede Kenya naa maa n jẹ ara wọn.
Itan sọ pe wọn maa n pa ara wọn, wọn yoo si jẹ ẹran ẹni ti wọn pa bii ẹran.
Àpá kan to ma n wa ni ara awọn eeyan tibia, ni ami to ti i pẹ julọ to fihan pe awọn babanla wa ma n pa ara wọn fun jijẹ.
Bakan naa nitan sọ pe o ṣe e ṣe ko jẹ pe lasiko tawọn ẹni iṣaaju lorilẹ-ede South Africa (Plio-Pleistocene period) wa laye ni aṣa yii waye - àpá kan to wa ni apa ọtun agbọn wọn, eyi to jẹ lati ara okuta.
Iyẹn ni nnkan bii miliọnu meji aabọ ọdun sẹyin.
Lasiko naa, o fẹrẹ jẹ pe ẹya inaki ti wọn da bii eeyan (hominids) lo n jẹ ẹran eeyan ju - Awọn bii Homo antecessor.
Ṣugbọn lawọn asiko ti jijẹ ẹran ara eniyan n waye yii, aṣa naa ko deede waye, ohun ti wọn ri ni wọn n jẹ.

Oríṣun àwòrán, GETTY
Bí ẹran èèyàn jíjẹ ṣe wá sópin

Oríṣun àwòrán, GETTY
Jijẹ ẹran eeyan ko pari si awọn orilẹ-ede ta a darukọ yii , o kari aye lawọn asiko naa ni.
Fun apẹẹrẹ, ẹri wa pe awọn eeyan to kọkọ wa ni Colombus nilẹ America, jẹ awọn to n jẹ ẹran ara eniyan. Awọn kan ni agbegbe Pacific tiẹ ṣi ni aṣa yii titi di awọn ọdun diẹ sẹyin.
Gbogbo awọn eroja aṣaraloore ti ara eeyan nilo bii Omega-3, awọn ounjẹ to pe, to si kun fun eroja aṣaraloore pada foju han bi aye ṣe n yi.
Awọn ẹya ara yii, paapaa ọra, jẹ ko ṣe e ma ni ninu ara. O si jẹ pataki awọn ẹya ti wọn ma n yọ lati ara awọn ti wọn ba jẹ.
Idi ni pe ko fi bẹẹ wọpọ lara awọn ẹranko ti awọn ọdẹ n pa, to ni gbogbo awọn eroja naa ninu.
Ṣugbọn bi imọ ijinlẹ ṣe n tẹsiwaju, bẹẹ lo di pe ohun ti kaluku n jẹ n yatọ, ti oye si wa pe awọn irugbin wa to le fun eeyan ni awọn eroja aṣaralore.
Ohun ti ayọka yii n kọ wa ni pe, iṣẹda eniyan ki i ṣe ti jagidijagan - ipo tabi aaye ti kaluku ba ba ara rẹ ni yoo sọ iru iwa ti yoo hu.
Nitori naa, ti ẹ ba n ra ohun tẹ ẹ fẹ lasiko yii nile itaja igbalode tabi lọja yoowu, ẹ maa ranti awọn iṣẹda akọkọ ti wọn ko lanfaani iru rẹ, to jẹ ohun ti wọn ri, ni wọn jẹ.
Ọjọgbọn José Luis Guil Guerrero lẹni to kọ ayọka yii lede rẹ. Ọjọgbọn nipa ounjẹ ni, ni Yunifasiti Almeria.














