Ọkùnrin kan fipá bá obìnrin kan lòpọ̀ ní Kwara, ó ṣáa pa, ó tún dáná sun-ún

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti tẹ ọkunrin kan fun ẹsun pe o fi ipa ba arabinrin kan lopọ, to si tun saa lada, ko to sun oku rẹ nina, to si tun sọ sodo.
Isẹlẹ naa waye ni ilu Aran Ọrin ni ijọba ibilẹ Irẹpọdun, ipinlẹ Kwara.
Afurasi ọhun ni orukọ rẹ n jẹ Atolagbe Yemi Oje, ẹni ogoji ọdun, to si sekupa arabinrin Mayowa Ajiboye.
Afurasi naa ni o n ka boroboro ni ileeṣẹ ọlọpaa, lọjọ kọkandinlọgbon, osu Keji, ọdun 2024 nigba ti ileeṣẹ Ọlọpaa n se afihan rẹ ni olu Ileesẹ wọn to wa ni ilu Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara.
Àlàyé lórí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe wáyé
Gẹgẹ bi alaye ti Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara CP Victor Olaiya ṣe, o ni osu kọkanla ọdun tokọja ni Mayowa Ajiboye ti Ile Aro Olola Aran-Orin fun Atolagbe Yemi ti ile Iloko Aràn-Orin ni N1,600, lati ba a fi ra igi idan, amọ ko baa ra igi naa.
Ni ọjọ kejilelogun osu keji ọdun yi, Mayowa ati ọmọ rẹ, Ope lọ inu igbo lati wa igi fun ara wọn sugbọn wọn ba Atọlagbe ti o jẹ wọn ni igi lati ọdun tokọja nibẹ, o dara pọ mọ wọn lati wa igi, o si ni ki Ope gbe awọn igi ti wọn ti ri lọ si ẹkuu, Mayowa ko si mọ pe o ni ero ibi si oun.
Loju ẹsẹ ni afurasi naa mu Mayowa wọ inu igbo jiunjiun ni alaye pe wọn n wa igi lọ, lojiji ni o ko ẹsẹ Mayowa mejeji latẹyin nigba to n gba ipe lori ago, o si subu lulẹ, Mayowa fi igi ọwọ rẹ na an sugbon afurasi ọun gbaa lọwọ rẹ o si run run mọ an lori titi o fi daku.
"Lẹyin ti o fipa baa lo pọ lo ge irun abẹ rẹ"
Alaye tẹsiwaju pe o fi aṣọ funfun nu oju ara rẹ lati fi se ogun owo, o wa paa pẹlu ada, o si dana sun oku rẹ koto di pe o ju iyoku ara rẹ sinu odo lati rii pe asiri ko tu.
Kọmisanna naa fi kun un pe Atolagbe san ẹjẹ ara ada naa nu, o si fi pamọ.
Bakan naa lo mu foonu, siimu ati memory card inu foonu naa pamọ.
Ileesẹ Ọlọpaa ṣalaye pe asiri ọkunrin yii tu nipasẹ Ope ọmọ oloogbe naa nigbati ko ri iya rẹ mọ to si mọ ẹni ti wọn jọ wagi lọ inu igbo.
CP Olaiya sọ di mimo pe awọn yoo wọ lọ ile ẹjọ ni kete ti iwadi bati pari lori rẹ.
BBC News Yoruba fọrọwa afurasi ọhun lẹnu wo, o sọ wi pe idi ti ohun fi gbẹmi arabinrin naa ni ki o ma ba tu asiri oun lẹyin ti oun fipa baa lo pọ tan.
O ni ọmọ ogoji ọdun ni oun, oun ko si mọ bi oun yoo se sọ fun Mayowa pe oun ni ifẹ rẹ nitori o ju oun lọ lọjọ ori ni oun se gbe gba ọna ika naa.















