Mount Sinai: Òkè mímọ́ fún Kristẹni, Musulumi àti Jew di ibùdó ìgbafẹ́ lásán

Ita ibudo ijọsin St Catherine ree. O jẹ ile kan to ni ọpọlọpọ ile miran ninu, bẹẹ ni agbala rẹ naa si wa lẹgbẹẹ kan ti wọn kọ ọ si, o ni awọn irugbin alawọ tutu ti wọn gbin sibẹ. Ninu aworan yii, awọn okuta lo yi ibudo ijọsin yii po, apa ibi kan si walẹ nibẹ lati sọkalẹ lori oke naa.

Oríṣun àwòrán, Universal Images Group via Getty Images

Àkọlé àwòrán, St Catherine to wa ni Senturi Kẹfa ni ibudo ti awọn Kristẹni mimọ n gbe ju lagbaaye nigba naa.
    • Author, Yolande Knell
    • Role, BBC News, Jerusalem
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Fun ọpọlọpọ ọdun ni awọn alejo fi n ṣabẹwo si ori oke Sioni (Mount Sinai) fun eto adura, atọnisọna kan yoo si mu wọn gunke, nibi ti wọn yoo ti wo ibi gegele okuta to wa nibẹ, ti wọn yoo ti wo atiyọ oorun, tabi ki wọn gba apa ibi to ba tun wu wọn ni Bedouin lọ.

Ṣugbọn ni bayii, ọkan lara awọn aaye ti awọn Juu (Jew), Kristẹni ati Musulumi bọwọ fun ni Egypt naa ti n ṣe bẹẹ di aaye aimọ, eto si ti bẹrẹ lati yi i pada, ti yoo di ibudo igbafẹ fun awọn arinrinajo faaji, yatọ si tawọn ẹni mimọ ti wọn n fi ibẹ jọsin tẹlẹ.

Fun awọn eeyan agbegbe yii, orukọ ti wọn mọ oke naa si ni Jabal Musa, Oke Sinai yii ni ibi ti a gbọ pe Mose ti gba ofin mẹwaa rẹ . Ọpọ eeyan lo tun gbagbọ pe aaye naa ni Ọlọrun ti ba Mose sọrọ lati ibi papa to n jona, gẹgẹ bi Bibeli ati Kurani ṣe wi.

Bakan naa ni aaye ijọsin awọn eeyan mimọ ti a mọ si St Catherine's Monastery, eyi ti wọn kọ ni Senturi kẹfa naa wa nibẹ. A si gbọ pe awọn alufaa ibẹ sọ pe awọn ko ṣetan lati ti ibudo naa pa.

Amọ ohun to n kọ ni lominu ni bi ibudo ti ajọ UNESCO paapaa damọ yii ṣe wa n di ibi ti wọn n kọ otẹẹli olowo nla si lọwọ bayii, ti wọn n ko ile itaja si ati aaye igbafẹ ti aye ti n naju.

Ori oke yii tun jẹ aaye fun awọn eeyan Bedouin kan ti a mọ si ẹya Jebeleya .

Awọn ẹya naa ti wọn maa n mojuto St Catherine, ni wọn wo ile wọn ati awọn ibi ti wọn n fori pamọ si lori oke naa, bi wọn ba fun wọn lowo fun ile ti wọn wo naa, owo ọhun ko to nnkan kan. Wọn fipa mu wọn lati hu oku ti wọn ti sin jade pẹlu, ninu awọn iboji to wa lagbegbe naa, aaye igbọkọsi ni wọn si fi iboji naa kọ.

"O ṣee ṣe ki wọn sọ fun wọn pe awọn igbesẹ yii ṣe dandan lawọn ṣe n gbe e, ati pe yoo ran ọrọ aje lọwọ, yoo mu idagbasoke wa, yoo si bu ẹwa kun ibẹ. Ṣugbọn gbogbo igbesẹ naa lo jẹ pe wọn fipa la a bọ awọn eeyan Bedouin yii lọrun ni, ko wu wọn ko ri bẹẹ."

