Ǹ kò kábàámọ̀ pé mo polongo ìbò fún Tinubu, ìdí tí mo fi bẹ̀bẹ̀ rèé - Olaiya Igwe

Aworan Ebun Oloyede

Oríṣun àwòrán, Instagram/olaiyaigwefilms

Gbajugbaja oṣere tiata, Ebun Oloyede ti ọpọ tun mọ si Olaiya Igwe ti ni oun ko kabamọ pe oun ṣe atilẹyin fun Aarẹ Bola Tinubu lẹyin ọsẹ kan to tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ Naijiria lori pe o ṣe ipolongo fun Tinubu.

Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu Oloye Kola Olootu lori redio kan nilu Ibadan, Olaiya ni titọrọ aforijin ti oun ṣe, ko tumọ si pe oun kabamọ pe oun ṣe atilẹyin fun Tinubu.

O ni ti oun ba tun ni anfani lati ṣe atilẹyin fun Aarẹ Tinubu lati ṣe aṣeyọri, oun ko ni ro ni ẹẹmeji rara.

“Se ẹ ri ohun ti mo ṣe fun Tinubu yii ni mo le ṣe fun gbogbo oju to n wo mi.

“Ti eeyan ba ṣe oore ẹgbẹrun kan fun mi, maa dupẹ ẹgbẹrun mẹwaa fun un, bi a ṣe da mi ni, iya mi ni mo fi jọ."

"Oore kekere kọ ni Tinubu ṣe fun mi, oore iṣẹ́ abẹ Kindinrin, ẹya ara to buru julọ ni"

Olaiya Igwe tẹsiwaju pe, “Ki wa ṣe oore kekere ni Tinubu ṣe fun, oore kindirin ni a pe, ọba ninu ẹya ara to buru ju.

“Iyẹn lo jẹ ki ṣe nnkan ti mo ṣe sugbọn gbogbo awọn ololufẹ mi to ba binu ni mo tọrọ aforijin lọwọ wọn.

“Ẹ ma binu, mo bẹ ọkunrin, obinrin, ọmọde, ẹ ma binu.”

Olaiye tẹsiwaju pe ọpọ eeyan lo ni pe nitori oun ti bẹbẹ tumọ si pe oun kabamọ pe oun ṣe atilẹyin fun Tinubu sugbọn o ni ọrọ ko ri bẹ rara.

“Mi o kabamọ pe mo ṣe atilẹyin fun Tinubu rara, koda ti n ba ni anfani lati tun ṣe atilẹyin fun un lati ṣe aṣeyọri, ti orilẹede Naijria ma fi tuba tusẹ, ma a tun ṣe.

“Ti awọn eeyan wa to wa ni ilẹ okeere ma fi ri pe ilu wa ti yi pada si rere, maa tun ṣe atilẹyin.

“Ohun ti mo bẹbẹ fun ni awọn ololufẹ mi to n fun mi ni ounjẹ pe ki wọn mase pada lẹyin mi.

“Pe ohun to mu mi gbe igbesẹ yii ni iran kan to waye sugbọn irufẹ eyi ko ni waye mọ.”

"Ireti si wa fun Naijiria"

Olaiye Igwe ni oun kan si awọn eekan ilu kan nitori pe oun ko ti ni anfani lati ri Aarẹ ba sọrọ, lori ibi ti ọrọ Naijiria doju kọ.

O ni ẹni to ba oun sọrọ salaye bi ibanujẹ ṣe ba Aarẹ lori bi eto ọrọ aje ṣe mẹyẹ lasiko yii, ti ebi si n pa araalu.

Sugbọn o jẹ ko di mimọ pe oun si ni igbagbọ pe nnkan yoo yatọ laipẹ lorilẹede Naijiria.

“Ireti wa fun wa sugbọn o soro lati sọ eyi nita nitori wọn le sọ oko.

“Mo fẹ bẹ Aarẹ lati maa ṣe ipade, lati ma jabọ fun araalu lori bi nnkan ṣe n lọ lorilẹede Naijiria.

“Ki ọkan araalu le balẹ, Aarẹ ni lati sọ fun awọn araalu pe bi nnkan se jẹ ree.”