'Ẹkún gbọ̀n mí, ayọ̀ tún kún inú mi lásìkò tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mi dá ẹ̀bùn fún mi'

Àkọlé fídíò,
'Ẹkún gbọ̀n mí, ayọ̀ tún kún inú mi lásìkò tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mi dá ẹ̀bùn fún mi'

Awọn eeyan ma n sọ pe èrè olukọ wa l'ọrun. Ṣugbọn fun Ọgbẹni Ezekiel Olagunju, aye lo ti bẹrẹ si ni gba ere iṣẹ rẹ.

Laipẹ yii ni fidio kan tan kaakiri ori ayelujara, eyi to ṣafihan bi awọn akẹkọọ kan ṣe n fun olukọ kan ni ẹbun oriṣiriṣi lasiko ti wọn n kẹkọọ lọwọ.

Ọpọ eeyan lo si n gboriyin fun olukọ naa bi wọn ṣe n wo fidio ọhun.

Ko si ẹni meji to wa ninu fidio naa bikoṣe Ọgbẹni Olagunju, to jẹ olukọ ede Jamani, ni fasiti Obafemi Awolowo, to wa niluu Ile-Ife.

Ninu fidio to gbe Ọgbẹni Olagunju jade, niṣe lo bu si ẹkun nigba ti awọn akẹkọọ rẹ bẹrẹ si i tu yaaya jade, ti wọn si n fun ni oriruuru ẹbun pẹlu ẹẹrin ati ayọ.

Eyi lo mu ki BBC Yoruba ba olukọ naa sọrọ lori ohun to ṣe, ti awọn akẹkọọ naa fi bu ọla to to bẹẹ fun.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo naa, Ọgbẹni Ezekiel Olagunju sọ pe ko si aṣiri meji ninu ibaṣepọ oun pẹlu awọn akẹkọọ naa, ju pe oun mu wọn gẹgẹ bi ọmọ.

Olagunju lo ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi olukọ ede Jamani, eyi ti wọn n sọ ni orilẹ-ede Germany, lati bi ọdun mejilelogun

O ni iyalẹnu lo jẹ fun oun lasiko ti oun nkọ awọn akẹkọọ naa lọwọ, ti wọn si bẹrẹ si n jade lati fun mi ni oriṣiriṣi nnkan.

"Ohun ti wọn sọ ni pe awọn n fi awọn ẹbun naa mọ riri awọn nnkan ti mo ti ṣe fun wọn.

"Ẹkun gbọn mi diẹ, ayọ si tun kun inu mi wi pe awọn ọmọ naa n ri gbogbo wahala ti mo n ṣe lori wọn.

"Lootọ awọn nnkan bii bisikiiti ati ọti ẹlẹrindodo ni wọn ko fun mi, amọ nnkan nla ni ninu ọkan mi nitori ifẹ ti wọn fihan pẹlu rẹ."

Olukọ Olagunju ṣalaye pe lootọ ni oun jẹ olukọ fun awọn ọmọ naa, amọ baba ni oun tun jẹ fun wọn.

O ni eyi si jẹ ara idi ti oun kii ṣe e pa iṣẹ jẹ lasiko ti o ba yẹ ki oun kọ wọn "koda, ki o rẹ mi".

"Mo ma n ri i bi igba ti mo yọ nnkan kan kuro ninu igbeaye wọn ni ti mi o ba lọ si yaara ikẹkọọ."

Bakan naa lo sọ pe o sẹ pataki fun awọn olukọ ile-ẹkọ giga lati ri awọn akẹkọọ wọn gẹgẹ bi ọmọ nitori pe "ọwọ wa ni ọjọ ọla wọn wa".

Meji lara awọn akẹkọọ to ba BBC sọrọ, sọ pe oju aye awọn olukọ lo yẹ lati maa fi ẹmi imoore han si wọn, kii ṣe nigba ti wọn ba ku.