"Eyi ki i ṣe idagbasoke ti awọn Jebeleya fẹ, ko si ki n ṣe ohun ti wọn beere fun ree. Niṣe lo dabii pe wọn fipa la a bọ wọn lọrun lati tẹ awọn ara ita lọrun , ti wọn si kọyin si awọn eeyan to n gbe nibẹ to si n tun ibẹ ṣe."

Ben Hoffler, arinrinajo ọmọ ilẹ Gẹẹsi kan to ti ba awọn ẹya Sinai ṣe daadaa lo sọ bẹẹ.

"Wọn ti n kọle nla agbaye si Bedouin, tako awọn eeyan to n rin kiri ti wọn n gbe nibẹ. "Ohun ti wọn fẹ kọ yii ni yoo yi igbesi aye wọn pada titi aye."

Ben Hoffler, lo wi bẹẹ.

Awọn eeyan ibẹ to le ni ẹgbẹrun mẹrin ko ṣetan lati ṣalaye taara lori ohun to n ṣẹlẹ yii.

Aworan yii ṣafihan ọkan lara awọn ibi ti wọn n kọ naa, Plain of e-Raha. Itansan ooru han loke naa, isalẹ ni wọn ti n ṣe awọn ọna ti yoo wọ ile naa.

Oríṣun àwòrán, Ben Hoffler

Àkọlé àwòrán, Nigba ti wọn n kọ el-Raha ni 2024
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nibi to de duro bayii ṣaa, Ilẹ Greece ni alagbara okeere to n sọrọ ju lori ohun to n ṣẹlẹ yii, oun lo n pariwo ohun ti awọn Egypt n ṣe, nitori ajọṣepọ rẹ pẹlu ibudo ijọsin yii.

Ija aarin awọn Athens ati Cairo tun ṣẹyọ lẹyin ti kootu ilẹ Egypt kan paṣẹ pe loṣu Karun-un, pe ori ilẹ ilu ni St Catherine - aaye ijọsin awọn Kristẹni to dagba ju lagbaaye wa.

Lẹyin ija ọdun mẹwaa, awọn adajọ sọ pe ibudo ijọsin naa le lo ilẹ to wa , ati awọn ohun alumọni to ba wa nibẹ.

Archbishop Ieronymos II ti Athens, olori ile ijọsin Greece, lo yara dide to si tako idajọ naa.

"Wọn fẹ gba dukia Oluwa, iṣura ọlọdun pipẹ yii ti fẹ bọ sibi ti ko yẹ."Bẹẹ ni Alagba naa wi ninu atẹjade kan.

Ninu ifọrọwerọ kan, Archbishop Damianos to ti wa ni St Catherine fọdun pipẹ, so fun iwe iroyin ilẹ Greek kan pe "ohun to ka wa laye gan-an leyi, o si ti wa loju".

Ninu ọrọ awon agba Greek to ti pẹ ni Jerusalem, wọn ni Anọbi Muhammad funra ẹ fi aaye mimọ yii fun awọn lati maa lo fun ijọsin -Ati pe o fun awọn ni lẹta idaboobo pẹlu.

Wọn fi kun un pe aaye ijọsin ti i ṣe Byzantine monastery - eyi ti awọn musulumi naa maa n wa nibẹ nitori mọṣalaṣi kekere to ni, ti wọn si ti kọ lati ọdun gbọọrọ lasiko Fatimid era - fi han pe alaafia wa laaarin awọn Kristẹni ati Musulumi, aaye isadi, aaye ireti si ni ibẹ. ".

Bi idajọ kootu to n mu ariyanjiyan waye yii ṣe n lọ lọwọ, Greece ati Egypt ti jọ panupọ lati da aabo bo St Catherine., ki wọn si gbe idanimọ rẹ ọlọdun gbọọrọ ga.

