Àwọn kan fẹ́ f'ìlú sílẹ̀ lẹ́yìn tí ilé aṣòfin ṣàgbékalẹ̀ àbá tó tako ìfẹ́ akọ sáko

Oríṣun àwòrán, getty
Lati igba ti ile igbimọ aṣofin orilẹ-ede Ghana ti fi aba kan to n gbogun ti awọn ọkunrin to n ni ibaṣepọ pẹlu ọkunrin ẹgbẹ wọn, atawọn abọ to n ba ara wọn lo pọ ṣọwọ si aarẹ wọn lati buwọ lu ni idaamu ti ba awọn eeyan ti ọrọ yii kan.
LGBTQ ti itumọ rẹ jẹ ’Lesbian, Gay, Bisexual, Transgender and Queer’ ni awọn eeyan ti ibalopọ akọ si abo ko wu, to jẹ irufẹ ẹya wọn ni wọn maa n ba laṣẹpọ.
Awọn toyinbo n pe ni 'Transgender' ni wọn maa n yi ara wọn pada si obinrin bi wọn ba jẹ ọkunrin tẹlẹ, ọkunrin wọn yoo si parada labẹ iṣẹ abẹ yoo di obinrin.
Queer lawọn ko ṣakọ, ko ṣabo ti wọn ki i jẹwọ iru eeyan ti wọn jẹ.
Ko fẹrẹ sibi tawọn eeyan yii ko si, ṣugbọn ni bayii, orilẹ-ede Ghana ti gbe aba ti yoo sọ wọn di arufin jade
Ki ni yoo ṣẹlẹ bijọba Ghana ba buwọ lu aba naa?
Bi Aarẹ Ghana ba fi le buwọ lu aba to n gbogun ti awọn -LGBTQ yii, yoo to ẹwọn ọdun mẹta ti ẹni to ba lufin yii yoo fi jura bi ofin orilẹ-ede Ghana ṣe wi.
Yatọ sẹni to n kopa ninu awọn aṣa naa, ẹnikẹni to ba lọwọ si ipolongo wọn naa yoo ṣẹwọn labẹ ofin.
Koda, ẹwọn awọn to ba ṣagbatẹru -LGBTQ yoo to ọdun marun-un bi wọn ṣe wi labẹ ofin orilẹ-ede Ghana.
Awọn tọrọ kan sọ ero ọkan wọn
Kwame Narh (ojulowo orukọ rẹ gan-an kọ niyẹn) sọ fun BBC pe niṣe lo n ṣe oun bii koun fi orilẹ-ede Ghana silẹ pẹlu aba buruku ọhun.
O ni bi wọn ba fi le buwọ lu u, oun yoo sa kuro ni Ghana ni.
Kwame sọ pe ọmọ ẹgbẹ LGBTQ toun jẹ ti jẹ koun padanu iṣẹ oun ri, nigba ti ọga oun sọ pe Bibeli ko faaye gba ẹgbẹkẹgbẹ bẹẹ.
O loju oun n ri mabo lai ti i jẹ pe aba naa di ofin, to ba dofin pẹnrẹn, oun yoo gba ibo mi-in lọ ni.
Bakan naa ni Josh Tinder (orukọ tiẹ naa gan-an kọ niyẹn) sọ fun BBC pe awọn ẹbi oun le oun nile, nigba ti wọn mọ pe oun n ni ibalopọ akọ si akọ.
‘’Mi o le rin bo ṣe wu mi ni Ghana mọ bayii, mo n ṣọ ara mi gan-an ni, nitori awọn eeyan ti n sọ ọrọ ikoriira nipa awa ta a jẹ LGBTQ.
‘’Mi o le jẹ ki wọn lọọ fa mi fun ọlọpaa o’’
Ọjọ meje ni ofin fun Aarẹ Ghana lati buwọ lu ofin naa.
Bi aarẹ ba pinnu pe oun ko ni i buwọ lu u, ofin fun un lọjọ mẹrinla lati kọwe alaye sawọn aṣofin, lori idi ti ko ṣe fẹẹ sọ aba naa di ofin.
Awọn ajafẹtọọ ọmọniyan lawọn yoo woju ijọba to ba buwọ lu u
Ọjọgbọn Audrey Gadzekpo ti i ṣe alaga Center for Democratic Development (CDD) ti sọ pe aba naa yoo tẹ ẹtọ awọn LGBTQ loju mọlẹ bijọba ba buwọ lu u.
O ni ki wọn ma ti i ṣe ohun to jọ bẹẹ.
Awọn ẹtọ bii ominira ara ẹni, iyi, anfaani lati wa ninu ẹgbẹ to wu ni ati bẹẹ bẹẹ lọ ni aba yii yoo tẹ loju ti ba di ofin bo ṣe wi.
‘’A maa lọ sile-ẹjọ to ga julọ bi aarẹ ba fi le buwọ lu u’’
Ọga ajọ kan ti wọn n pe ni Commission For Human Rights and Administrative Justice (CHRAJ), Joseph Whottal lo sọ eyi di mimọ.
Bakan naa ni ọga ajọ UNAIDS, Winnie Byanyima, sọ pe ofin ti yoo koba gbogbo eeyan lo n bọ ni Ghana yii, yoo si mu ibẹru-bojo pọ si i ni.
O ni yoo ko ba idagbasoke orilẹ-ede naa, yoo si ṣakoba awọn eto to n dabo bo ẹmi.
Ajọ ayanilowo, IMF naa lawọn ko fara mọ aba yii.
Wọn ni ki kalulu ṣe bo ṣe fẹ lo n mayegun.
IMF ni awọn si maa n wo alaafia ati ominira ilu tawọn fẹẹ ya lowo kawọn too ṣaanu wọn.














