Òpó ṣọ́ọ̀ṣì wó lulẹ̀, èèyàn 30 kú, ọ̀pọ̀ farapa

Ọkọ ti wọn maa n fi gbe awọn alailera

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọlọpaa insipẹkitọ kan, Ahmed Gebeyehu, ṣalaye pe ẹgbẹẹgbẹrun awọn olujọsin lo pejọ si ṣọọṣi Arerti Mariam lowurọ kutu nigba ti apa kan ile ijọsin naa ṣadeedee wo lulẹ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko din ni ọgbọn eeyan to padanu ẹmi wọn tawọn to le ni igba eeyan mii si farapa lẹyin ti opo ile ijọsin kan wo lulẹ lorilẹede Ethiopia.

Ọlọpaa insipẹkitọ kan, Ahmed Gebeyehu, ṣalaye pe ẹgbẹẹgbẹrun awọn olujọsin lo pejọ si ṣọọṣi Arerti Mariam lowurọ kutu nigba ti apa kan ile ijọsin naa ṣadeedee wo lulẹ.

Awọn eeyan naa lọ sile ijọsin ọhun to wa laarin gbungbun ẹkun Minjar Sheknora ti ko ju aadọrin kilomita lọ si Addis Ababa ti i ṣe olu ilu Ethiopia fun ayẹyẹ Maria Mimọ to maa n waye lọdọọdun.

Ọgbẹni Ahmed sọ pe o ṣee ṣe ki awọn eeyan to ku pọ si i.

O fikun ọrọ rẹ wi pe ọpọ eeyan to ku ni ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọdun mẹẹdọgbọn si ọgọrin ọdun.

Igbimọ alaṣẹ ẹsẹ kuku sọ pe ọpọ eeyan si wa labẹ ile to wo, ati pe iṣẹ idoola ẹmi si n lọ lọwọ.

''Apa kan ṣọọṣi naa lo ya lulẹ- ariwo sọ bi apa ṣọọṣi naa ti da wo,''

Awọn o ṣoju mi koro ni lojiji ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ ti ibẹru-bojo si gbalẹ ni ṣọọṣi naa.

''Apa kan ṣọọṣi naa lo ya lulẹ- iro nla to bani lẹru sọ soke bi apa ṣọọṣi naa ti da wo,'' o ṣoju mi koro lo sọ bẹẹ.

Wọn ti ko ọpọ awọn eeyan to farapa lọ si ile iwosan fun itọju ni Addis Ababa.

Ijọba Ethiopia ti ranṣẹ ibanikẹdun sawọn ẹbi awọn eeyan to farakaasa nibiu iṣẹlẹ naa.

Ko ṣaba si itọpinpin titẹle alakalẹ ijọba lori eto ilera ati eto aabo ara ẹni ni Ethiopia.

Bakan naa ni iṣẹlẹ ile wiwo wọpọ ni orilẹede naa.