Wo oúnjẹ tí ìyá tó ń tọ́mọ lọ́wọ́ le è jẹ, bí ọ̀pọ̀ oúnjẹ ṣe gbówó lórí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Aisha Babangida
- Role, Broadcast Journalist
- Reporting from, BBC News, Abuja
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Bí ipa ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ àti gbogbo nǹkan túnbọ̀ ṣe ń nípa lórí àwọn ènìyàn Nàìjíríà, àrà ọ̀tọ̀ tún ni ipa tó ní àwọn ìyá tó ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́. Àwọn ìyá tó ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́, tó ń fún ọmọ lọ́yàn nílò láti jẹun gídi kí wọ́n lè fún àwọn ọmọ wọn lọ́yàn dáadáa.
Àmọ́ bí ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ ṣe ń peléke si ló ń kó ìpalára bá àwọn ìyá tó ń tọ́ ọmọ lọ́wọ́ láti lè fún àwọn ọmọ wọn lọ́yàn.
Àwọn oúnjẹ tí Zainab Suleiman, ẹni tó jẹ́ ìyá tó ní ọmọ oṣù méje lọ́wọ́ ni ìrẹsì, sẹ̀mó, iṣu àti ọ̀dùnkún. Ó ní òun tún fẹ́ràn láti máa mú mílìkì àti tíì àti pé òun fẹ́ràn láti máa jẹ èso bíi ọ̀gẹ̀dẹ̀, ọsàn àti ápù. Ó ní àwọn oúnjẹ yìí máa ń jẹ́ kí omi ọyàn òun jáde dáadáa.
Àmọ́ láti bíi oṣù mẹ́rìn sẹ́yìn, Zainab Suleiman ní òun kò lè ra àwọn oúnjẹ yìí mọ́ nítorí bí iye owó àwọn orí oúnjẹ náà ṣe ti gbówó lórí.
Ohun tó ń ṣe abọ́yadé gbogbo ọlọ́ya ló ń ṣe ni ọ̀rọ̀ náà rí nítorí kìí ṣe Zainab Suleiman ọ̀pọ̀ àwọn ìyá ọlọ́mọ ló ń kojú irú ìṣòro yìí. Bí ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ ṣe ń lékún ní gbogbo ìgbà tí owọ tó ń wọlé fún àwọn ìyá kò sì lékún jẹ́ kí ó ṣòro fún àwọn ìyá láti máa jẹ àwọn oúnjẹ tó dára láti pèsè omi ọyàn tí wọ́n nílò fún àwọn ọmọ wọn.
Àbẹ̀wò BBC sí àwọn ọjà ṣàfihàn rẹ̀ pé àpò ìrẹsì oní àádọ́ta kílógíráàmù tí wọ́n ń tà ní #35,000 ní ọdún méjì sẹ́yìn ti di #76,000 báyìí. Ìlé iṣu kan tó jẹ́ éyọ márùn-ún tí wọ́n ń tà ní #6,500 tẹ́lẹ̀ ló ti di #22,000 báyìí.
Bákan náà ni apẹ̀rẹ̀ ọ̀dùnkún tí wọ́n ń tà ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta náírà tẹ́lẹ̀ ti di ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án báyìí.
Kí ni àwọn ìyá tó ń tọ́mọ lọ́wọ́, pàápàá àwọn tálákà, wá le ṣe láti bọ́ nínú ìpèníjà ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ yìí?
BBC bá onímọ nípa oúnjẹ ní ẹ̀ka ètò ìlera aráàlú ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ahmadu Bello University, Zaria, Dókítà Suleiman Idris Hadejia sọ̀rọ̀ lórí àwọn oúnjẹ tí àwọn ìyá ọlọ́mọ lè máa jẹ tí kò sì ní gún wọn lápá.
Dókítà Hadejia ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ tó ṣara lóore ni àwọn ìyá tó ń tọ́mọ lọ́wọ́ lè jẹ tí owọ rẹ̀ kò sì wọ́n púpọ̀.
