1.3 mílíọ́nù ọmọdé tí kò rí oúnjẹ jẹ ni yóò pàdánù ìrànwọ́ ní Naijiria àti Ethiopia - UNICEF

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n pese iranlọwọ fun awọn ọmọ alaini lagbaye, UNICEF, ti sọ pe o ṣeeṣe ki awọn ohun elo iranwọ ọmọde to wa ni ikawọ oun tan laarin oṣu meji asiko yii.
O ni eyii yoo ṣe akoba fun nnkan bii miliọmu kan ọmọde ti ko ri ounjẹ jẹ ni Naijiria ati ni Ethiopia.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, eyii ko ṣẹyin bi Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump atawọn ajọ oluranwọ mii lagbaye ṣe n fopin si iranlọwọ ilẹ okeere ti wọn n ṣe fun awọn orilẹede ti ko rọwọ họri.
UNICEF sọ siwaju pe miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ọmọde ti ebi ọpagba n pa n da seria fun lawọn orilẹede mejeji ọhun ni ko ni ri iranlọwọ mọ.
O ni "Lai si iranlọwọ owo lakọtun, awọn ounjẹ aṣaraloore ti a n pin yo tan ti yoo ba fi di inu oṣu Karun un ọdun yii, eyii n tumọ si pe 70,000 ọmọde ni Ethiopa ti wọn gbẹklẹle irufẹ oun jẹ bẹẹ ni ko ni ri."
Igbakeji adari UNICEF, Kitty Van der Heijden ni ewu nla lo wa fun ọmọde ti idadurode ba de ba itọju wọn.
Ni Naijiria, UNICEF sọ pe o ṣeeṣe ki ounjẹ aṣaloore ti oun n fun awọn ọmọde ti ebi n ba finra tan ni ipari oṣu Kẹta yii.
Van der Heijden mẹnuba ọmo kan ti epi ba finra titi ti awọ ara rẹ si n ṣi danu niluu Maiduguri.
Ileeṣẹ iroyin Reuters jabọ pe lati ọdun diẹ sẹyin ni awọn oloju aanu ti n jawọ ninu fifi owo ranṣẹ si awọn ajọ ti kii ṣe ti ijọba kaakiri agbaye, UNICEF si wa lara awọn ajọ ti igbesẹ na pa lara.
Ọrọ naa tunbọ buru siwaju lẹyin ti ijoọba Amẹrika, to maa n fun ajọ naa ni owo to pọju dawọ igbesẹ ọhun duro fun oṣu mẹta lati ọjọ kinni ti Aarẹ Donald Trump gun ori alefa.
Van der Heijden ni ewu ni igbesẹ naa jẹ fun awọn alaini lagbaye to nilo iranlọwọ, paapaa awọn ti ebi n pa nilẹ adulawọ.















