Olaiya Igwe: Ilà ójú mi, ló wà lójú ìyá MC Oluomo, ọ̀gá àti àbúrò mi ni – Olaiya Igwe
Ta ba se ni loore, ọpẹ la n du nitori ẹni ta se loore, ti ko dupẹ, bii igba ti ọlọṣa ko ni lẹru lọ ni.
Eyi ni alaye gbajumọ osere tiata, Alhaji Lukman Ebun Oloyede, ti ọpọ eeyan mọ si Olaiya Igwe, to fi n yira nilẹ lasiko ti o gba ẹbun ọkọ bọginni kan.
Alaga pata fun igbimọ to n se akoso ibudokọ ero nipinlẹ Eko, Alhaji Musiliu Akinsaya, ti ọpọ mọ si MC Oluomo lo fi mọto naa ta Olaiya Igwe lọrẹ.
Ayajọ ọjọ ibi rẹ si ni MC Oluomo gbe mọto naa fun lairotẹlẹ, to si wo lulẹ lojiji, to n yi nilẹ lori oore kanka naa.
- Olaiya Igwe ò kú o, àyè ló wà
- Mi ò lágbára tàbí oògùn ṣùgbọ́n.....- Olaiya Igwe lẹ́yìn àìsàn kíndìnrín tí ayé fi kéde ikú rẹ̀
- Àwọn tó ń ṣe ayédèrú fíìmù fẹ́rẹ̀ sọ mí di ẹni ilẹ̀ lẹ́yìn tí mo pàdánù N52m- Olaiya Igwe
- ₦50m ni mo pàdánù lórí sinimá tí mo ṣe kẹ́yìn tórí àwọn tó ń ṣe ayédèrú fíìmù - Olaiya Igwe
- Eré wa ni kẹ wò, ẹ má wo aṣemáṣe àwa onítíátà - Olaiya Igwe
- Wọ́n fún mi ní ‘Biscuit’ jẹ ní òde àṣé Igbó ni, inú gbọ̀ngàn ayẹyẹ wá dàbí ebè lójú mi – Olaiya Igwe
Ọpọ eeyan to wo fidio to jade sori ayelujara lori bo se n yi nilẹ nigba to gba kọkọrọ mọto naa, lo n bu ẹnu atẹ lu osere tiata yii pe o fi agba ara rẹ wọlẹ.
Ẹnu pọ to kun Olaiya Igwe lori igbesẹ naa, idi si ree ti BBC Yoruba fi kan si lati mọ iha to k si eebu yii ati idi to se n yi nilẹ fun ẹni to j aburo si.
‘Awọn eeyan ti ko loye tabi mọ Ọlọrun lo n bu mi pe mo yira nilẹ fun MC Oluomo’
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, gbajumọ osere, akọtan ati agbe sinima jade naa ni titi lai lo yoo maa dupẹ oore fun awọn eeyan to ba se oun loore.
O ni oun ti lo ọpọlọpọ ọkọ ayọkẹlẹ ri, titi dori ọkọ Navigator amọ ọkọ eleyi jẹ ẹbun ti oun ko reti rẹ, to si ba oun lojiji pẹlu.
Olaiya, ẹni to salaye bi isẹlẹ naa se waye tun woye pe awọn eeyan to loye tabi mọ Ọlọrun lo n bu oun pe oun yira nilẹ lori oore ojiji, ti oun ko ro tẹlẹ.
‘Mo fẹ daku lọjọ ti MC Oluomo fun mi ni mọto, boya eyi gan ni ko ba jọ yin loju’
Olaiya Igwe tẹsiwaju pe ẹbun ọkọ naa ba oun lojiji debi pe oun fẹ daku lọjọ ti MC Oluomo fun oun ni mọto naa.
“Boya ti mo ba tiẹ ti daku lọjọ naa ni, ẹgba ni awọn to n bu mi ko ba fi na mi pe mo daku.
N ko ni jawọ lati maa dupẹ oore lọwọ ẹni to ba se mi loore, mo rababa, mo si yira fun Ọlọrun ni nitori eeyan kankan ko ni ga ju Ọlọrun to da lọ.”
- Agbẹjọ́rò mi yóò tẹsẹ̀ òfin bọ ìṣẹ̀lẹ̀ Shoprite àmọ́ àwọn aláṣẹ ibùdó ìtajà náà sì ń bẹ̀ mí lọ́wọ́ - Toyin Asewo to re Mecca
- Yorùbá kìí ṣe egúngún oníhòhò, ìwà wèrè ni sinimá oníhòhò táwọn òṣèré kan ń ṣe- Lere Paimo
- Àwọn ǹkan ti ọ̀pọ̀ ko mọ nípa Baba Suwe
- Àwọn Òṣèré fíìmù Yorùbá tẹ́ ò ro tó tí jápaa lọ ìlú Òyìnbó rèé
- Mo kan sara sawọn ayasọlo- Dayo Amusa
- Àwọn ìlúmọ̀ọ́ká Mẹ́wàá to kú nínú oṣù keje odun 2021
- Mercy Aigbe ṣá ọmọ rẹ̀ sínúu fíìmù tuntun, wo itú tí ọmọ ọdún mẹ́wàá náà pa
‘Aburo ati ọga ni MC Oluomo jẹ fun mi’
Nigba to n salaye iru ajọsepọ to wa laarin oun ati MC Oluomo, gbajumọ osere tiata naa ni ọmọ bibi ilu Abeokuta ni iya eekan ẹgbẹ awakọ naa, to tun jẹ ilu oun.
“Ila to wa loju mi yii, lo wa loju iya MC Oluomo nigba to wa laye, Abeokuta ni emi ati iya naa ti wa, aburo ni MC Oluomo jẹ si mi.
Ọga ati Kabiyesi ni mo maa n pe nitori ipo ti Ọlọrun gbe si nitori Ọlọrun gan ni ka maa se apọnle ẹni ti oun na gbega.
Bakana naa, agbegbe Ajao ni emi ati MC dijọ n gbe, ẹ ba fi mi silẹ, ki lọrun se bo se fẹ se fun mi.”
Olaiya wa pari ọrọ r pe ọpọ eeyan lo pe oun lori foonu lati ki oun ku oriire ẹbun ọjọ ibi naa, ti wọn ko si tabuku bi oun se yira nilẹ.
O wa yan pe awọn ‘ero’ lo n bu oun lori ayelujara nitori awọn ‘eeyan’ ti pe oun lati ki oun ku oriire.
- Àwọn òṣèré Nollywood tí wọn ò sí lóri amóhùmáwòrán mọ́
- Mo gbé àpótí aṣọ mẹ́ta ti bàbá mi fún ọ̀gá mi láti ṣeré tíátà, ẹ̀bí bá gbógun tì mí - Murphy Afolabi
- Bí mó bá fojú kan Baba Wande lórí ìtàgé, ṣe ní ẹ̀rù máa ń bà mí - Tafa Oloyede
- Iṣẹ́ ọpọlọ ló yẹ ká ṣe nínú tíátà, kìí ṣe àfihàn ara bíbó àbí ìhòòhò wa - Binta Mọgaji
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?




