Ẹbí dáwọ́ lu ìyàwó oníyàwó lálùbami nítorí ó kọ̀ láti bu ìyẹ̀pẹ̀ sí òkú ọkọ rẹ̀ àtijọ́

Oríṣun àwòrán, Others
Obinrin kan ni awọn mọlẹbi ọkọ rẹ nigba kan sọ di apo ẹwa, ti wọn n lu nitori o kọ lati da iyẹpe ṣoju ori ọkọ rẹ to di oloogbe.
Mellen Mogaka ni o ti n beere fun idajọ ododo lori iṣẹlẹ naa to waye ni Nyabisimba, ilu kan ni orilẹede Kenya.
Iṣẹlẹ naa waye ni ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta ọdun, 2025.
Ninu fọnran to lu sita lori ọpọ ayelujara, awọn mọlẹbi ọkọ naa lo yọ ẹgba si Mellen ti wọn si bẹrẹ si ma lu u ni alubami.
Oloogbe naa ni o jẹ ọkọ Mellen tẹlẹ, ṣugbọn ti wọn ti kọ ara wọn silẹ ṣaaju iku rẹ.
Mellen ni oun ati oloogbe naa ti o jẹ ọkọ rẹ tẹlẹ ni awọn ti tuka ṣugbọn wọn kesi oun pe ko mu awọn ọmọ oloogbe wa si ibi eto isinku rẹ ki wọn le bu ọla ikẹyin fun baba wọn.
Iya Mellen ni, pẹlu omije loju ni oun fi n wo bi wọn ṣe n lu ọmọ oun ni itẹ oku naa
O ni o ṣeni laanu pe oun ko ni agbara kankan lati gba ọmọ oun silẹ lọwọ awọn eeyan ti wọn n lu ni alubami nitori o jẹ aṣa.
"Wọn da iyepẹ si lẹnu, da omi le lori. Wọn bọ bata ẹsẹ rẹ, ti wọn si ju sinu koto oloogbe.
"E sọ fun mi, iru aṣa wo ni eyi?"
Iya ni oun bẹrẹ si ni pariwo fitafita ṣugbọn o ṣeni laanu pe, awọn eeyan yii kọ lati gbọ si oun lẹnu.
Baba Mellen, Nehemiah Matundura, naa sọrọ lori iriri rẹ, to si jẹ ko di mimọ pe awọn mọlẹbi ọkọ ọmọ rẹ tẹlẹ ṣekọlu si oun naa.
"Wọn ṣe mi balabala, ti wọn si ju ọmọ mi sinu koto. Gbogbo aṣọ mi lo kun fun iyepẹ, eyi ti wọn da si mi lara."
Mellen, iya ọlọmọ meji lo ti wa pe fun idajọ ododo, to si jẹ ko di mimọ pe inu irora ni oun wa, ti gbogbo ara rẹ si wu nitori lilu ti wọn lu u.
"Iya kan da iyepẹ si gbogbo ara mi, to fi de ibi awọtẹlẹ, irun ati eti mi.
"Ọkunrin kan gba mi ni ikun mi, gbogbo ara lo n ro mi.
"Mo fẹ ki ijọba ran mi lọwọ nitori n ko ni ẹnikẹni lati saa lọ ba."
Ọwọ ti tẹ eeyan mẹta lori iṣẹlẹ naa- Ileeṣẹ ọlọpaa
Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Kenya ti kede pe ọwọ ti tẹ eeyan mẹta to lọwọ ninu ikọlu si obinrin kan ni itẹ oku ni agbegbe Kiambere lorilẹede Kenya.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita, ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti ri fọnran naa, ti wọn si dupẹ lọwọ araalu to pe akiyesi wọn si iṣẹlẹ naa.
"Lẹyin ti a gbọ nipa iṣẹlẹ naa, a ti bẹrẹ iwadii ni kiakia, ti ọwọ si ti tẹ eeyan mẹta. Wọn ti wa ni ahamọ, ti wọn yoo si foju bai le ẹjọ laipẹ."
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni, awọn ti ṣawari obinrin naa, ti wọn si ri aridaju pe o wa ni alaafia.
"Alaafia ni obinrin naa wa bayii, ti a si ti mu awọn eeyan mẹta si ahamọ.
"A dupẹ lọwọ araalu fun bi wọn kesi wa lori iṣẹlẹ idojutini yii."















