Ẹ̀yin nìkan kọ́ ni agbẹnusọ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà - Tinubu sọ òkò ọ̀rọ̀ sí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government
Aarẹ Bola Tinubu ti sọko ọrọ si awọn olori ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria, to si n rọ wọn lati jẹ ki alaafia jọba.
Aarẹ sọrọ eyi lasiko to n ṣe ifilọlẹ oju ọna reluwe Red Line nipinlẹ Eko.
Bẹẹ ba gbagbe, ẹgbẹ osisẹ Labour gunle ifẹhonuhan ati ìwọde ọlọjọ meji lori ọwọngogo ounjẹ to gbode lorilẹede Naijiria.
Nigba to n sọrọ, Aarẹ tọrọ aye lati fọrọ ransẹ si ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria NLC ati TUC.
"Ẹgbẹ osisẹ ni lati mọ pe sise ìwọde laarin oṣu mẹsan tí ìjọba wa de ko jẹ itẹwọgba.
"Ti ẹ ba fẹ gbe apoti ibo, ẹ duro de ọdun 2027. Ẹ jẹ ki alaafia jọba. Ẹyin nìkan kọ ní agbẹnusọ fun awọn ọmọ Naijiria."
Bakan naa ni Aarẹ orilẹede Naijiria tun gbe oṣuba kare fun bi ìjọba ìpinlẹ Eko lori ifilọlẹ naa.
"Inu mi dun lati sọ erongba wa fun ọpọlọpọ ọdun ti wa si imusẹ.
"Ki i ṣe lati ni erongba nla, a kan ni lati gbajumọ nnkan ti a fẹ."
Nnkan yoo rọrun laipẹ - Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Lagos State Government
Aarẹ Tinubu tun fi asiko naa pẹtu sọkan awọn ọmọ orilẹede Naijiria, to si fi dawọn loju pe nnkan to lasiko yii yoo rọrun laipẹ
O ni, " Mo n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lati lori pẹpẹ yii pe ayipada yoo wa. Ilọsiwaju wa ti jẹ dandan, ajọsepọ wa ni."
Aarẹ ni bi alekun ṣe n gun iye eeyan to wa lorilẹede Naijiria tumọ si pe orilẹede Naijiria gbọdọ bẹrẹ si ni ṣeto fun ọjọ ọla.
"A gbọdọ gbajumọ nnkan to da. Eto aje wa yoo gboro si, a o bọra wa kuro ninu ipo ti a wa yii, inu wa yoo si dun pe a gbe igbesẹ yii."
Aarẹ wa jẹ ko di mimọ pe isejọba toun ko ni fi aye silẹ fun iwa ibajẹ.
"Ìwa ibajẹ yoo di ohun igbagbe, a o tọju owo lati pese eto fun awọn ọmọ wa, lati pese eto ìlera, lati pese irinna fun awọn araalu."















