Àsìkò òjò la wà yìí, wo bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àrá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pẹlu bi a ti ṣe wa lasiko ojo bayii, ko ṣe e ṣe ki ara o ma san an.
Nigba mii ti ara ba san, o ma n ba awọn dukia jẹ tabi fa iku nigba miran.
Laipẹ yii ni ara lile kan to san to si fa ina ti jo ile-ẹkọ alakọọbẹrẹ Saint Peter's Primary School to wa ni Igbemo, nipinlẹ Ekiti.
Iṣẹlẹ ina ọhun waye lọjọ Aiku, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta ọdun 2025.
Iroyin sọ pe ojo kan lo rọ fun bii wakati kan lọjọ naa, ninu rẹ ni ara ti san. Ara lo sọ ina le orule ile-ẹkọ lori to fi jo.
Yara ikawe marun-un lo wa nile-ẹkọ naa, eyi ti ara san, to si jo wọn.
Oore kan to wa ninu ijamba naa ni pe asiko ti awọn tiṣa ati akẹkọọ wa nilee wọn fun isinmi opin ọsẹ lo ṣẹlẹ.
Ẹmi kankan ko ba ijamba ina naa lọ.

Oríṣun àwòrán, Ekiti State Deputy Governor's Office
Kí ló ṣẹlẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́ Ajé táwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti tíṣà dé?

Oríṣun àwòrán, Ekiti State Deputy Governor's Office
Lọjọ keji tina jo ile ẹkọ naa ti i ṣe ọjọ Aje, awọn tiṣa ko le kọmọ nibẹ.
Ṣugbọn nitori iṣẹ gbọdọ tẹsiwaju, ki ẹkọ awọn ọmọ ma si duro, awọn tiṣa naa ṣeto, wọn ko wọn lọ sile ẹkọ AUD Pilot Nursery and Primary School to wa nitosi, lati maa ba ẹkọ wọn lọ.
Nigba to ṣabẹwo sile ẹkọ to jona naa, Gomina Biodun Oyebanji, ti Igbakeji rẹ, Abilekọ Monisade Afuye, ṣoju fun, ṣeleri pe ijọba yoo kọ ile ẹkọ naa pada laipẹ.
Gomina fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ naa ati bi awọn akẹkọọ ṣe ni lati kuro ibi ti wọn ti wa tẹle.
" A maa kọ ile ti ina jo yii pada laipẹ, kawọn akẹkọọ ati olukọ le fọkan balẹ.
"Inu mi bajẹ nitori ina to mu iyalẹnu wa pẹlu ara to san.
Loootọ, ile jona, ṣugbọn inu mi dun pe a ko padanu ẹmi kankan, nitori asiko ti awọn akẹkọọ atawọn tiṣa wa nilee wọn lo ṣẹlẹ."
Gomina Oyebanji lo sọ bẹẹ.
Gomina Oyebanji yin awọn olukọ naa fun bi wọn ṣe tete ko awọn akẹkọọ lọ sibudo mi-in.

Oríṣun àwòrán, Ekiti State Deputy Governor's Office
Kí ló ń fa àrá sísán?
Nigba ti nnkan ko ba fararọ fun oju ọjọ, to darapọ mọ omi ati afẹfẹ to lọ wọọrọ to n ga loke lọhun-un, nigba naa ni ara yoo san, gẹgẹ bi iwadii imọ ijinlẹ Sayẹnsi ti BBC ṣe.
Bakan naa, nigba ti oorun ko ba ta silẹ mọ, atẹgun olooru to wa nisalẹ ilẹ yoo ru, ara yoo si san.
Omi yoo bẹrẹ si i kora jọ pọ, oju ọrun naa yoo si maa korajọ. Lẹyin eyi ni yoo maa mu ooru ti yoo yipada di agbara àrá.
Nigba ti gbogbo agbara wọnyi ba kora jọ tan ni ojo yoo bẹrẹ si i rọ, otutu yoo maa mu, bẹẹ ni atẹgun yoo maa fẹ.
Apapọ awọn nnkan ọtọ yii ni yoo ranṣẹ si àrá, nigba naa ni yoo la gaara, ti yoo han loju ọrun pe agbara n kan ara wọn.
Eyi ni a mọ si ara to ṣee ṣe ko mu ina dani nigba mi-in, to si le ṣe ijamba ọlọkan-o-jọkan.
Bí o ṣe lè dá ààbò bo ara rẹ lọwọ àrá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni 2018, o kere tan, eeyan mẹrindinlogun lo ku lẹsẹkẹsẹ, bẹẹ lawọn mii farapa nigba ti ara san nile ijọsin Seventh-Day Adventist kan lorilẹede Rwanda.
Eeyan ogoje (140) ni wọn sare gbe lọ sileewosan alabọọde to wa nitosi.
Bakan naa lọrọ ri lorilẹede Ghana ni 2021, nigba ti ara san to si pa eeyan mẹta.
Bawo wa ni o ṣe le da aabo bo ara rẹ lọwọ ara?
Akọkọ, o gbọdọ fi foonu rẹ silẹ lasiko ti ara n san, ma ṣe ki i bọ ina lati ro o lagbara lasiko yẹn.
- Ma ṣe sunmọ ohunkohun to n lo ina ẹlẹtiriiki.
- O ṣe pataki lati kuro ni ẹnu ọna ati ojuu fẹrẹsẹ.
Eyi ni wọn fi maa n kilọ fun awọn ọmọde pe ki wọn ma duro lẹnu ọna bi ojo ba n rọ.
Ma ṣe sun si ilẹẹlẹ onisimẹti lasan .
- To ba jẹ pe ita lo wa lasiko ti ara n san, kuro lagbegbe to ba ga tabi ori oke.
- Ma ṣe sa si abẹ igi fun aabo.
- Kuro ninu omi tabi odo eyikeyi lasiko ti ara ba n san.
- Ma ṣe sun mọ ohunkohun to n lo ina ẹlẹtiriiki, bii fẹnsi, abẹ ina nla ti a mọ si 'power line'' ati bẹẹ bẹẹ lọ.













