Ojú òpó 'mychat' ní mó tí ń mú àwọn obìnrin tá fí n ṣe oògùn owó-afurasí sàlàyé fún ọlọ́pàá

Aworan afihan amí idanimọ ọlọpaa ati afurasi

Oríṣun àwòrán, BBC

Afurasi afiniṣẹṣo kan Adebayo Olamide ti salaye fun awọn ọlọpaa ona to gba lati fi tan awọn obinrin to pada lo lati fi sẹṣo owo.

Gẹgẹ bo ṣe wí, oju opo idọrẹ "mychat" lọ ni oun ti pade wọn toun sí gba ibẹ tan wọn lọ sibi iku.

Lasiko ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun n safihan rẹ lọ tu kẹkẹ ọrọ silẹ.

Azeez ẹni ọdun mejilelọgbọn sọ pe oun jẹ ọkan ninu awọn ikọ afiniṣẹṣo to ṣe pe pipa obinrin ati tita ẹya ara wọn l'awọn yan gẹgẹ bi iṣẹ. Ṣaaju asiko yi ni ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣafihan awọn ọmọ ìkọ alaburu yi ti orúkọ wọn n jẹ : Moses Abidemi Awuraji, Oluwo Samuel Monday, Peter Oluwalolese, Jamiu Yusuf, Akinwunmi Ifatosin, Sherifff Agbai ati Osojieahen Alioneitouria.

Gbogbo wọn l'awọn agbofinro mu lori ẹsun pe wọn sẹku pa arabinrin ẹni ọdun marundinlogoji kan Sulaimon Adijat, ti wọn fi ṣe ogun owo.

Azeez na papa bora ṣugbọn ọwọ pada tẹ ti sí jẹwọ pe oṣu Kẹsan ọdun to koja loun darapọ mọ ìkọ naa ati pe oun ti bawọn pa obinrin meje lẹnu igba toun bẹrẹ.

Kọmisana ọlọpaa to ṣafihan awọn afurasi yi sọ pe wọn jijọ n ṣiṣẹ pẹlu babalawo kan Moses Abidemi Awuraji lati fi awọn eeyan ṣe etutu ọla.

O ni " Nise l'awọn afurasi yi n yin awọn ẹni ti wọn ba mu lọrun pa ti wọn si n ge ẹya ara wọn ta fun Oluwo Monday Samuel ati Alfa Ariwo to ti na papa bora "

O fikun pe awọn afurasi yi jẹwọ pe awọn pa obinrin mẹwa ọtọọtọ ni ile Moses Abidemi to wa ni Igbo Olomi.

Oju opo mychat ni mo ti n tan awọn obinrin naa lọ si ẹnu iku

Ninu alaye bo ṣe n tan awọn obinrin naa Azeez sọ pe " oju opo hook up my chat ni mo ti n ri awọn obinrin yii.Igba kigba ti Moses Abidemi Awuraji ba ti nilo ẹyà ara wọn maa kan sọ fun wọn pe mo fẹ ṣe hook up pẹlu wọn ni"

O ni oun kii mọ awọn obinrin naa saaju igba naa." Oju opo ayelujara nikan naa láti maa n pade.Mo maa beere pe ṣe wọn raye, a o dunadura iye ti wọn fẹ gba,maa si juwe adirẹsi mii ni Atan Ota fun wọn"

"Mo maa pe Moses Abidemi ti wọn ba ti de maa sí gbe wọn lọ sí ile rẹ ni Igbo Olomi Atan Ota.Ninu iyara rẹ la ti maa n pa wọn"

O tẹsiwaju pe "Iyawo Abidemi yoo di ẹsẹ wọn mu ti maa si yin wọn lọrun pa."