Àwọn oúnjẹ wo ni kò wọ́n níye yìí?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo oúnjẹ ló ti gbówó lórí, Dókítà Hadejia ní àwọn oúnjẹ kàn wá tí owó wọn kò ì tíì kọjá àfaradà, tí wọ́n sì ṣaara lóore.
Ó ní àwọn oúnjẹ tó dára, tó sì tún máa ń pèsè okun fára tí owó wọn kò sì wọ́n púpọ̀ ni watermelon, ìgbá, ànọ̀mọ́ àti cabbage.
Àwọn mìíràn ni jéró, àgbàdo, ẹ̀wà sóyà, ẹ̀fọ́ úgú, ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀, ilá, àti ẹ̀gẹ́. Ó ní síse àpapọ̀ àwọn oúnjẹ yìí àti mímu omi dáadáa ṣe pàtàkì fún ìlera tó péye fún àwọn ìyá tó ń tọ́mọ lọ́wọ́.
“Àwọn ìyá tó bá ń tọ́mọ lọ́wọ́ lè se ànọ̀mọ́, jéró tàbí ẹ̀gẹ́ papọ̀, kí wọ́n fi jẹ ọbẹ̀ úgú, ilá tàbí ọbẹ̀ ẹ̀pà.
“Lẹ́yìn tí wọ́n jẹ oúnjẹ yìí tán, wọ́n le fi ìrèké tàbí watermelon ṣe ìpanu le lórí, kí wọ́n sì máa mu omi dáadáa. Àwọn oúnjẹ yìí dára láti pèsè omi ọyàn dáadáa.”
Dókítà Hadejia fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn oúnjẹ yìí ni kò wọ́n níye àti pé wọ́n wà káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ó sọ pé ẹ̀kọ́ àti mọ́ínmọ́ín náà jẹ́ oúnjẹ tó dára fún àwọn ìyá tó ń tọ́mọ lọ́wọ́.
Ó tẹ̀síwájú láti gba àwọn ìyá ọlọ́mọ nímọ̀ràn láti máa dáná ní ẹ̀ẹmèjì lójúmọ́ àti láti máa pèsè àwọn oúnjẹ ọ̀sẹ̀ kan kalẹ̀ láti mú àdínkù bá iye ìgbà tí wọ́n fi ń pèsè àwọn oúnjẹ náà.
Àwọn tó ń ta èso tún ṣàlàyé fún BBC pé bí ọ̀wọ́n gógó ṣe bá gbogbo nǹkan, àwọn èso kàn ṣì wà tí owó wọn kò gunni lápá rárá.
Wọ́n ní àwọn èso bíi watermelon, ìgbá àti kùkùmbá kò wọ́n níye púpọ̀ tí a bá fi wé ápù tí wọ́n ń ta kékeré ẹyọ mẹ́ta ní ẹgbẹ̀rún kan náírà dípò àádọ́ta lé ní irinwó náírà tí wọ́n ń tà á tẹ́lẹ̀.

Àwọn ìmọ̀ràn míì fún àwọn ìyá tó ń tọ́mọ lọ́wọ́
TDókítà Hadejia ní kété tí ọmọ bá ti pé oṣù mẹ́fà, omi ọyàn kò ní tó ọmọ náà mọ́ nítorí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ tó ti ń dàgbà si, tí wọ́n sì nílò láti máa fi àwọn oúnjẹ míì kun fun.
Ó ní lára àwọn oúnjẹ tí wọ́n lè máa fún ọmọ ni lílọ àgbàdo pẹ̀lú ẹ̀wà sóyà pọ̀ pẹ̀lú edé láti fi ṣe ògì fún àwọn ọmọdé.
Ó ní àwọn èròjà yìí kò wọ́n rárá, tó sì wọ́pọ̀ ní agbègbè wa.
Ónímọ̀ náà ní ìwádìí kan tí wan ṣe ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ kan ní ìpínlẹ̀ Kaduna ṣàfihàn rẹ̀ pé fífún àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn ti lé ní oṣù mẹ́fà máa ń mú kí wọ́n dàgbà dada, pèsè agbára àti okum tí wọ́n nílò fún ìlera wọn fún wọn.















