Àṣìta ìbọn pa ọdẹ nínú igbó l'Ogun, akẹgbẹ́ rẹ̀ márùn-ún dèrò àhámọ́

Awọn ọlọde ninu igbo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fi ṣinkun ofin gbe awọn ọlọdẹ marun-un latari iku Taiwo Bolugbe t'oun naa jẹ ọlọdẹ.

CSP Omolola Odutola, Alukoro ọlọpaa Ogun, fidi eyi mulẹ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Iṣẹgun, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 2025.

Odutola ṣalaye pe awọn ọdẹ naa lọọ dẹgbẹ ọdẹ lagbegbe Ajinawo, niluu Imasayi, eyi to wa nijọba ibilẹ Yewa, ipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta ni wọn ṣọdẹ lọ sigbo naa.

Báwo ni Taiwo ṣe kú láàárín àwọn ọdẹ ẹgbẹ́ rẹ̀?

CSP Odutola ṣalaye pe ẹran ti wọn n le lati pa ni Taiwo fẹẹ mu ti ibọn rẹ fi ṣeṣi yin.

''Iṣẹlẹ yii waye ni nnkan bii aago mẹta ọsan, a gbọ pe ibọn to gbe si ejika lo yọ bọ to si ṣeṣi yin.

''Ibọn naa lo ba a nibi ọrun ati àgbọ̀n isalẹ, bẹẹ lo si ṣe dagbere faye pẹlu gbogbo igbiyanju awọn ọlọdẹ ẹgbẹ rẹ lati doola ẹmi rẹ''

Nigba to n tẹsiwaju, Alukoro sọ pe aago mẹrin aabọ irọlẹ ti lu kawọn ọlọdẹ yooku too fi ọrọ naa to ọlọpaa leti.

Lẹyin ifisun naa ni wọn ko awọn ọdẹ marun -un yii si ahamọ bi Alukoro ṣe sọ. Odutola sọ pe iwadii n tẹsiwaju lori isẹlẹ ọhun.

O ni awọn ti taari ọrọ naa si ẹka to n ri si iwadii ẹsun ọdaran.

''Awọn ọdẹ marun-un naa ti wa lakata ọlọpaa, lẹka to n tọpinpin labẹnu.

A maa ṣagbẹyẹwo alaye ti wọn ba ṣe, bi ọwọ wọn ko ba si mọ lori ẹ, wọn yoo foju bale-ẹjọ''

CSP Odutola lo sọ bẹẹ.

O rọ awọn eeyan to ba n gbe ibọn dani, paapaa awọn ọlọdẹ latin maa ṣọra pẹlu ibọn.