Àwọn nǹkan kan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Mr. Ibu tó di olóògbé

Mr Ibu

Oríṣun àwòrán, Other

Gbajumọ oṣere, John Okafor, ti ọpọ mọ si Mr. Ibu, ti jade laye.

Ẹnikan to jẹ ọrẹ oserekunrin naa, sugbọn ti ko fẹ ka da orúkọ rẹ sọ fun BBC pe lootọ ni oṣere naa ku lọjọ keji, oṣu Kẹta, ọdun 2024.

Amọ ẹbi rẹ ko tii sọ ohunkóhun.

Onitọhun salaye pe ileewossn kan nipinlẹ Eko, nibi ti Mr. Ibu ti n gba itọju fun ẹsẹ rẹ kan ti wọn gé lọdun 2023, lo ku si.

Bakan naa ni aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere ni Naijiria, Emeka Rollas, ti fi idi iku rẹ mulẹ.

Ọgbẹni Rollas fidi eyi mulẹ ninu ọrọ kan to kọ si ori ayelujara Instagram, sọ pe aisan ọkan lo pa a.

Iroyin sọ pe lati igba ti wọn ti ṣe iṣẹ abẹ keji fun ni ẹsẹ laipẹ yii, ni ara rẹ ko ti ya daadaa mọ.

Oṣere mii tun fidi iku rẹ mulẹ fun BBC Igbo.

BBC gbiyanju lati ba ọkan lara awọn ọmọ Mr. Ibu, Chioma Jasmine Okafor, sọ̀rọ̀, ṣugbọn ko gbe ipe rẹ titi di akoko ti a gbe iroyin yii jade.

Oṣu Kọkanla, ọdun 2023, ni mọlẹbi gbajugbaja oṣere tiata lorilẹede Naijiria, John Okafor, ti ọpọ mọ si Mr Ibu kede pe oṣere naa ti padanu ẹsẹ rẹ kan lori igbiyanju wọn lati mu nwa layẹ.

Mr Ibu wa nile iwosan fun ọpọlọpọ ọjọ, ti awọn ọmọ Naijiria si dawo jọ fun lati fi tọju ara rẹ.

Ninu atẹjade ti mọlẹbi fi soju opo ayẹlujara Mr Ibu, salaye pe Mr Ibu ti ṣe isẹ abẹ meje sugbọn lati ri pe o wa laaye, wọn ni lati ge ọkan lara ẹsẹ rẹ.

Nnkan to yẹ ki o mọ nipa Mr. Ibu

Mr. Ibu

Oríṣun àwòrán, Other

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 1961, ni wọn bi John Ikechukwu Okafor.

Ọmọ ipinlẹ Enugu ni.

Mr. Ibu ṣe orisirisi iṣẹ bii onidiri, ayaworan ati awọn iṣẹ pẹpẹẹpẹ mi ṣaaju ko to di oṣere.

Lẹyin to pari nile ẹkọ girama, iroyin sọ pe aisi owo ko jẹ ko lọ si ile ẹkọ giga, botilẹ jẹ pe, o ri anfaani lati wọle.

Ṣugbọn nitori ifẹ to ni si eto ẹkọ, o pada lọ si ile ẹkọ imọ ẹrọ, Institute of Management and Technology (IMT), niluu Enugu, nigba ti owo de ọwọ rẹ.

Ọdun 1998 ni Mr. Ibu bẹrẹ ere ṣíṣe, amọ ogo rẹ ko buyọ titi di ọdun 2004, nigba to kopa ninu ere Mr Ibu.

Ere naa si lo fi gba ami ẹyẹ rẹ akọkọ

O le ni igba fiimu ti Ọgbẹni John Okafor ti kopa nigba aye rẹ.

Lara wọn ni Mr. Ibu, Mr. Ibu 2 , Mr. Ibu and His Son, Coffin Producers, Husband Suppliers, International Players, Mr. Ibu in London, Police Recruit, 9 Wives, Ibu in Prison ati Keziah.

Oloogbe Okafor tun fi igba kan kọrin, to si gbe rẹkọọdu orin to pe ni 'This girl' ati 'Do you know', jade ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.