Àwọn ènìyàn ìlú Osi rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba àpapọ̀ lórí afárá Ẹ̀rọ́

Afara Ero

Àwọn ọ̀dọ́ ìlú Osi ní ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti, ìpínlẹ̀ Kwara ti rọ ìjọba àpapọ̀ láti bójú àánú wò wọ́n lórí afárá Ẹ̀rọ́ tó wà ní ìlú náà.

Àrọwà yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí ìjọba àpapọ̀ fún iléeṣẹ́ kan láṣẹ láti wó afárá náà.

Ààrẹ àwọn ọ̀dọ́ ní ìlú Osi, Kayode Bamidele Ogborogan ṣàlàyé fún BBC News Yoruba ìdí tí wọ́n ṣe ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba lórí afárá ọ̀hún.

Ogborogan ní lọ́jọ́ Kejìdínlógún oṣù Kìíní ọdún 2024 ni àwọn ṣàdédé rí àwọn kan tí wọ́n ń wó afárá náà.

Ó ní nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ ìlú súnmọ́ àwọn ènìyàn náà láti mọ ìdí tí wọ́n ṣe ń wó afárá náà ni wọ́n ṣàlàyé pé ẹnìkan ló gbé iṣẹ́ fún àwọn láti wó afárá yìí.

Ó tẹ̀síwájú pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn nígbà tí wọ́n fi lẹ́tà han àwọn pé ìjọba àpapọ̀ ti ta afárá náà fún àwọn, pé ìdí nìyí tí àwọn fi ń wo.

Ogborogan fi kun ọ̀rọ̀ pé èyí ló mú àwọn gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan láti mọ̀ pé lóòótọ́ ni ìjọba fún àwọn ẹni náà láṣẹ láti wó afárá náà.

Ó ṣàlàyé pé ìròyìn náà bá àwọn lọ́kàn jẹ́ nítorí ìwúlò tí afárá náà ni pọ̀ pupọ̀ fún wọn ní ìlú Osi, tó sì ní ipa tó ń kó lórí ètò ọrọ̀ ajé ìlú àwọn.

Kí ni ìwúlò afárá náà fún ìlú Osi?

Afara Ero
Afara Ero
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ogborogan ṣàlàyé pé afárá náà já sí oko tí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ìlú wọn ń dá ní agbègbè náà bí ó ṣe jẹ́ pé àgbẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ìlú Osi.

Ó ní afárá náà jẹ́ kí gbígbé èrè oko àwọn ènìyàn ìlú náà rọrùn láti ibìkan bọ́ sí ibòmíràn.

Bákan náà ló fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ọdún 1926 ni ìjọba ti kọ́ afárá náà, ó ní afárá náà ṣì le dáadáa kódà ju tuntun tí wọ́n kọ́ fún wọn lọ.

"A ri pé afárá yìí kò ní ìpalára kankan tó ń ṣe fún ènìyàn tàbí pé ó ti hù ní ibì kankan tó fi lè ṣe àkóbá fún ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn wa.

"Kìí ṣe pé afárá náà ti ń mì tàbí pé ó fẹ́ wó, ó wúlò gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà míì tí àwọn ènìyàn lè máa gbà tí nǹkan bá ṣe èyí tí à ń lò lọ́wọ́ báyìí."

Ogborogan tẹ̀síwájú pé ọ̀nà tí afárá náà wà já sí ọgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìpínlẹ̀ Kwara tí ìjọba ń kọ́ sínú ìlú náà ti yóò sì wúlò púpọ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ ní ìlú náà.

"Tí wọ́n bá fi lè wó afárá yìí, ó túmọ̀ sí pé ọ̀nà kan péré ni a lè máa gbà wọ inú tàbí gba jáde.

"Pẹ̀lú bí ètò ààbò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣe ń lọ kò yẹ kó jẹ́ pé ọ̀nà kan péré ni a lè máa gbà wọlé tàbí jáde kúrò nínú ìlú."

Ó ní gbogbo àwọn ìwúlò yìí ni àwọn fi ń ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba láti jọ̀ ọ́ jàre fi afárá náà kalẹ̀ fún àwọn láti tún máa lò ó, kí wọ́n má wo nítorí ó ń ṣe àǹfàní tó pọ̀ fún àwọn.

Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni wọ́n ti gbé lórí ọ̀nà náà?

Afara Ero tuntun

Akọ̀wé àgbà fún Osi Welfare Association, Emmanuel Bamidele so fún BBC News Yoruba pé ní kété tí àwọn ti rí pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní wo afárá náà ni àwọn ti kọ ìwé sí iléeṣẹ́ tó rí sí iṣẹ́ òde ní Nàìjíríà láti bẹ̀ wọ́n pé kí dáwọ́ dúró lórí ìgbésẹ̀ náà.

Emmanuel Bamidele ní gbogbo àwọn ìwúlò afárá náà ni àwọn ti kọ sínú ìwé tí àwọn fi ránṣẹ́ sí wọn kí wọ́n lè mọ ìwúlò afárá náà fún àwọn ènìyàn Osi.

Òun náà rọ ìjọba láti fi afárá náà kalẹ̀ fún àwọn láti ṣe àtúnṣe sí gbogbo ibi tí wọ́n ti wó níbẹ̀ kí ọ̀nà náà le ṣeé gbà padà.