Kò tíì pé ọdún kan tí ìyá wa kú tí Sisi Quadri náà tún jáde láyé – Àbúrò olóògbé

Àkọlé fídíò,

Aburo Sisi Quadri, Oyebamiji Muktar, ti sọ pe ko pẹ ti iya awọn jade laye ti Sisi Quadri naa tun tẹle.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba lo ti fi ọrọ naa lede lọjọ Abamẹta.

O ni ko tii pe ọdun kan ti iya awọn jade laye ti Quadri naa tun papoda.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, oloogbe naa ṣi fun awọn lowo ṣaaju iku rẹ.

O ni “Ko si ohun to ṣe wọn, o ko N300,000 to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ fun wa pe ki a ko dani nitori a le nilo owo.

“Lẹyin naa lo tun fi miliọnu kan naira mii ṣọwọ sinu akanti wa, ko si nnkan to ṣe e.

“Nigba ti a de LAUTECH ni Ogbomosho, oun funra rẹ lo fi ẹsẹ ara rẹ wọ inu ile iwosan naa.”

Muktar pari ọrọ rẹ pe ibanujẹ nla ni iku Sisi Quadri jẹ fun ẹbi awọn nitori ko tii to ọdun kan ti iya awọn jade laye ki Sisi Quadri naa to papoda.

Sisi Quadri

Oríṣun àwòrán, bbc

'Ikú Sisi Quadri wáyé lẹ́yìn tó rí 'Visa' Amẹ́ríkà gbà'

Aworan Sisi Quadri

Oríṣun àwòrán, fathiaentertainments_showbiz

Ọga ileeṣẹ Faihia Entertainment, Olawale B ni gbajugbaja oṣere tiata to di oloogbe, Tolani Oyebamiji, ti ọpọ mọ si Sisi Quadri ti ri Visa orilẹede Amẹrika gba ko to di pe o jade laye.

Olawale sọ ọrọ yii loju opo ayelujara Instagram rẹ, @fathiaentertainments_showbiz lọjọ Ẹti lẹyin ti iroyin nipa iku Sisi Quadri gbode.

O ni, “O ba mi lọkan jẹ lati gbọ nipa iku gbajugbaja oṣere tiata, @iamsisiquadri, wọn ti buwọlu iwe irinna rẹ, ti a si ti mu ọjọ sugbọn ta ni wa ti a fẹ bi Ọlọrun?”

Oloogbe naa lo jade laye lẹni ọdun mẹrinlelogoji, to si jẹ ilumọka oṣere nigba aye rẹ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, fathiaentertainments_showbiz

Taa ni Sisi Quadri, oṣere tiata to di oloogbe?

Sisi Quadri, ẹni ti orukọ abisọ rẹ n jẹ Tolani Quadri Oyebamiji ni o jẹ ilumọka alawada oṣere tiata Yoruba.

O di ilumọka fun ipa to ko ninu ere sinima to jade lọdun 2004, Seniyan Seranko.

Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kejila ọdun 1979 ni wọn bi Sisi Quadri niluu Iwo nipinlẹ Osun.

O kawa jade ni ile ẹkọ gbogbo nise Poly Iree nipinlẹ Osun.

O fẹ Iyawo, to si ọmọ ọkunrin meji, Olamilekan Oyebamiji and Olamide Oyebamiji, ki ọlọjọ to de.

Òsúkè lásán ló ṣe Sisi Quadri, kódà ẹsẹ̀ ara rẹ̀ ló fi rìn wọ ilé ìwòsàn LAUTECH – Àbúrò olóògbé

Sisi Quadri

Oríṣun àwòrán, Sisi Quadri/BBC

Ọkan lara awọn aburo oloogbe Sisi Quadri, Oyebamiji Muktar, ti ṣalaye fun BBC Yoruba bi irinajo bi iku oloogbe naa ṣe waye.

Okunrin naa sọ pe awọn ti kọkọ gba ipe kan pe o ṣubu nibi to ti n ṣere ori itage lọwọ ki wọn to gbe wale.

O ni “Ni ọjọ kọkandinlogun ni wọn pe wa pe wọn ṣubu nibi ti wọn ti n ṣere itage lọwọ, aburo wa dẹ lọ gbe wọn nibẹ wale.

“A gbe wọn lọ sile iwosan, wọn si ṣe ayẹwo fun nibẹ, wọn si sọ pe aisan iba ni wọn ni, wọn si ṣetọju wọn nibẹ.

Yatọ si aisan iba ti Sisi Quadri ni, aburo rẹ ọhun tun sọ fun BBC pe o ni arun ọgbẹ inu amọ wọn n tọju rẹ.

Muktar sọ pe oloogbe naa ṣi fi owo ranṣe si awọn lọjọ kejidinlogun, oṣu Keji, ọdun 2024 yii pe ki wọn fi gbẹ kọngadẹrọ ni iranti iya wọn to di oloogbe ni nnkan bii ọdun kan sẹyin.

O fi kun ọrọ rẹ pe oloogbe naa kii sinmi lẹyin ọpọlọpọ iṣẹ amọ awọn mọlẹbi rẹ maa n gbiyanju lati ri daju pe o n sinmi, koda, awọn ti fi akoko igba kan pa foonu rẹ ri ki wọn ma baa pe fun iṣẹ.

O ṣi fun wa lowo ki a to lọ sile iwosan

Muktar sọ siwaju si pe aisan to yọri iku oloogbe naa kii ṣe aisan to da dubulẹ.

O ni “Ko si ohun to ṣe wọn, o ko N300,000 to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ fun wa pe ki a ko dani nitori a le nilo owo.

“Lẹyin naa lo tun fi miliọnu kan naira mii ṣọwọ sinu akanti wa, ko si nnkan to ṣe e.

“Nigba ti a de LAUTECH ni Ogbomosho, oun funra rẹ lo fi ẹsẹ ara rẹ wọ inu ile iwosan naa.”

Muktar pari ọrọ rẹ pe ibanujẹ nla ni iku Sisi Quadri jẹ fun ẹbi awọn nitori ko tii to ọdun kan ti iya awọn jade laye ki Sisi Quadri naa to papoda.