Wo ohun tí àwọn àgbàgbà òṣèré ń sọ nípa Sisi Quadri tó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Sisi Quadir
Lati ọjọ Ẹti ti iroyin iku ojiji to pa gbajmọ onitiata ni, Tọlani Quadri Oyebamiji, ti gbode kan lawọn eeyan ti n ṣedaro adẹrin-in-poṣonu yii.
Yatọ sawọn ololufẹ rẹ ti wọn n gbadun bo ṣe maa n bu awọn eeyan bii ẹni layin ninu fiimu, awọn agbaagba lagbo tiata Yoruba naa sọrọ nipa Sisi Quadri loju opo ayelujara Instagram wọn.
Lara awọn gbajumọ oṣere to ṣedaro iku Sisi Quadri ni Biola Bayo, Ibrahim Yẹkini, Odunlade Adakola, Mr Latin, Ibrahim Chatta, Regina Chukwu, ati bẹe bẹẹ lọ.
Biọla Adebayọ ni a maa ṣaaro rẹ pupọ, Sisi Quadri. K’Oluwa tẹ ọ s’afẹfẹ rere.

Oríṣun àwòrán, Biola Bayo
Ibrahim Yẹkini sọ pe "Ile aye ile asan."
Ni ti Bọlaji Amusan, Mr Latin o ni ki Oluwa fun un nisinmi ayeraye.
Regina Chukwu ni "Ko buru o. Bẹẹ mo ṣi n ṣorọ nipa rẹ lọjọ meloo kan sẹyin o, lai mọ pe o n gbiyanju lati ṣegun iku lọwọ."
"Ọpọlọpọ eeyan o mọ pe mo kọṣẹ lọdọ rẹ gẹgẹ bii aṣojuloge fun ọpọlọpọ ọdun. Bẹẹ ni, iṣẹ aṣojuloge ni mo n ṣe fawọn onitiata tẹlẹ. O daarọ o, Ọga."
Fẹmi Adebayọ Salami, ni ọjọ buruku ni ọjọ iku oloogbe naa jẹ, o si gbadura ki Ọlọrun tu idile rẹ ninu.

Oríṣun àwòrán, Femi Adebayo
Ọdunlade Adekọla ni "Eyi ba ni ninu jẹ pupọ. Ọrun ire, Sisi Quadri."
Ibrahim Chatta, Saidi Balogun, Laide Bakare, atawọn gbajumọ oṣere tiatat mii tun banujẹ lori iku Sisi Quadri.
Àlàyé rèé lórí ìròyìn tó tẹwa lọ́wọ́ nípa ohun tó ṣòkùnfà ikú Sisi Quadri

Oríṣun àwòrán, iamsisiquadir
Iku oṣere tiata Yoruba nii,Tolani Quadri Oyebamiji, Sisi Quadri ṣi n ṣe ọpọ ololufẹ rẹ bi iranran.
Kaakiri oju opo ayelujara lawọn eeyan ti n beere pe ki lo ṣokunfa iku rẹ ati pe ipo wo ni o wa ti ọlọjọ fi de baa.
BBC Yoruba kan si ọkan lara awọn to kọkọ kede iku rẹ loju opo ayelujara Otunba Adekunle Abolade ti gbogbo aye mọ si Dodo Ede.
Lojuopo rẹ to ti kede iku Sisi Quadri, o sọ pe oun ṣẹ́ṣẹ wo fiimu ti Sisi Quadri ti kopa ninu rẹ Anikulapo tan ni lowurọ oni.
O ni Sisi Quadri ku ninu fiimu naa to siti wa pada jade laye loju aye gangan.
Ninu alaye rẹ to ṣe Dodo Ede ni ilu Ogbomosho ni Sisi Quadri dakẹ si ati pe ni ile iwosan fasiti Ladoke Akintola lo ti n gba itọju lori ailera to n koju lẹnu lọọlọ yi.
Alaga nigba kan ri fun ẹgbẹ sọrọ sọrọ ni ipinlẹ Osun yi sọ pe lọwọlọwọ bayiioun wa loju ọna Iwo si Ogbomosho lati lọ wo iru etoto yẹ ni ṣiṣe fun ẹyẹ ikẹhin oloogbe
Ikú Sisi Quadri dùn mí nítorí mó sẹsẹ wò fíìmù Anikulapo tàn níbi tó tí ku nínú rẹ̀ ní

