Ẹ yé pe èdè Yorùbá ní 'vernacular,' èdè àwọn ará oko ló ń jẹ́ 'vernacular' - Ọjọ̀gbọ́n Ogunsina

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá kìí ṣe 'Vernacular,' èdè àwọn ará oko ló ń jk Vernacular
Ẹ yé pe èdè Yorùbá ní 'vernacular,' èdè àwọn ará oko ló ń jẹ́ 'vernacular' - Ọjọ̀gbọ́n Ogunsina
Aworan Ọjọgbọn James Adebidi Ogunsina

Ọjọgbọn ninu ede Yoruba kan, James Adebisi Ogunsina ti bu ẹnu ẹtẹ lu awọn to n pe ede Yoruba ni ''vernacular.''

Ọjọgbọn Ogunsina sọ pe ''ede awọn ara oko ni wọn n pe ni ‘’Vernacular, ọpọ ni ko mọ itumọ ede naa.

Ede Yoruba kii ṣe Vernacular, ki ṣe ede ara oko.

Ede awọn Ọjọgbọn...awọn Yoruba gbọn lọpọlọpọ, ẹni ti o ba mọ nipa ede Yoruba, a ri pe o kun fun ọpọlọpọ imọ ijinlẹ, o kun fun ọpọlọpọ ọgbọn.

Awọn owe wa, awọn oriki wa, ọfọ wa gbogbo rẹ lo tayọ.''

Ọjọgbọn Ogunsina ni nnkan ko ri bi ti tẹlẹ mọ nipa eto ẹkọ.

''Laye igba yẹn, awọn to kẹkọọ gboye ni ile ẹkọ fasiti ni wọn maa n ṣe ọga agba ilẹ ẹkọ girama.

Bi wọn ti n de bayii ni wọn yoo gbe ọkọ ayọkẹlẹ fun wọn.

Iwe pe nigba naa, iwe a wu eeyan ka ti ẹ ba wa ni fasiti nigba naa.

Awọn olukọ ki da iṣẹ silẹ nigba naa, ko dẹ si pe eeyan maa wa iṣẹ kiri nigba naa.

Ko ṣoro lati lọ si ilu oyinbo nigba yẹn, ẹni ti yoo ṣiṣẹ ijọba, ko ṣoro fun un.

-Nitori naa, eeyan mọ idi ti o fi n kawe, ti ẹ ba ti kẹkọọ gboye nigba naa, ibalẹ ọkan ti de.

Ṣugbọn nisin yii, nnkan ti bajẹ, wọn o jẹ ki iwe wu awọn ọmọ wa ka mọ.

Ọpọ awọn olukọ ni ko da ṣamu ṣamu ninu ẹkọ ti wọn ka,'' Ọjọgbọn Ogunsina lo sọ bẹẹ.