Ọ̀gá Hisbah kọ̀wé fipò sílẹ́, lẹ́yìn tí Gómìnà Kano korò ojú sí bí wọ́n ṣe ń kojú àwọn ọ̀daràn

Ọga ikọ Hisbah nipinlẹ Kano, Sheikh Aminu Ibrahim Daurawa, ti kọwe fipo olori ikọ naa silẹ lẹyin ọjọ keji ti gomina ipinlẹ yii, Abba Kabir Yusuf, ṣo ero ọkan rẹ nipa ọna ti Hisbah n gba ṣiṣẹ wọn.
Ninu fidio kan ti Sheikh Daurawa fi soju opo Fesibuuku rẹ lo ti ṣalaye, pe ọrọ ti Gomina Abba Yusuf sọ da omi tutu soun lọkan, o si pa ẹmi ati ṣiṣẹ lara oun.
Gbajumọ Aafaa ni Kano naa sọ pe idi niyẹn toun fi kọwe fipo silẹ.
Sheikh Daura sọ pe oun ṣi n ni suuru fun Gomina lori ọrọ rẹ, oun si n tọrọ aforiji lọwọ rẹ fun boun ṣe kọwe fipo silẹ yii.
Ki ni Gomina sọ nipa Hisbah?
Gomina Abba Kabir Yusuf, nigba to n sọrọ nipa ikọ Hisbah, sọ pe ọna ti Hisbah n gba koju iwa ọdaran n ba oun lọkan jẹ gidi.
‘’ Mo ri fidio kan ti Ajọ Hisbah ti lọọ ba awọn ọdọ kan ti wọn ni ọdaran ni wọn, wọn n fi ọparun lu wọn.
‘’Wọn lu wọn bii ẹwurẹ, wọn tun gbe wọn ju sẹyin ọkọ. Wọn so wọn lẹsẹ, wọn fiya jẹ wọn.
‘’K’Oluwa ma jẹ ka ri wahala, bi eegun ẹyin ẹnikan ba lọọ kan nibẹ yẹn nkọ. Aṣiṣe nla gbaa ni ọna ti Hisbah n gba ṣiṣẹ wọn’’
Gomina tẹsiwaju pe oun ri fidio mi-in, nibi ti Hisbah ti lọ si Yunifasiti Bayero, ti wọn n lu awọn ọmọ ọlọmọ mọ yara wọn.
O ni Ajọ yii ni lati tun ero wọn pa pẹlu ilana ti wọn n gba koju iwa ọdaran, nitori ohun ti wọn n ṣe lodi si ilana ẹsin Islam ti wọn gba gbe e kalẹ.















