Olumirin: Omi tí ọmọ Oduduwa ṣàwárí lọ́dún 1140 AD ní Erinjesha tó ń ṣe ìwòsàn fáráàlú

Njẹ o ti gbọ nipa omi kan to n ṣan lati inu apapta lati oke wa to wa niluu Erinjesha, nipinlẹ Osun?
Omi yii ni itan sọ pe awọn eeyan agbegbe naa kọkọ ṣawari lọdun 1140 AD.
Lonii, ibudo omi naa ti di ibudo igbafẹ fun ọpọ awọn eeyan kaakiri ilẹ Yoruba ati ni Naijiria.
Oshewa Kehinde to jẹ onimọ nipa omi naa to tun mu ikọ wa lọ sibẹ sọ fun BBC Yoruba pe omi naa ni ọpọ awọn eeyan agbegbe naa n mu, koda omi ọhun maa n ṣe iwosan fun ẹnikẹni to ba ni igbagbọ ninu rẹ.
Orisun omi Olumirin
Nigba ti a de ibudo ti omi naa wa, onpitan rẹ fi ere ikoko kan han wa, eyii to ṣafihan ibi ti omi na ti n ṣan wa, amọ o ni ibi ti orisun omi ọhun wa jina, lo jẹ ki awọn alaṣẹ mọ ere ikoko ọhun lati ṣapejuwe rẹ.
O ni "Ọkan lara awọn ọmọ baba Oduduwa ti a pe ni Yeye Aye... nigba ti baba Oduduwa waja, Yeye Aye tọ Ifa lọ, Ifa ni irinajo ti Yeye Aye fẹ rin maa na ni ọjọ mẹtadinlogun.
"Ọdẹ to tẹle Yeye Aye wa lati Ile Ife ti a pe Aponju Abela ṣe ọdẹ wa, o rin inu igbo kaakiri, o ri omi to n jabọ lara apata, o ni oun ri 'Oluwa-imirin.'
"Nigba ti aye ọlaju de, Oluwa-imirin yii ni wọn sọ di Olumirin."
Omi naa ni ọpọ awọn araalu Erinjesha n mu

Ọgbẹni Kehinde sọ fun pe ọdun 1957 ni ijọba fa omi ọhun lati ibi to wa lọ sinu ilu Erinjesha, omi naa ni wọn si n mu titi di oni yii.
Yatọ si pe wọn n mu oni apata naa o sọ siwaju si pe omi ọhun maa n ṣe iwosan
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹnikẹni to ba ni awọn aisan bii inu rirun, ori fifọ ati bẹẹ bẹẹ lọ yoo ri iwosan to ba mu omi naa pẹlu igbagbọ.
Fun awọn ti kii ṣe ọmọ ilu Erinjesha ohun igbafẹ ni omi naa jẹ fun wọn.
Kehinde pari ọrọ rẹ pe gbogbo awọn arinrinajo afẹ to maa n lọ sidi omi Olumirin lo n pada sile wọn pẹlu ayọ ati alaafia.
Ati pe irọ ni iroyin kan to ni oyinbo kan to lọ sibẹ padanu ẹmi rẹ.






