Èmi kọ́ ni mo fa ìṣoro tó n kojú Nàìjíríà lásìkò yìí – Cardoso, Gómìnà CBN

Aworan Olayemi Cardoso

Oríṣun àwòrán, CBN/Facebook

Àkọlé àwòrán, Cardoso

Gomina banki agba lorileede Naijiria, Ọlayẹmi Cardoso ti sọ pe oun ko lọwọ ninu ipenija eto ọrọ aje to le koko, eyi ti awọn araalu n koju lasiko yii.

Cardoso lo sọrọ naa nibi ipade igbimọ to n ṣakoso ilana lori ọrọ owo, Monetary Policy Committee (MPC) to jẹ alaga rẹ.

Nibẹ lo ti sọ pe kii ṣe igbimọ naa lo fa iṣoro to n koju eto ọrọ aje Naijiria, eyi to mu ipenija ba raalu.

Cardoso fidi rẹ mulẹ pe banki agba Naijiria ti n gbe awọn igbesẹ to yẹ lati mu ki ilera to pe ye ba ilana ẹka eto owo, ti yoo si pada bọ sipo.

“Ẹrin maa n pa mi nigba ti wọn ba beere pe ilana ti CBN gbe kalẹ lori ọrọ lo fa ipenija eto ọrọ aje, ṣugbọn ki ṣe ọrọ ẹrin rara, ati pe mo ro pe o ṣe pataki ki awọn ọmọ Naijiria mọ pe emi ti mo jẹ gomina CBN ati awọn igbimọ mi ko mọ ohunkohun nipa ohun to n ṣẹlẹ yii.

“Ọna abayọ la n wa.

A si ti ṣe ipinnu lati rii pe a jade kuro ninu wahala ti Naijiria wa ninu ẹ yii.

“A de lasiko ipenija, ṣugbọn ti a ko le fa ọwọ agogo sẹin.

“Ohun gbogbo ti a le ṣe ni lati gbe awọn igbesẹ to le, latile mu ki ohun to le koko di ẹrọ.

Mo si nigbagbọ pe yoo ṣee ṣe, nitori pe pẹlu igboya la maa fi ṣe e.”