"Mo rí fìrífìrí lẹ́yìn sinimá mi, ‘Òṣòròǹgà’ torí mo tọpinpin ìṣẹ̀mbáyé Yorùbá"

Àkọlé fídíò,
"Mo rí fìrífìrí lẹ́yìn sinimá mi, ‘Òṣòròǹgà’ torí mo tọpinpin ìṣẹ̀mbáyé Yorùbá"

Ewi ni ilẹ Yoruba jẹ ohun pataki pupọ, to si tun jẹ ohun iwuri nla fun ọpọ ọmọ kaarọ ojiire lati ri pe ọlaju ko ti gba aṣa ati ise lọwọ iran Yoruba.

Aremo Yusuf Alabi Balogun ti ọpọ mọ si Aremo Gemini jẹ ọdọ kan to yan ewi kika layo, to si nifẹ si gbigbe aṣa Yoruba larugẹ.

Bakan naa lo jẹ Onpitan to n kọ nipa itan ilẹ Yoruba.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, Gemini salaye pe imisi lo sokunfa ọpọlọpọ itan ti to n kọ sita ati pe ede Yoruba jẹ ede kan to nifẹ si pupọ.

"Niwọn igba ti a ba n ṣe ijuba fawọn agba, ko ni si laburu"

Aremo Gemini wa salaye pe lẹyin ti oun gbe sinima oun, Osoronga jade, oun ri firifiri kan tabi meji.

O ni eyi waye nitori pe oun n toju bọ awọn ohun isẹnbaye to jẹ ti ilẹ Yoruba.

"Sugbọn a ko le fẹ iru eyi ku, tori ẹni ti yoo ba jẹun gbọ́in-gbọin, yoo ti ilẹkun gbọingbọin.

Amọ niwọn igba ti a ba n se ijuba fun awọn agba, ko ni si laburu fun wa."

Aworan Aremo Yusuf Balogun

"Awọn sinima agbelewo Ajileye, Ogunde ni mo wo dagba, ni ede Yoruba fi da lẹnu mi"

"Ti a ba ni ki a gbe yẹwo, itan ti mo n kọ yii ati ewi ti mo n ka wa ninu oun gbogbo,

"Ti ẹ ba wo orilẹede ti a wa, ọpọlọpọ nnkan lo n ṣẹlẹ ti awọn eeyan n gbe si ori ayelujara lojojumọ.

"Iyẹn gan to ni itan lati kọ sita."

O salaye pe bi Yoruba ṣe dun lẹnu rẹ ko sẹyin pe ede Yoruba ni wọn fi kọ lati kekere.

"Bi wọn ba ni pe Yoruba dun lẹnu mi, maa wulẹ ni o ni ṣe pẹlu ọna ti mo gba dagba nitori pe yatọ si awọn to ni maa ni 'Vernacular ni ede Yoruba, awa n sọ ede Yoruba laarọ, lọsan, lalẹ ni ilẹ wa.

"Awọn sinima agbelewo Ajileye, Ogunde nkankan ni mo dẹ tun wo dagba, iyẹn naa ni ṣe pẹlu imọ ẹkọ ede Yoruba."

Bakan naa lo rọ awọn ọdọ lati ma ṣe fi tẹbẹnu ede Yoruba ati pe ki wọn nifẹ si ede nitori ti a ba padanu ede, a padanu aṣa ati orisun ilẹ Yoruba

Ọrọ pọ lẹnu Aremo Gemini lori bi o ṣe n lo ede Yoruba ni ọna to rẹwa, ẹ wo fọnran ti a gbe soke.