Ọlọ́pàá bínú yínbọn mọ́ èèyàn mẹ́ta ní Cross River, ọ̀kan kú, méjì balẹ̀ sílè ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, Others
Insipẹtọ ileeṣẹ ọlọpaa Effiong Bassey ni wọn ni o sadede binu sodi, to si yinbọn lu eeyan mẹta niluu Calabar nipinlẹ Cross River.
Gẹgẹ bí o ṣe wa loju opo ileeṣẹ iroyin abẹle, Channels TV, Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa ti fi di isẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan ti wọn fi lede lọjọ Aiku, ọjọ Kẹtalelogun oṣu kẹta ọdun 2025.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Ugbo Irene ṣalaye pe iṣẹlẹ naa waye ni owurọ ọjọ Aiku ni ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Atakpa niluu Calabar.
O ni Bassey pada de lati ibi iṣẹ alẹ to lọ ṣe ni ileeṣẹ ifowopamọ Ekondo, lo si bẹrẹ si ni ma hu iwa kiwa.
"Insipẹtọ Bassey kọ lati fi ibọn AK 47 ọwọ silẹ, to si lọ duro si ẹnu ọna abawọle ileeṣẹ ọlọpaa ti ko si jẹ ki ẹnikẹni wọle tabi jade sita
"Lẹyin ọpọ igbiyanju lati jẹ ki alaafia jọba, ọrọ naa pada di tọrọfọnkale," atẹjade naa ṣalaye.
"Nigba to ya ni awọn ẹsọ alabo lati Tactical Units/Patrol teams de sibi iṣẹlẹ naa ṣugbọn Insipẹtọ Bassey sina bolẹ, to si yinbọn lu awọn eeyan to wa layika ileeṣẹ ọlọpaa.
"O ṣeni laanu pe ibọn ba eeyan mẹta, to fi mọ arabinrin kan, Ijeoma Wilson Obot, ẹni ọdun mọkanlelogoji, to jẹ ipe Ọlọrun.
"Awọn meji yooku, Charlse Mkpang pẹlu eeyan mii ni wọn wa ni ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju."
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Bassey ni o ti w ani ahamọ bayii, ti iwadii si ti ibẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.















