Pope Francis farahàn fún ìgbà àkọ́kọ́ láti ilé ìwòsàn Rome

Oríṣun àwòrán, APTN
- Author, Bethany Bell
- Role, BBC News
- Reporting from, Rome
- Author, Zahra Fatima
- Role, BBC News
- Reporting from, London
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Pope Francis ti farahan fun igba akọkọ lati igba to ti wa ni ile iwosan ni oju ferese ile iwosan to ti wa lati ọjọ kẹrinla oṣu keji.
Ẹni ọdun mejidinlaadọrin naa ni o gba iyọnda kuro ni ile iwosan ni bi isẹju diẹ sẹyin, ti awọn dokita si ni yoo nilo to oṣu meji lai fi sinmini Vatican.
Lati bi ọsẹ mẹfa sẹyin ni Pope ti wa ni ile iwosan, ti o si la ọpọ nnkan kọja, Dokita Sergio Alfieri, ọkan ninu awọn dokita Pope sọ.
Pope Francis fi arabalẹ lati gba itọju, to n si tun fi eti silẹ, Dokita Alfieri sọ. Ara Pope ko ti ya tan ṣugbọn ko ni aisan ilẹ tutu mọ, to si ti gbadun ju ti tẹlẹ lọ, gẹgẹ bii awọn dokita se ṣalaye.

Oríṣun àwòrán, APTN
Dr Alfieri ni awọn to ba ni aisan yii ni wọn padanu ohun wọn, "paapa to ba jẹ pe agbalagba ni eeyan naa, yoo gba akoko diẹ ki ohun wọn to pada."
Ni ọjọ Ẹti, Cardinal Victor Fernandez ni lẹyin ọpọ itọju, Pope yoo nilo lati kọ bi wọn se n sọrọ bayii. Ileeṣẹ iroyin Reuters lo gbe jade.
Awọn dokita ni ti Ara Pope ba tunbọ gba itọju si, o ṣeeṣe ki Pope pada si ẹnu iṣẹ ni aipẹ.
Pope ni o jẹ pe ẹẹkan ni wọn ti ri lati igba to ti wa ni ile iwosan ninu aworan kan ti Vatican gbe sita lọsẹ to kọja, nibi to ti n gba adura ni ile ijọsin ile iwosan naa.
Saaju ninu oṣu kẹta yii ni, wọn ka ohun Pope silẹ nibi to ti n sọrọ ni ede abinibi rẹ, Spanish fun ile ijọsin St Peter's ni ilu Vatican.
Nibẹ lo ti dupẹ lọwọ ijọ Aguda fun bi wọn se n gba adura fun.
Odun kejila Pope ree gẹgẹ bii olori ijọ Aguda lagbaye.
O ti ọpọ iṣoro ilera kọja ni igbesi aye rẹ.
















