Kí ni ìyàtọ̀ láàrín Oníṣẹ̀ṣe àti Oníṣègùn ìbílẹ̀ ?

Oríṣun àwòrán, Others
Ka to tẹnu bọrọ, o ṣe koko fun gbogbo ọmọ kaarọ ojiire lati mọ pe ṣinkun yatọ si gbagi ni ilẹ Yoruba.
Oniṣegun ati Oniṣẹṣe yatọ si arawọn ni gbogbo ọna ṣugbọn ki gan ni awọn iyatọ yii.
Ileeṣẹ BBC News Yoruba tọ awọn agbagba ninu ijinlẹ ede ati aṣa ilẹ Yoruba lọ lati tan imọlẹ si awọn nnkan yii.
Alaaye wọn jẹ ko di mimọ pe Onisẹṣe, eyi ti wọn tun le pe ni Babalawo lo le sọ nipa Ifa, ti Oniṣegun si ma n sọ nipa Ọsanyin.
O se koko lati mọ itumọ awọn ọrọ yii ka to mu ẹnu ba iyatọ to wa laarin wọn.
Awọn wo ni a n pe Oniṣẹṣe?
Dokita Oluseyi Atanda to jẹ Olori Onisẹṣe nipinlẹ Osun salaye pe ẹlẹsin ni Oniṣẹṣe, to si jẹ pe Oniṣẹṣe pin si ọna to pọ.
Dokita Atanda ni, gbogbo ẹni to ba n jọsin fun Olodumare ni ilana ti ibilẹ, to si n tọ ipasẹ orisa kan tabi omiran lati ba Olodumare sọrọ ni wọn ma n pe ni Oniṣẹṣe.
“Oniṣẹṣe le jẹ onifa, ti a n pe ni Babalawo, Onisango, Ọlọsun, Ọlọya, Elegun tabi Elesu.
“Ede kan naa lo ko gbogbo wa pọ ti a n pe ni IFA nitori pe Ifa ki i se eeyan, ọrọ ẹnu Olodumare ni ohun to n jẹ Ifa, to salaye bi Orisa kọọkan ṣe ri ati ojuse gbogbo wọn."
Atanda tẹsiwaju pe ẹsẹ Ifa kan fidi rẹ mulẹ ni ọkanran lọtun, ọwanrin ni ọwọ osi, eyi tun wọn sapaejuwe gẹgẹ bi ọkanran onilẹ.
Awọn wo ni a n pe ni Oniṣegun?
Aarẹ Jeayinfa Ayanwoye ninu fọnran kan to gbe sori ayelujara salaye pe Oniṣegun jẹ eeyan to jẹ onimọ nipa ka ja ewe, ati ka wa egbo, oogun ponbele tabi oogun atata.
Ayanwoye ni eeyan ti a ba ri to mọ nipa ka mu ewe kan tabi meji ka jo pọ pẹlu awọn nnkan mii, to si ke pe ọsanyin ni Oniṣegun.
“Ti wọn ba ni o dọwọ Babalawo, Babalawo a ni o dọwọ Ifa, ti wọn ba ni o dọwọ Oniṣegun, Oniṣegun a ni o dọwọ Ọsanyin.”
Ayanwoye ni Ọsanyin lo n kọ Oniṣegun nipa ewe ati egbo.
Dokita Atanda ninu alaye ti rẹ sọ pe, ẹni to n ja ewe ati egbo, to si fi n se iwosan lo n jẹ Oniṣegun.
O ni Oniṣegun ko ni ṣe pẹlu ẹsin kankan.
“A ti ri Oniṣegun to jẹ Alhaji, Alhaja, Olosha, Pasitọ ti ọpọ wọn si jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn Oniṣegun.
“Iṣegun ni wọn n ṣe, ko ni ṣe pẹlu ẹsin. Ṣugbọn ẹlẹsin ibilẹ naa le jẹ Oniṣegun, to mu gẹgẹ bi iṣẹ”
Ki wa ni awọn iyatọ to wa laarin Oniṣegun ati Oniṣẹṣe
- Ẹsin ni awọn Oniṣẹṣe n ṣe, iwosan ni awọn Oniṣegun n ṣe
- Ifa ni awọn Oniṣẹse ma n ba sọrọ sugbọn Ọsanyin ni awọn Oniṣegun ma n ba a ṣe
- Tewe-tegbo ni ami idanimọ awọn Oniṣegun, amọ ka wo ifa, ka ba awọn orisa sọrọ ni ti awọn Oniṣẹṣe.
- Oniṣegun ko ni ṣe pẹlu ẹsin kankan sugbọn iyẹn ko ni ki Oniṣeṣe ma jẹ Oniṣegun.