Oríṣun àwòrán, Dodo Ede
Lara ibeere ti awọn eeyan n beere nipa iku Sisi quadri ni pe wọn fẹ mọ iru iku to mu ẹmi rẹ lọ.
Bawọn kan ṣe n sọ pe aisan kidinri ni awọn mii n sọ pe aisan ranpẹ lo sokunfa idagbere rẹ faye.
Dodo Ede sọ fun BBC pe oun ko le sọ pato ohun to ṣokunfa iku rẹ amọ o ti to ọjọ meloo kan to wa ni ile iwosan to ti n gba itọju ni Ogbomoso.
''Ogbomoso lo dakẹ si. Ibẹ ni wọn si ti pe mi lati sọ fun. Lọwọ bayii oku rẹ wa ni aye igbokupamọsi taa mọ si mọṣuari.Ki Olorun tẹ si afẹfẹ rere''
O fikun pe awọn mọlẹbi ni wọn wa nipo lati sọ ohun to pa Sisi Quadri.
O ni iku rẹ jẹ ibanujẹ nla fun awọn eeyan ilu Iwo to jẹ ibi ti wọn ti bi Sisi Quadri.
O jẹ ka mọ wi pe Sisi Quadri fi baba silẹ, iyawo ati ọmọ.

Oríṣun àwòrán, iamsisiquadir
Gbajugbaja oṣere tiata ati adẹrinposonu nii Tolani Quadri Oyebamiji ti ọpọ mọ si Sisi Quadri ti dagbere faye.
Lọjọ Ẹti ni iroyin bẹrẹ si tan kaakiri oju opo ayelujara nipa iku rẹ.
Ko pẹ si igba naa ti aarẹ ẹgbẹ oṣere TAMPAN, Bolaji Amusan ti ọpọ mọ si Mr Latin fi ọrọ nipa iku rẹ soju opo Instagram rẹ to si ni ''Hmmm... ki Eledua tẹ si afẹfẹ rere''
Bakan naa ni agba oṣere nii Saidi Balogun naa fi soju opo rẹ pe awọn ti padanu Sisi Quadri.
Titi di akoko igba taa n ṣe akojọpọ iroyin yi, a ko le sọ pato ohun to ṣokunfa iku rẹ.
Ilumọọka apanilẹrin yi jẹ eeyan kan tawọn ololufẹ ere tiata Yoruba nifẹ si tori bi o ṣe maa n ṣe ẹkẹ eebu ninu sinima.
Omọ ilu Iwo Olodo Ọba nipinlẹ Ọṣun yii ninu ifọrọwero pẹlu BBC sọrọ nipa didagba rẹ ati ipa ti awọn obi rẹ ni lori iṣẹ rẹ.
O ni ile loun ba ọrọ sisọ ati pe ko si ẹni ti awọn obi to bi oun ko le sọrọ si.
Ọpọlọpọ ololufẹ rẹ lo maa n ṣe eemọ bo ṣe rọrun fun lati maa ṣe bi obinrin ninu ere sinima.
Ninu idahun si ibeere yi nigba ti BBC beere lọwọ rẹ , o ni irọrun lo ba de fun oun.
Ọdun 1979 ni a bi ẹlẹekẹ eebu alawada yii to jẹ atọkun eto to tun n ṣiṣẹ alaga iduro nibi idana igbeyawo yatọ si iṣẹ ere ṣiṣe to sọ di ilumọọka.
Laipẹ yi lo ba wọn kopa ninu ere sinima agbelewo nii Anikulapo to ṣẹṣẹ jade sita.