Ori oke tente Mount ree lalẹ ọjọ kan ni 2024. Ina tan loke apata naa, to ga gogoro ju oke mi-in to tun wa nibẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Ben Hoffler

Àkọlé àwòrán, Oke Sioni (Mount Sinai), ti awọn eeyan agbegbe rẹ mọ si Jabal Musa, ni ibi ti a gbọ pe Mose ti gba ofin mẹwaa wá.

'Ẹbun pàtàkì rèé tàbí àyọjúràn?

Ọdun 2021 ni Egypt bẹrẹ isọdọtun agbayanu to gunle fun awọn arinrinajo yii.

Awọn igbesẹ naa ni ṣiṣi otẹẹli, awọn ibudo koriko to tutu dodo ati aaye igbalejo nla to tobi gan-an,titi kan ṣiṣẹ amugbooro papakọ ofurufu kekere to wa nitosi, ati ọkọ ayọkẹlẹ to n lo waya ti yoo maa gbe awọn eeyan lọ si Oke Mose.

"Ijọba n gbe idagbasoke larugẹ ni, wọn si n ṣọna ẹbun pataki fun Egypt ti yoo kari gbogbo agbaye, ti yoo si fi aaye gba gbogbo ẹsin "

"Eto yii yoo mu irinajo afẹ rọrun fun awọn arinrinajo, yoo mu idagbasoke ba ilu, nibi ti St Catherine wa ati agbegbe rẹ.yoo si mu alaafia ba awọn nnkan iṣẹda to wa nibẹ, yoo fi aṣa ati iṣe wa han, yoo tun pese ibugbe fun awọn to n ṣiṣẹ ni St Catherine." Minisita ọrọ ileegbe, Sherif el-Sherbiny, lo sọ bẹẹ lọdun to kọja.

Bo tilẹ jọ pe iṣẹ ti dawọ duro diẹ na, nitori aisowo, eyi ti a mọ si Plain of el-Raha -nitosi St Catherine's Monastery ti di kikọ tan- bẹẹ ni wọn n ṣe awọn ọna rẹ lọwọ.

Eyi ni ibi ti a gbọ pe awọn olutẹlẹ Moses, awọn ọmọ Israeli, ti duro de e nigba to gun ori oke Sioni lọ. Awọn awoye si sọ pe agbara pataki to so ibẹ ro ni wọn ti bajẹ bayii.

Ori oke naa ree lọwọ alẹ, lati Jebel el Ahmar, ni ọdun 2024. Wọn tan ina si oke naa, o si mọlẹ lọ si ọọkan.

Oríṣun àwòrán, Ben Hoffler

Àkọlé àwòrán, Aaye yii ni ọpọ eeyan mọ fun bo ṣe rẹwa to pẹlu iṣẹ ọwọ Ẹlẹdaa, nibi awọn oke wọnni.

Àjọ UNESCO kìlọ̀

Ni 2023, Ajọ UNESCO ṣalaye ominu to n kọ ọ nipa atunkọ ori oke yii, o si pe Egypt lati ṣiwọ idagbasoke rẹ to loun n ṣe.

UNESCO sọ pe ki wọn wo ipa ti atunkọ yii yoo ni lori ilu, ki wọn si wa ọna irapada mi-in.

Eyi ko ti i waye latigba naa.

Ni oṣu Keje, Ajọ World Heritage Watch, fi lẹta kan ranṣẹ si UNESCO, wọn ni ki ajọ yii kede pe ewu n bẹ fun gbogbo agbegbe St Catherine, ki gbogbo aye ri i.

Bakan naa ni awọn to n polongo iru nnkan bayii ti dide, wọn kan si King Charles, gẹgẹ bii Baba ẹgbẹ St Catherine Foundation, to maa n fun wọn lowo lati tọju ibudo naa ati awọn iwe ti awọn Kristẹni iṣaaju ti kọ sibẹ.

Ọba naa paapaa ṣapejuwe ibudo yii bii aaye mimọ ti iṣura ibẹ ko gbọdọ yingin titi de iran de iran".

