Ìjọba Nàìjíríà béèrè bílíọ́nù mẹ́wàá dọ́là gẹ́gẹ́ bí owó gbà máa bínú lọ́wọ́ Binance

Afihan ami idanimọ Binancce ati aworan aarẹ Naijiria Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Presidency

Awọn alaṣẹ lorileede Naijiria ti beere biliọnu mẹwaa dọla lọwọ ileeṣẹ idokowo crypto nii Binance gẹgẹ bi owo ijiya.

Eyi ko ṣẹ lẹyin ẹsun ti wọn fi kan ileeṣẹ naa pe o ṣokunfa bi Naijiria ṣe padanu owo nitori magomago ti wọn ṣe nidi paṣiparọ dọla si Naira.

Ijọba sọ pe ileeṣẹ Binance kopa lati ri pe alekun ba iye paṣiparọ Naira si dọla to si mu i iye owo dọla dẹnukọlẹ niwọn ida to sunmọ aadọrin ninu ida ọgọrun laipẹ yii.

Bayo Onanuga to jẹ ọkan ninu awọn agbẹnusọ aarẹ Tinubu sọ pe ijọba ri ọwọ Binance lara bi idẹnukọlẹ ti ṣe ba Naira.

''Oju opo yi a maa fa gbendeke kalẹ lori iye owo paṣiparọ Naira si dọla ti eleyi si tako ofin.CBN nikan lo lẹtọ lati fi gege si iye owo paṣiparọ owo ni Naijiria''

O fikun pe ''oju opo Binance n gbabọde fawọn to n gbe iye owo paṣiparọ kalẹ ti eleyi si n ṣakoba fun ọrọ aje Naijiria lasiko ti ijọba n gbiyanju lati da pada sipo.''

LỌjọbọ awọn alaṣẹ Naijiria fidi rẹ mulẹ pe lootọ lawọn mu awọn alaṣẹ Binance meji ti awọn agbofinro si n fọrọ wa wọn lẹnu wolori ẹsun pe oju opo yi n gbabọde fawọn to n ko owo pamọ lọna aitọ ati awọn to n fi owo naa ṣagbatẹru fawọn agbesunmọmi to fi mọ awọn ẹsun miran.''

Binance

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gomina Banki apapọ CBN Olayemi Cardoso sọ lọjọ Iṣẹgun pe nkan bi biliọnu mẹrindinlọgbọn lo gba ọwọ Binance jade sita latara idokowo crypto.

O tẹsiwaju pe ọpọ awọn idunadura to waye loju opo naa ko gba oju ọna to tọ to si jẹ pe awọn ko ribi da awọn ẹni wọnyii mọ.

Onanuga ni tiẹ sọ pe Binance n fa rukerudo ninu ẹka ọrọ aje Naijiria ati pe ijọba ko ni kawọ gbera ki iru ẹ tẹsiwaju amọ ṣa awọn alaṣẹ Binance ti n fọwọ so wọpọ pẹlu awọn alaṣẹ.

''Awọn oṣiṣẹ Binance ti n ba ijọba ṣiṣẹ pọ nipa ipese iroyin ''Bẹẹ ni o ṣalaye lori eto ileeṣẹ BBC kan Newsday to waye lọjọ Ẹti.

‘Binance, ati awọn mii ko ni oripa lorileede Naijiria’

Onanuga sọ pe Binance ati awọn oju opo Crypto mii ko forukọsilẹ ni ibamu pẹlu ofin orileede Naijiria.

Gomina Banki apapọ tẹlẹ Godwin Emefiele sọ pe awọn ko ni faaye gba crypto kankan titi di ọdun 2023 ti ijọba wa pada gbẹsẹ kuro lori aṣẹ yii.

Agbẹnusọ aarẹ sọ pe Binance ti yọ idunadura pẹlu Naira kuro lojyu opo wọn ti wọn si n fọwọ so wọ lati pese iroyin fawọn alaṣẹ..

Onanuga sọ pe awọn n beere owo shikini lọwọ ileeṣẹ naa eyi to sunmọ biliọnu dọla mẹwaa ni owo gba ma binu tori bi wọn ṣe fẹ da ori ọrọ aje Naijiria kodo laarin igba perese.

Ijọba Naijiria sọ pe CBN nikan lo laṣẹ lati fi gbendeke si iye paṣiparọ owo Nairia si owo ilẹ okere.

“A gbe oṣuwọn ẹgbẹrin lọna ọgọrun Naira si dọla kan kalẹ ninu iṣuna ọdun yi amọ iye owo paṣiparọ to wa nilẹ yi ti kọja rẹ.Awọn to n ṣowo paṣiparọ owo sọ pe bi a ko ba wa wọrọkọ fi ṣada lori Binance Naira wa yi dẹnukọlẹ ju bayii lọ''

Igba wo ni iwadii yi yoo pari?

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC Zakari Mijinyawa to jẹ ọga ẹka ibanisọrọ ni ọfisi olugbaninimọran si aarẹ lori ọrọ aabo sọ pe awọn n ṣe iwadii awọn adari ileeṣẹ Binance.

''A ti n fọrọ wa awọn oṣiṣẹ wọn lẹnu wo lori ọrọ to niṣe pẹlu ilana paṣiparọ owo ni Naijiria''

Mijinyawa sọ fun BBC pe ''idunadura ati ifọrọwerọ n tẹsiwaju pẹlu awọn alaṣẹ Binance ti wọn si n ba wa fọwọ so wọ pọ''

Amọ ko s pato igba ti iwadii yi yoo pari .

Bẹẹ ni ko srọ nipa adehun to wa laarin ijọba ati Binance ti wọn jijọ n fọrọwer lori.