Wo ǹkan mẹ́jọ tó yẹ kó o mọ̀ nípa ọkọ̀ ojú irin ‘Red Line’ tó bẹ̀rẹ̀ l’Ékòó

Ọjọbọ ọsẹ yii ni Aarẹ Bọla Tinubu ṣe ifilọlẹ ọkọ oju irin tuntun, ‘Red Line’ niluu Eko, eyi ti Gomina Babajide Sanwo-Olu ṣagbatẹru rẹ.
Agbekalẹ yii waye lati mu igboke-gbodo ọkọ rọrun fawọn eeyan ipinlẹ Eko, ko si tun bu iyi kun ilu naa ju ti tẹlẹ lọ.
Wọnyi lawọn koko to yẹ ko o mọ nipa ọkọ oju irin Red Line tuntun naa.
Kókó mẹ́jọ
*O kere tan, ọkọ yii yoo maa rin lẹemẹtadinlogoji (37 trips) lojumọ, yoo si gbe ju ẹẹdẹgbẹta ẹgbẹrun eeyan lọ (500,000).
*Ibudokọ mẹjọ lo wa lati Agbado, nipinlẹ Ogun to fi de ipinlẹ Eko bii Iju, Agege, ikẹja, Oṣodi, Muṣin, de Oyingbo .
* Aaye to ṣee gba fun mọto ati afara ẹlẹsẹ ti ko ni i jẹ ki sunkẹerẹ-fakẹẹrẹ ba ọkọ oju irin yii ti wa nilẹ sẹpẹ.
*Eyi yoo jẹ ki kaluku rin tiẹ nirọrun, aabo to peye yoo si wa fawọn to n fẹsẹ rin pẹlu.
* Ajọ Lagos Metropolitan Area Transport Authority (LAMATA)lo n dari ọkọ oju irin Red Line, labẹ ileeṣẹ igboke-gbodo ọkọ nipinlẹ Eko.
* Ọkọ oju irin yii wa fun lati din sunkẹerẹ-fakẹẹrẹ ọkọ ku, din ijamba ọkọ ku ati fun aabo awọn eeyan.
* Epo diisu ni ọkọ oju irin Red Line yoo maa lo.
* Okoowo nla ni agbekalẹ ọkọ oju irin yii, ko din ni $135m ti wọn kọkọ ya sọtọ fun un labẹ akoso LAMATA.