Nitori idagbasoke ilu la ṣe n gbe igbesẹ yii- Ijọba Egypt

Ile nla ti wọn bẹrẹ ni Egypt yii kọ ni akọkọ iru ẹ ti yoo mu ẹjọ dani, ti awọn eeyan yoo koro oju si pe ai ro ti ọmọnikeji ni wọn ṣe n kọ ọ ti wọn wa n pe e ni idagbasoke.

Ṣugbọn ijọba ri i bii ọna kan lati gbe ọrọ aje dide.

Ilẹ Egypt ti figba kan ri ni ẹka irinajo afẹ to pawo wọle daadaa, wọn si ti n bọ ninu idaamu ti Covid-19 mu ba wọn ati nigba ti ogun Gaza kan wọn. Ṣugbọn ijọba Egypt ti n leri bayii pe nigba ti yoo ba fi di 2028, awọn yoo ti le gbalejo ọgbọn miliọnu( 30 million visitors).

Labẹ ijọba to ti kọja ni Egypt, funra wọn ni wọn n gbe ọrọ idagbasoke Sinai, lai kan si awọn eeyan agbegbe Bedouin rara.

Laisiko ogun Middle East to waye ni 1967 ni wọn gba agbegbe naa, wọn si da a pada fun Egypt lẹyin ti awọn orilẹede mejeeji tọwọ bọwe adehun ni 1979.

Latigba naa ni awọn eeyan Bedouin ti maa n sọ pe wọn ti fi ọwọ rọ awọn sẹyin niluu awọn.

Ni ti ọna okun pupa to gbajumọ ti wọn ṣe, titi kan Sharm el-Sheikh, bẹrẹ ni Guusu Sinai laaarin 1980, ọpọ eeyan lo fi n we ohun to n ṣẹlẹ ni St Catherine bayii.

"Awọn ẹya Bedouin lo ni agbegbe naa, awọn ni wọn maa n mu awọn arinrinajo mọna, awọn ni wọn n ṣiṣẹ nibẹ, awọn ni wọn n fi ibẹ fun awọn to ba fẹẹ gba ibẹ."

Akọroyin ilẹ Egypt, Mohannad Sabry lo ṣalaye bẹẹ.

"Afi bi awọn olokowo arinrinajo ṣe de bayii ti wọn si le wọn danu -wọn ko le wọn lasan, wọn tun gba ọna atijẹ lọwọ wọn, wọn le wọn da si ilẹẹlẹ lati ori oke, nibi ti ko si nnkan fun wọn."

Otẹẹli kan ti wọn n kọ lọwọ ree ni Plain of el-Raha, ni 2024. O tobi, o rẹwa, ilẹ ibẹ si tẹju pẹrẹsẹ

Oríṣun àwòrán, Ben Hoffler

Àkọlé àwòrán, Otẹẹli kan ti wọn n kọ lọwọ ree ni Plain of el-Raha, ni 2024.

Ojú àpá kò lè jọ ojú ara mọ́

Gẹgẹ bo ṣe ri fun okun pupa, afojusun wa pe awon eeyan Egypt lati apa ibo miran niluu ni wọn yoo mu wa lati ṣiṣẹ ni ibudo tuntun St Catherine ti wọn n kọ lọwọ.

Ṣaa, ijọba sọ pe oun ṣi n ṣe atunṣe si awọn ile Bedouin to wa lagbegbe naa pẹlu.

Aaye ijọsin St Catherine yii ti n koju ọpọ ilakọja lati miliniọmu to kọja.

Nnkan bẹrẹ si i yipada bi wọn ṣe n fẹ okun pupa si i, ti awọn arinrinajo si n wa lati wo o .

Ero rẹpẹtẹ lo n wọle wa lati wo ajoku ina to ṣẹyọ nigba aye Mose, titi kan Codex Sinaiticus - akọsilẹ ti wọn fi ọwọ kọ to si jẹ ara ofin mẹwaa.

Ni bayii, bo tilẹ jẹ pe ibudo ijọsin atijọ naa yoo ṣi wa nibẹ, ohun ti wọn n kọ sibẹ ko le jọra wọn bii tatijọ mọ.