Àlàyé rèé lórí ìdí tí wọ́n ṣe dàjọ́ ikú fún Joseph Kabila, ààrẹ tẹ̀lẹ́ ni Congo

Joseph Kabila naa ree to ya fọto niwaju igi kan, o wọ aṣọ oyinbo alawọ eeru, o si wọ omin-in to ni awọ omi aro ati ila tẹẹrẹ sinu.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Joseph Kabila, aarẹ Congo nigba kan, pada si orilẹede naa loṣu Karun-un, lẹyin to ti funra rẹ na papa bora lẹyin odi fun awọn asiko kan
    • Author, Wedaeli Chibelushi
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ orilẹede Olominira Congo nigba kan, Joseph Kabila, ni wọn ti dajọ iku fun bayii lori ẹsun lilọwọ si ogun to n ja orilẹede naa, ati awọn ẹsun to jọ mọ iditẹ mọ ijọba.

Bo tilẹ jẹ pe Joseph Kabila ko si nile lasiko idajọ naa, ile ẹjọ paṣẹ naa lẹyin rẹ. O tẹle ilana oyinbo ti a mọ si 'death in absentia', to tumọ si pe bi wọn ko tilẹ foju ri oku rẹ, idajọ naa fẹsẹ mulẹ.

Lara awọn ẹsun ti wọn ka si olori Congo tẹlẹ naa lẹsẹ ni pe o ṣe atilẹyin fun ikọ ọmọ ogun ọlọtẹ, M23. Ikọ ọmọ ogun yii ni wọn si mọ fun kiko ogun ja orilẹede naa, ti wọn si ti sọ ọpọ ile ọla di ahoro ni apa Ila-Oorun Congo.

Ọjọ Ẹti ni kootu fidi ẹ mulẹ, pe Kabila jẹbi ẹsun iditẹmọ ijọba, ẹsun iwa to tako ọmọniyan lo ṣikeji, lilọwọ si ki ogun waye ṣikẹta, ipaniyan, ẹsun ibalopọ ti ko tọ, ifiyajẹni ati pe o patẹ idaluru si ni awọn eyi to ku.

Ṣaaju ni aarẹ tẹlẹ naa ti ni oun ko jẹbi awọn ẹsun yii, ṣugbọn ko yọju si kootu lati gbeja ara rẹ, tabi lati wa tako ohun ti ile ẹjọ sọ pe o ṣe.

Ohun ti Kabila sọ nigba naa ni pe wọn lo ọwọ agbara lati to awọn ẹsun naa pọ ni, wọn si di i le oun lori.

O ni awọn kan ni wọn n lo ile ẹjọ lati fi ọwọ ọla gba oun loju.

Ni bayii ṣaa, ko sẹni to mọ ibi ti Joseph Kabila wa.

Ọdún 18 ni Kabila fi wà nípo ààrẹ Congo, bàbá rẹ̀ ló kúrò nípò tí òun fi gbà á

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi a ba n sọ nipa asiko ti aarẹ Joseph Kabila fi wa nipo agbara ni Congo, ọdun mejidinlogun (18) ni.

Baba rẹ, Laurent, lo fipo naa silẹ ti Kabila fi gba a, wọn si yinbọn pa baba naa ni 2001 ni.

Kabila , ẹni ọdun mẹrinlelaadọta (54), gbe ipo naa fun Aarẹ Félix Tshisekedi, ni 2019, ṣugbọn ija pada de laaarin wọn, Kabila si kuro niluu ni 2023, o gba ẹyin odi lọ.

Nigba to di oṣu Kẹrin ọdun yii, aarẹ tẹlẹ yii sọ pe oun fẹ ba wọn wa ojutuu si ija to n gba ọpọ ẹmi lapa Ila-Oorun Congo, o si de si ilu Goma ti awọn ọmọ ogun M23 ti n ṣọṣẹ, oṣu Karun-un lo pada de.

Eyi mu ki Aarẹ Tshisekedi fi ẹsun kan Kabila, pe oun lo wa nidii iṣẹ buruku ti awọn M23 n jẹ, awọn aṣofin naa da si i pẹlu, wọn si gba agbara imuniti ti Kabila ni lọwọ rẹ, ti ile ẹjọ fi le ni ko waa jẹjọ.

Ẹ o ranti pe ogun ọdun pipẹ to n ṣẹlẹ ni Congo naa tun burẹkẹ si i lọdun yii, nigba ti awọn M23 gba ọpọ ilu to wa ni apa ibi ti wọn ti n ri epo lorilẹede naa, titi kan Goma, ilu Bukavu ati papakọ ofurufu meji.

Lori ọrọ yii, ajọ Iṣọkan Agbaye (UN) ati awọn orilẹede agbaye mi-in ti naka abuku si orilẹede Rwanda to jẹ alamuleti Congo, wọn ni awọn naa n ti M23 lẹyin, wọn si n fi ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ ogun ranṣẹ si Congo.

Ṣugbọn Rwanda ti olu ilu rẹ jẹ Kigali, sọ pe ko ri bẹẹ, wọn ni awọn n dena bi ogun naa ko ṣe ni i de ọdọ awọn ni.

Oṣu Keje ni awọn ọmọ ogun ọlọtẹ naa ati ijọba, kọwọ bọwe adehun alaafia, ṣugbọn wọn ko tori ẹ sinmi ogun ati itajẹsilẹ.