Ó ti lé ni 30,000 tó ti bá ogun lọ ní Gaza – Hamas

Gaza

Oríṣun àwòrán, getty images

Ileeṣẹ eto ilera Hamas ti fidi ẹ mulẹ, pe o ti le ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn eeyan (30,000) ti wọn jẹ ọmọ Palestine ti wọn ti ku bayii ni Gaza.

Eyi bẹrẹ lati ọjọ keje, oṣu kẹwaa, ọdun 2023.

Ẹka eto ilera naa sọ pe ọmọde ati awọn obinrin lo pọ ju ninu awọn ti wọn pa yii.

Ninu atẹjade wọn l’Ọjọbọ, wọn fi han pe eeyan mọkanlelọgọrin (81), ni wọn pa lọjọ kan ṣoṣo, eyi to mu afikun ba ẹgbẹrun lọna ọgbọn ti wọn kede tẹlẹ.

Akọsilẹ tootọ to le sọ iye eeyan to ti ku ko si, gẹgẹ bi iwoye iṣẹlẹ yii.

Eyi ri bẹẹ nitori onka ti Hamas gbe jade ko kan awọn ti wọn ko de ileewosan ki wọn too ku.

Ọpọ eeyan lo ṣi wa labẹ àlàpà ti ile wo lu wọn mọlẹ si, nigba tawọn Isrẹli sọ ado oloro lati ofurufu, ti ẹnikẹni ko si ri awọn wọnyi mọ.

Mọṣuari n kun akunfaya, ija lọsibitu, ẹrọ ibara-ẹni-sọrọ ko ṣiṣẹ

Bi wọn yoo ba ṣe akọsilẹ iku ọmọ Palestine kan lasiko yii, wọn gbọdọ ri oku rẹ. Ileewosan yoo sọ ibi to ku si, ohun to pa a, asiko to farapa ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gbogbo eyi ni wọn ni ko dẹrun latari bi mọṣuari ṣe n kun akunfaya.

Ija tun n waye lawọn ọsibitu latari ai si ifọkanbalẹ, bẹẹ ni foonu ati ẹrọ intanẹti ki i ja gara.

Sugbọn bi asọye ọlọdun pipẹ lati pari ogun yii ba waye, igbiyanju lati yanju iṣoro yii yoo bọ si i.

Ohun kan taye n naka aleebu si bayii lori onka awọn ti wọn n ku ni pe wọn ko ṣe akọsilẹ bawọn Palestine ṣe n ku.

Boya ado oloro awọn Isrẹli lo n pa wọn ni, nnkan ija oloro mi-in ni tabi bẹẹ kọ.

Wọn ni gbogbo ẹ naa ni wọn n ka kun ikọlu Isrẹli.

Gaza

Oríṣun àwòrán, getty

Ajọ UN n kilọ, wọn lo ṣee ṣe ki ìyàn mu apa kan Gaza

Ajọ UN ṣalaye pe apa kan Gaza le lugbadi iyan laipẹ, bẹẹ ni ajakalẹ arun ti n pọ si i latari ai si oogun ati itọju.

Ọjọ keje, oṣu kẹwaa logun yii bẹrẹ, nigba ti ẹgbẹrun ọmọ ogun Hamas ya wọ Guusu Isrẹli.

Bi ọpọ ṣe doloogbe lawọn mi-in wa nigbekun ogun gẹgẹ bi akọsilẹ Isrẹli ṣe sọ.